An-Naba

سورة النبأ

Súrà 78 · Mákí · 40 àwọn ẹsẹ

78:1Júzù 30 · ojú. 582

عَمَّ يَتَسَاءَلُونَ1

Nípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná?
78:2Júzù 30 · ojú. 582

عَنِ النَّبَإِ الْعَظِيمِ2

Nípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni,
78:3Júzù 30 · ojú. 582

الَّذِي هُمْ فِيهِ مُخْتَلِفُونَ3

èyí tí wọ́n ń yapa ẹnu sí.
78:4Júzù 30 · ojú. 582

كَلَّا سَيَعْلَمُونَ4

Rárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.
78:5Júzù 30 · ojú. 582

ثُمَّ كَلَّا سَيَعْلَمُونَ5

Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.
78:6Júzù 30 · ojú. 582

أَلَمْ نَجْعَلِ الْأَرْضَ مِهَادًا6

Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí,
78:7Júzù 30 · ojú. 582

وَالْجِبَالَ أَوْتَادًا7

àti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)?
78:8Júzù 30 · ojú. 582

وَخَلَقْنَاكُمْ أَزْوَاجًا8

A sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo).
78:9Júzù 30 · ojú. 582

وَجَعَلْنَا نَوْمَكُمْ سُبَاتًا9

A ṣe oorun yín ní ìsinmi.
78:10Júzù 30 · ojú. 582

وَجَعَلْنَا اللَّيْلَ لِبَاسًا10

A tún ṣe alẹ́ ní ìbora.
78:11Júzù 30 · ojú. 582

وَجَعَلْنَا النَّهَارَ مَعَاشًا11

A tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu.
78:12Júzù 30 · ojú. 582

وَبَنَيْنَا فَوْقَكُمْ سَبْعًا شِدَادًا12

A tún mọ sánmọ̀ méje t’ó lágbára sókè yín.
78:13Júzù 30 · ojú. 582

وَجَعَلْنَا سِرَاجًا وَهَّاجًا13

A tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ t’ó ń tàn gbòlà.
78:14Júzù 30 · ojú. 582

وَأَنْزَلْنَا مِنَ الْمُعْصِرَاتِ مَاءً ثَجَّاجًا14

Àti pé A sọ omi t’ó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò
78:15Júzù 30 · ojú. 582

لِنُخْرِجَ بِهِ حَبًّا وَنَبَاتًا15

nítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde
78:16Júzù 30 · ojú. 582

وَجَنَّاتٍ أَلْفَافًا16

pẹ̀lú àwọn ọgbà t’ó kún digbí fún n̄ǹkan oko.
78:17Júzù 30 · ojú. 582

إِنَّ يَوْمَ الْفَصْلِ كَانَ مِيقَاتًا17

Dájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan.
78:18Júzù 30 · ojú. 582

يَوْمَ يُنْفَخُ فِي الصُّورِ فَتَأْتُونَ أَفْوَاجًا18

(Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ.
78:19Júzù 30 · ojú. 582

وَفُتِحَتِ السَّمَاءُ فَكَانَتْ أَبْوَابًا19

Wọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn.
78:20Júzù 30 · ojú. 582

وَسُيِّرَتِ الْجِبَالُ فَكَانَتْ سَرَابًا20

Wọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná.
78:21Júzù 30 · ojú. 582

إِنَّ جَهَنَّمَ كَانَتْ مِرْصَادًا21

Dájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà.
78:22Júzù 30 · ojú. 582

لِلطَّاغِينَ مَآبًا22

(Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ.
78:23Júzù 30 · ojú. 582

لَابِثِينَ فِيهَا أَحْقَابًا23

Wọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ.
78:24Júzù 30 · ojú. 582

لَا يَذُوقُونَ فِيهَا بَرْدًا وَلَا شَرَابًا24

Wọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀,
78:25Júzù 30 · ojú. 582

إِلَّا حَمِيمًا وَغَسَّاقًا25

àyàfi omi gbígbóná àti àwọyúnwẹ̀jẹ̀.
78:26Júzù 30 · ojú. 582

جَزَاءً وِفَاقًا26

(Ó jẹ́) ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn).
78:27Júzù 30 · ojú. 582

إِنَّهُمْ كَانُوا لَا يَرْجُونَ حِسَابًا27

Dájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́.
78:28Júzù 30 · ojú. 582

وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا كِذَّابًا28

Wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́ gan-an.
78:29Júzù 30 · ojú. 582

وَكُلَّ شَيْءٍ أَحْصَيْنَاهُ كِتَابًا29

Gbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan.
78:30Júzù 30 · ojú. 582

فَذُوقُوا فَلَنْ نَزِيدَكُمْ إِلَّا عَذَابًا30

Nítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fun yín bí kò ṣe ìyà.
78:31Júzù 30 · ojú. 583

إِنَّ لِلْمُتَّقِينَ مَفَازًا31

Dájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
78:32Júzù 30 · ojú. 583

حَدَائِقَ وَأَعْنَابًا32

Àwọn ọgbà àti èso àjàrà,
78:33Júzù 30 · ojú. 583

وَكَوَاعِبَ أَتْرَابًا33

àti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí,
78:34Júzù 30 · ojú. 583

وَكَأْسًا دِهَاقًا34

àti ife ọtí t’ó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn).
78:35Júzù 30 · ojú. 583

لَا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا وَلَا كِذَّابًا35

Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀.
78:36Júzù 30 · ojú. 583

جَزَاءً مِنْ رَبِّكَ عَطَاءً حِسَابًا36

(Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn).
78:37Júzù 30 · ojú. 583

رَبِّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا الرَّحْمَٰنِ ۖ لَا يَمْلِكُونَ مِنْهُ خِطَابًا37

(Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun t’ó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀.
78:38Júzù 30 · ojú. 583

يَوْمَ يَقُومُ الرُّوحُ وَالْمَلَائِكَةُ صَفًّا ۖ لَا يَتَكَلَّمُونَ إِلَّا مَنْ أَذِنَ لَهُ الرَّحْمَٰنُ وَقَالَ صَوَابًا38

Ọjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ t’ó ṣe wẹ́kú.
78:39Júzù 30 · ojú. 583

ذَٰلِكَ الْيَوْمُ الْحَقُّ ۖ فَمَنْ شَاءَ اتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِ مَآبًا39

Ìyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà).
78:40Júzù 30 · ojú. 583

إِنَّا أَنْذَرْنَاكُمْ عَذَابًا قَرِيبًا يَوْمَ يَنْظُرُ الْمَرْءُ مَا قَدَّمَتْ يَدَاهُ وَيَقُولُ الْكَافِرُ يَا لَيْتَنِي كُنْتُ تُرَابًا40

Dájúdájú A fi ìyà t’ó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fun yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: "Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà)."

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Yasser Salama - An-Naba · Tlawati