Al-Layl

سورة الليل

Súrà 92 · Mákí · 21 àwọn ẹsẹ

92:1Júzù 30 · ojú. 595

وَاللَّيْلِ إِذَا يَغْشَىٰ1

(Allāhu) búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú.
92:2Júzù 30 · ojú. 595

وَالنَّهَارِ إِذَا تَجَلَّىٰ2

Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n.
92:3Júzù 30 · ojú. 595

وَمَا خَلَقَ الذَّكَرَ وَالْأُنْثَىٰ3

Ó tún búra pẹ̀lú Ẹni tí Ó dá akọ àti abo.
____________________
Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni Ẹni tí Ó dá akọ àti abo. Ó sì ń fi ara Rẹ̀ búra.
92:4Júzù 30 · ojú. 595

إِنَّ سَعْيَكُمْ لَشَتَّىٰ4

Dájúdájú iṣẹ́ yín, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni.
92:5Júzù 30 · ojú. 595

فَأَمَّا مَنْ أَعْطَىٰ وَاتَّقَىٰ5

Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu),
92:6Júzù 30 · ojú. 595

وَصَدَّقَ بِالْحُسْنَىٰ6

(tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní òdodo,
92:7Júzù 30 · ojú. 595

فَسَنُيَسِّرُهُ لِلْيُسْرَىٰ7

A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un.
92:8Júzù 30 · ojú. 595

وَأَمَّا مَنْ بَخِلَ وَاسْتَغْنَىٰ8

Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni t’ó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run,
92:9Júzù 30 · ojú. 595

وَكَذَّبَ بِالْحُسْنَىٰ9

(tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní irọ́,
92:10Júzù 30 · ojú. 596

فَسَنُيَسِّرُهُ لِلْعُسْرَىٰ10

A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un.
92:11Júzù 30 · ojú. 596

وَمَا يُغْنِي عَنْهُ مَالُهُ إِذَا تَرَدَّىٰ11

Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá já bọ́ (sínú Iná).
92:12Júzù 30 · ojú. 596

إِنَّ عَلَيْنَا لَلْهُدَىٰ12

Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà.
92:13Júzù 30 · ojú. 596

وَإِنَّ لَنَا لَلْآخِرَةَ وَالْأُولَىٰ13

Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé.
92:14Júzù 30 · ojú. 596

فَأَنْذَرْتُكُمْ نَارًا تَلَظَّىٰ14

Nítorí náà, Mo ti fi Iná eléjò fòfò kìlọ̀ fun yín.
92:15Júzù 30 · ojú. 596

لَا يَصْلَاهَا إِلَّا الْأَشْقَى15

Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú,
92:16Júzù 30 · ojú. 596

الَّذِي كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ16

ẹni tí ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.
92:17Júzù 30 · ojú. 596

وَسَيُجَنَّبُهَا الْأَتْقَى17

Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu),
92:18Júzù 30 · ojú. 596

الَّذِي يُؤْتِي مَالَهُ يَتَزَكَّىٰ18

ẹni t’ó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀).
92:19Júzù 30 · ojú. 596

وَمَا لِأَحَدٍ عِنْدَهُ مِنْ نِعْمَةٍ تُجْزَىٰ19

Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni,
92:20Júzù 30 · ojú. 596

إِلَّا ابْتِغَاءَ وَجْهِ رَبِّهِ الْأَعْلَىٰ20

bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ.
92:21Júzù 30 · ojú. 596

وَلَسَوْفَ يَرْضَىٰ21

Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rẹ̀).

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Ahmad Nainaa - Al-Layl · Tlawati