Súrà 2 · Júzù 1

Al-Baqarah · 2:56

ثُمَّ بَعَثْنَاكُمْ مِنْ بَعْدِ مَوْتِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ

Lẹ́yìn náà, A ji yín dìde lẹ́yìn ikú yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).
____________________
Ikú tí wọ́n kú yìí jẹ́ ikú ìbáwí (bí irú ikú tí Allāhu s.w.t. sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah yìí kan náà, nínú āyah 259), kì í ṣe ikú òpin ìṣẹ̀mí tí ń kò lé gbogbo ẹ̀dá lórí n’ílé ayé. Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ta wọ́n jí padà s’ílé ayé kí wọ́n lè parí òǹkà àsìkò tí Ó ti bù fún ìṣẹ̀mí ayé wọn. Ẹ̀dá kan kò níí kú ikú òpin ìṣẹ̀mí kí ó tún padà s’ílé ayé mọ́. Nítorí náà, kò sí àkúdàáyà. Ète àwọn àlùjànnú kan ni. Ẹ ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 154 nínú sūrah yìí.

Tafsír

Kò sí tafsír ní èdè rẹ. Èyí ni Al-Mukhtasar ní èdè Gẹ̀ẹ́sì.

56. Then He brought you back to life after death so that you might be thankful to Him for the blessings He granted you in this way.

Ṣí nínú olùkà - Ka surah náà ní kíkún