Az-Zalzalah

سورة الزلزلة

Súrà 99 · Màdíínà · 8 àwọn ẹsẹ

99:1Júzù 30 · ojú. 599

إِذَا زُلْزِلَتِ الْأَرْضُ زِلْزَالَهَا1

Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní ìmìtìtì rẹ̀,
99:2Júzù 30 · ojú. 599

وَأَخْرَجَتِ الْأَرْضُ أَثْقَالَهَا2

àti (nígbà) tí ilẹ̀ bá tú àwọn ẹrù t’ó wúwo nínú rẹ̀ jáde,
99:3Júzù 30 · ojú. 599

وَقَالَ الْإِنْسَانُ مَا لَهَا3

ènìyàn yó sì wí pé: "Kí l’ó mú un?"
99:4Júzù 30 · ojú. 599

يَوْمَئِذٍ تُحَدِّثُ أَخْبَارَهَا4

Ní ọjọ́ yẹn ni (ilẹ̀) yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìró rẹ̀ (tí ẹ̀dá gbé orí ilẹ̀ ṣe).
99:5Júzù 30 · ojú. 599

بِأَنَّ رَبَّكَ أَوْحَىٰ لَهَا5

Nítorí pé dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó fún un ní àṣẹ (láti sọ̀rọ̀).
99:6Júzù 30 · ojú. 599

يَوْمَئِذٍ يَصْدُرُ النَّاسُ أَشْتَاتًا لِيُرَوْا أَعْمَالَهُمْ6

Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò máa gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nítorí kí wọ́n lè fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n.
99:7Júzù 30 · ojú. 599

فَمَنْ يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ خَيْرًا يَرَهُ7

Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.
99:8Júzù 30 · ojú. 599

وَمَنْ يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ شَرًّا يَرَهُ8

Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:7.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà