Ash-Shams

سورة الشمس

Súrà 91 · Mákí · 15 àwọn ẹsẹ

91:1Júzù 30 · ojú. 595

وَالشَّمْسِ وَضُحَاهَا1

(Allāhu) búra pẹ̀lú òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀.
91:2Júzù 30 · ojú. 595

وَالْقَمَرِ إِذَا تَلَاهَا2

Ó tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn).
91:3Júzù 30 · ojú. 595

وَالنَّهَارِ إِذَا جَلَّاهَا3

Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru.
91:4Júzù 30 · ojú. 595

وَاللَّيْلِ إِذَا يَغْشَاهَا4

Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀.
91:5Júzù 30 · ojú. 595

وَالسَّمَاءِ وَمَا بَنَاهَا5

Ó tún búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́n ?
____________________
Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni Ẹni tí Ó mọ àwọn sánmọ̀. Ó sì ń fi ara Rẹ̀ búra.
91:6Júzù 30 · ojú. 595

وَالْأَرْضِ وَمَا طَحَاهَا6

Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀.
91:7Júzù 30 · ojú. 595

وَنَفْسٍ وَمَا سَوَّاهَا7

Ó tún búra pẹ̀lú ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba.
91:8Júzù 30 · ojú. 595

فَأَلْهَمَهَا فُجُورَهَا وَتَقْوَاهَا8

Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n.
91:9Júzù 30 · ojú. 595

قَدْ أَفْلَحَ مَنْ زَكَّاهَا9

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè.
91:10Júzù 30 · ojú. 595

وَقَدْ خَابَ مَنْ دَسَّاهَا10

Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù.
91:11Júzù 30 · ojú. 595

كَذَّبَتْ ثَمُودُ بِطَغْوَاهَا11

Ìjọ Thamūd pe òdodo nírọ́ nípa ìtayọ ẹnu-àlà wọn.
91:12Júzù 30 · ojú. 595

إِذِ انْبَعَثَ أَشْقَاهَا12

(Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa).
91:13Júzù 30 · ojú. 595

فَقَالَ لَهُمْ رَسُولُ اللَّهِ نَاقَةَ اللَّهِ وَسُقْيَاهَا13

Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: "(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀)."
91:14Júzù 30 · ojú. 595

فَكَذَّبُوهُ فَعَقَرُوهَا فَدَمْدَمَ عَلَيْهِمْ رَبُّهُمْ بِذَنْبِهِمْ فَسَوَّاهَا14

Wọ́n pè é nírọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn.
91:15Júzù 30 · ojú. 595

وَلَا يَخَافُ عُقْبَاهَا15

(Ẹni t’ó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Ahmad Nainaa - Ash-Shams · Tlawati