Al-Muddaththir

سورة المدثر

Súrà 74 · Mákí · 56 àwọn ẹsẹ

74:1Júzù 29 · ojú. 575

يَا أَيُّهَا الْمُدَّثِّرُ1

Ìwọ olùdaṣọbora.
74:2Júzù 29 · ojú. 575

قُمْ فَأَنْذِرْ2

Dìde kí o ṣèkìlọ̀.
74:3Júzù 29 · ojú. 575

وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ3

Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún.
74:4Júzù 29 · ojú. 575

وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ4

Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́.
74:5Júzù 29 · ojú. 575

وَالرُّجْزَ فَاهْجُرْ5

Òrìṣà ni kí o jìnnà sí.
74:6Júzù 29 · ojú. 575

وَلَا تَمْنُنْ تَسْتَكْثِرُ6

Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà.
74:7Júzù 29 · ojú. 575

وَلِرَبِّكَ فَاصْبِرْ7

Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún.
74:8Júzù 29 · ojú. 575

فَإِذَا نُقِرَ فِي النَّاقُورِ8

Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde,
74:9Júzù 29 · ojú. 575

فَذَٰلِكَ يَوْمَئِذٍ يَوْمٌ عَسِيرٌ9

ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira,
74:10Júzù 29 · ojú. 575

عَلَى الْكَافِرِينَ غَيْرُ يَسِيرٍ10

tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́.
74:11Júzù 29 · ojú. 575

ذَرْنِي وَمَنْ خَلَقْتُ وَحِيدًا11

Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan.
74:12Júzù 29 · ojú. 575

وَجَعَلْتُ لَهُ مَالًا مَمْدُودًا12

Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá
74:13Júzù 29 · ojú. 575

وَبَنِينَ شُهُودًا13

àti àwọn ọmọkúnrin t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.
74:14Júzù 29 · ojú. 575

وَمَهَّدْتُ لَهُ تَمْهِيدًا14

Mo sì ṣe ayé nírọ̀rùn fún un gan-an.
74:15Júzù 29 · ojú. 575

ثُمَّ يَطْمَعُ أَنْ أَزِيدَ15

Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún.
74:16Júzù 29 · ojú. 575

كَلَّا ۖ إِنَّهُ كَانَ لِآيَاتِنَا عَنِيدًا16

Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa.
74:17Júzù 29 · ojú. 575

سَأُرْهِقُهُ صَعُودًا17

Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná).
____________________
Orúkọ àpáta ńlá kan nínú Iná ni Sọ‘ūd. Kèfèrí yóò máa pọ́n òkè náà láààrin àádọ́rin ọdún ní àpọ́njábọ́. Ìdí nìyí tí wọ́n fi pe ìyà náà ní ìyà pọ́nkèpọ́nkè.
74:18Júzù 29 · ojú. 575

إِنَّهُ فَكَّرَ وَقَدَّرَ18

Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀).
74:19Júzù 29 · ojú. 576

فَقُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ19

Wọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
74:20Júzù 29 · ojú. 576

ثُمَّ قُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ20

Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
74:21Júzù 29 · ojú. 576

ثُمَّ نَظَرَ21

Lẹ́yìn náà, ó wò sùn.
74:22Júzù 29 · ojú. 576

ثُمَّ عَبَسَ وَبَسَرَ22

Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí.
74:23Júzù 29 · ojú. 576

ثُمَّ أَدْبَرَ وَاسْتَكْبَرَ23

Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìn dà, ó sì ṣègbéraga.
74:24Júzù 29 · ojú. 576

فَقَالَ إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ يُؤْثَرُ24

Ó sì wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́.
74:25Júzù 29 · ojú. 576

إِنْ هَٰذَا إِلَّا قَوْلُ الْبَشَرِ25

Kí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara"
74:26Júzù 29 · ojú. 576

سَأُصْلِيهِ سَقَرَ26

Èmi yóò fi sínú iná Saƙọr.
74:27Júzù 29 · ojú. 576

وَمَا أَدْرَاكَ مَا سَقَرُ27

Kí l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ iná Saƙọr?
74:28Júzù 29 · ojú. 576

لَا تُبْقِي وَلَا تَذَرُ28

(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì.
____________________
Ìyẹn ni pé, Iná náà yóò máa jó o lọ, kò sì níí gba ẹ̀mí rẹ̀.
74:29Júzù 29 · ojú. 576

