Al-Inshiqaq

سورة الإنشقاق

Súrà 84 · Mákí · 25 àwọn ẹsẹ

84:1Júzù 30 · ojú. 589

إِذَا السَّمَاءُ انْشَقَّتْ1

Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
84:2Júzù 30 · ojú. 589

وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ2

- ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ –
84:3Júzù 30 · ojú. 589

وَإِذَا الْأَرْضُ مُدَّتْ3

àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú,
84:4Júzù 30 · ojú. 589

وَأَلْقَتْ مَا فِيهَا وَتَخَلَّتْ4

ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo
84:5Júzù 30 · ojú. 589

وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ5

– ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ – (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)
84:6Júzù 30 · ojú. 589

يَا أَيُّهَا الْإِنْسَانُ إِنَّكَ كَادِحٌ إِلَىٰ رَبِّكَ كَدْحًا فَمُلَاقِيهِ6

Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀.
84:7Júzù 30 · ojú. 589

فَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِيَمِينِهِ7

Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,
84:8Júzù 30 · ojú. 589

فَسَوْفَ يُحَاسَبُ حِسَابًا يَسِيرًا8

láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn.
84:9Júzù 30 · ojú. 589

وَيَنْقَلِبُ إِلَىٰ أَهْلِهِ مَسْرُورًا9

Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú.
84:10Júzù 30 · ojú. 589

وَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ وَرَاءَ ظَهْرِهِ10

Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀,
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hāƙƙọh; 69:25.
84:11Júzù 30 · ojú. 589

فَسَوْفَ يَدْعُو ثُبُورًا11

láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun.
84:12Júzù 30 · ojú. 589

وَيَصْلَىٰ سَعِيرًا12

Ó sì máa wọ inú Iná t’ó ń jò fòfò.
84:13Júzù 30 · ojú. 589

إِنَّهُ كَانَ فِي أَهْلِهِ مَسْرُورًا13

Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé).
84:14Júzù 30 · ojú. 589

إِنَّهُ ظَنَّ أَنْ لَنْ يَحُورَ14

Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni).
84:15Júzù 30 · ojú. 589

بَلَىٰ إِنَّ رَبَّهُ كَانَ بِهِ بَصِيرًا15

Rárá (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀.
84:16Júzù 30 · ojú. 589

فَلَا أُقْسِمُ بِالشَّفَقِ16

Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwòǹpapa.
84:17Júzù 30 · ojú. 589

وَاللَّيْلِ وَمَا وَسَقَ17

Mo tún búra pẹ̀lú òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀.
84:18Júzù 30 · ojú. 589

وَالْقَمَرِ إِذَا اتَّسَقَ18

Mo tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀).
84:19Júzù 30 · ojú. 589

لَتَرْكَبُنَّ طَبَقًا عَنْ طَبَقٍ19

Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan.
84:20Júzù 30 · ojú. 589

فَمَا لَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ20

Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo?
84:21Júzù 30 · ojú. 589

وَإِذَا قُرِئَ عَلَيْهِمُ الْقُرْآنُ لَا يَسْجُدُونَ ۩21

Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀.
84:22Júzù 30 · ojú. 589

بَلِ الَّذِينَ كَفَرُوا يُكَذِّبُونَ22

Rárá, ńṣe ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é nírọ́.
84:23Júzù 30 · ojú. 589

وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يُوعُونَ23

Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn).
84:24Júzù 30 · ojú. 589

فَبَشِّرْهُمْ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ24

Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
84:25Júzù 30 · ojú. 590

إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ25

Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pin ń bẹ fún wọn.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà