Al-Buruj

سورة البروج

Súrà 85 · Mákí · 22 àwọn ẹsẹ

85:1Júzù 30 · ojú. 590

وَالسَّمَاءِ ذَاتِ الْبُرُوجِ1

(Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀.
85:2Júzù 30 · ojú. 590

وَالْيَوْمِ الْمَوْعُودِ2

Ó tún búra pẹ̀lú ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn.
85:3Júzù 30 · ojú. 590

وَشَاهِدٍ وَمَشْهُودٍ3

Ó tún búra pẹ̀lú olùjẹ́rìí àti ohun t’ó jẹ́rìí sí.
85:4Júzù 30 · ojú. 590

قُتِلَ أَصْحَابُ الْأُخْدُودِ4

A ṣẹ́bi lé àwọn t’ó gbẹ́ kòtò (iná),
85:5Júzù 30 · ojú. 590

النَّارِ ذَاتِ الْوَقُودِ5

. (ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò).
85:6Júzù 30 · ojú. 590

إِذْ هُمْ عَلَيْهَا قُعُودٌ6

(Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀.
85:7Júzù 30 · ojú. 590

وَهُمْ عَلَىٰ مَا يَفْعَلُونَ بِالْمُؤْمِنِينَ شُهُودٌ7

Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
85:8Júzù 30 · ojú. 590

وَمَا نَقَمُوا مِنْهُمْ إِلَّا أَنْ يُؤْمِنُوا بِاللَّهِ الْعَزِيزِ الْحَمِيدِ8

Kò sì sí kiní kan tí wọ́n torí rẹ̀ jẹ wọ́n níyà bí kò ṣe pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ọlọ́pẹ́,
85:9Júzù 30 · ojú. 590

الَّذِي لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ9

Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
85:10Júzù 30 · ojú. 590

إِنَّ الَّذِينَ فَتَنُوا الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ ثُمَّ لَمْ يَتُوبُوا فَلَهُمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَلَهُمْ عَذَابُ الْحَرِيقِ10

Dájúdájú àwọn t’ó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná t’ó ń jò sì wà fún wọn.
85:11Júzù 30 · ojú. 590

إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ جَنَّاتٌ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْكَبِيرُ11

Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
85:12Júzù 30 · ojú. 590

إِنَّ بَطْشَ رَبِّكَ لَشَدِيدٌ12

Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le.
85:13Júzù 30 · ojú. 590

إِنَّهُ هُوَ يُبْدِئُ وَيُعِيدُ13

Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde).
85:14Júzù 30 · ojú. 590

وَهُوَ الْغَفُورُ الْوَدُودُ14

Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá),
85:15Júzù 30 · ojú. 590

ذُو الْعَرْشِ الْمَجِيدُ15

Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ,
85:16Júzù 30 · ojú. 590

فَعَّالٌ لِمَا يُرِيدُ16

Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́.
85:17Júzù 30 · ojú. 590

هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ الْجُنُودِ17

Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ,
85:18Júzù 30 · ojú. 590

فِرْعَوْنَ وَثَمُودَ18

(ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd?
85:19Júzù 30 · ojú. 590

بَلِ الَّذِينَ كَفَرُوا فِي تَكْذِيبٍ19

Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo nírọ́.
85:20Júzù 30 · ojú. 590

وَاللَّهُ مِنْ وَرَائِهِمْ مُحِيطٌ20

Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn.
85:21Júzù 30 · ojú. 590

بَلْ هُوَ قُرْآنٌ مَجِيدٌ21

Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé,
85:22Júzù 30 · ojú. 590

فِي لَوْحٍ مَحْفُوظٍ22

tí ó wà nínú wàláà tí À ń ṣọ́.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà