إِذَا السَّمَاءُ انْفَطَرَتْ1
Al-Infitar
سورة الإنفطار
Súrà 82 · Mákí · 19 àwọn ẹsẹ
82:1Júzù 30 · ojú. 587
Nígbà tí sánmọ̀ bá fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
82:2Júzù 30 · ojú. 587
وَإِذَا الْكَوَاكِبُ انْتَثَرَتْ2
àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
82:3Júzù 30 · ojú. 587
وَإِذَا الْبِحَارُ فُجِّرَتْ3
àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,
82:4Júzù 30 · ojú. 587
وَإِذَا الْقُبُورُ بُعْثِرَتْ4
àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,
82:5Júzù 30 · ojú. 587
عَلِمَتْ نَفْسٌ مَا قَدَّمَتْ وَأَخَّرَتْ5
(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
82:6Júzù 30 · ojú. 587
يَا أَيُّهَا الْإِنْسَانُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ الْكَرِيمِ6
Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,
82:7Júzù 30 · ojú. 587
الَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّاكَ فَعَدَلَكَ7
Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.
82:8Júzù 30 · ojú. 587
فِي أَيِّ صُورَةٍ مَا شَاءَ رَكَّبَكَ8
Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.
82:9Júzù 30 · ojú. 587
كَلَّا بَلْ تُكَذِّبُونَ بِالدِّينِ9
Ní ti òdodo, ńṣe l’ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́.
82:10Júzù 30 · ojú. 587
وَإِنَّ عَلَيْكُمْ لَحَافِظِينَ10
Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.
82:11Júzù 30 · ojú. 587
كِرَامًا كَاتِبِينَ11
(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.
82:12Júzù 30 · ojú. 587
يَعْلَمُونَ مَا تَفْعَلُونَ12
Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
82:13Júzù 30 · ojú. 587
إِنَّ الْأَبْرَارَ لَفِي نَعِيمٍ13
Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.
82:14Júzù 30 · ojú. 587
وَإِنَّ الْفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٍ14
Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.
82:15Júzù 30 · ojú. 587
يَصْلَوْنَهَا يَوْمَ الدِّينِ15
Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.
82:16Júzù 30 · ojú. 587
وَمَا هُمْ عَنْهَا بِغَائِبِينَ16
Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.
82:17Júzù 30 · ojú. 587
وَمَا أَدْرَاكَ مَا يَوْمُ الدِّينِ17
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
82:18Júzù 30 · ojú. 587
ثُمَّ مَا أَدْرَاكَ مَا يَوْمُ الدِّينِ18
Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
82:19Júzù 30 · ojú. 587
يَوْمَ لَا تَمْلِكُ نَفْسٌ لِنَفْسٍ شَيْئًا ۖ وَالْأَمْرُ يَوْمَئِذٍ لِلَّهِ19
(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.