At-Tin

سورة التين

Súrà 95 · Mákí · 8 àwọn ẹsẹ

95:1Júzù 30 · ojú. 597

وَالتِّينِ وَالزَّيْتُونِ1

Allāhu búra pẹ̀lú èso tīn àti èso zaetūn.
95:2Júzù 30 · ojú. 597

وَطُورِ سِينِينَ2

Ó tún búra pẹ̀lú àpáta Sīnīn.
95:3Júzù 30 · ojú. 597

وَهَٰذَا الْبَلَدِ الْأَمِينِ3

Ó tún búra pẹ̀lú ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí.
95:4Júzù 30 · ojú. 597

لَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ فِي أَحْسَنِ تَقْوِيمٍ4

Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí t’ó dára jùlọ.
95:5Júzù 30 · ojú. 597

ثُمَّ رَدَدْنَاهُ أَسْفَلَ سَافِلِينَ5

Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná).
95:6Júzù 30 · ojú. 597

إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَلَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ6

Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn.
95:7Júzù 30 · ojú. 597

فَمَا يُكَذِّبُكَ بَعْدُ بِالدِّينِ7

Ta l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)?
95:8Júzù 30 · ojú. 597

أَلَيْسَ اللَّهُ بِأَحْكَمِ الْحَاكِمِينَ8

Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni?

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Yasser Salama - At-Tin · Tlawati