لَوَّاحَةٌ لِلْبَشَرِ29

Ó máa jó awọ ara di dúdú.
74:30Júzù 29 · ojú. 576

عَلَيْهَا تِسْعَةَ عَشَرَ30

(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
74:31Júzù 29 · ojú. 576

وَمَا جَعَلْنَا أَصْحَابَ النَّارِ إِلَّا مَلَائِكَةً ۙ وَمَا جَعَلْنَا عِدَّتَهُمْ إِلَّا فِتْنَةً لِلَّذِينَ كَفَرُوا لِيَسْتَيْقِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَيَزْدَادَ الَّذِينَ آمَنُوا إِيمَانًا ۙ وَلَا يَرْتَابَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَالْمُؤْمِنُونَ ۙ وَلِيَقُولَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ وَالْكَافِرُونَ مَاذَا أَرَادَ اللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ اللَّهُ مَنْ يَشَاءُ وَيَهْدِي مَنْ يَشَاءُ ۚ وَمَا يَعْلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَ ۚ وَمَا هِيَ إِلَّا ذِكْرَىٰ لِلْبَشَرِ31

Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: "Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?" Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ̀ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara.
74:32Júzù 29 · ojú. 576

كَلَّا وَالْقَمَرِ32

Ẹ gbọ́! Allāhu búra pẹ̀lú òṣùpá.
74:33Júzù 29 · ojú. 576

وَاللَّيْلِ إِذْ أَدْبَرَ33

Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ.
74:34Júzù 29 · ojú. 576

وَالصُّبْحِ إِذَا أَسْفَرَ34

Ó tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́.
74:35Júzù 29 · ojú. 576

إِنَّهَا لَإِحْدَى الْكُبَرِ35

Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) t’ó tóbi.
74:36Júzù 29 · ojú. 576

نَذِيرًا لِلْبَشَرِ36

(Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara.
74:37Júzù 29 · ojú. 576

لِمَنْ شَاءَ مِنْكُمْ أَنْ يَتَقَدَّمَ أَوْ يَتَأَخَّرَ37

Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn.
74:38Júzù 29 · ojú. 576

كُلُّ نَفْسٍ بِمَا كَسَبَتْ رَهِينَةٌ38

Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun t’ó ṣe níṣẹ́.
74:39Júzù 29 · ojú. 576

إِلَّا أَصْحَابَ الْيَمِينِ39

Àyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
74:40Júzù 29 · ojú. 576

فِي جَنَّاتٍ يَتَسَاءَلُونَ40

Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra
74:41Júzù 29 · ojú. 576

عَنِ الْمُجْرِمِينَ41

nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé:
74:42Júzù 29 · ojú. 576

مَا سَلَكَكُمْ فِي سَقَرَ42

"Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr?"
74:43Júzù 29 · ojú. 576

قَالُوا لَمْ نَكُ مِنَ الْمُصَلِّينَ43

Wọn yóò wí pé: "Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni.
74:44Júzù 29 · ojú. 576

وَلَمْ نَكُ نُطْعِمُ الْمِسْكِينَ44

Àwa kò sì sí nínú àwọn t’ó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
74:45Júzù 29 · ojú. 576

وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ الْخَائِضِينَ45

Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ.
74:46Júzù 29 · ojú. 576

وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوْمِ الدِّينِ46

Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́
74:47Júzù 29 · ojú. 576

حَتَّىٰ أَتَانَا الْيَقِينُ47

títí ikú fi dé bá wa."
74:48Júzù 29 · ojú. 577

فَمَا تَنْفَعُهُمْ شَفَاعَةُ الشَّافِعِينَ48

Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní.
74:49Júzù 29 · ojú. 577

فَمَا لَهُمْ عَنِ التَّذْكِرَةِ مُعْرِضِينَ49

Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí
74:50Júzù 29 · ojú. 577

كَأَنَّهُمْ حُمُرٌ مُسْتَنْفِرَةٌ50

bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ t’ó ń sá lọ,
74:51Júzù 29 · ojú. 577

فَرَّتْ مِنْ قَسْوَرَةٍ51

t’ó sá fún kìnìhún?
74:52Júzù 29 · ojú. 577

بَلْ يُرِيدُ كُلُّ امْرِئٍ مِنْهُمْ أَنْ يُؤْتَىٰ صُحُفًا مُنَشَّرَةً52

Rárá, ńṣe ni ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān).
74:53Júzù 29 · ojú. 577

كَلَّا ۖ بَلْ لَا يَخَافُونَ الْآخِرَةَ53

Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni.
74:54Júzù 29 · ojú. 577

كَلَّا إِنَّهُ تَذْكِرَةٌ54

Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
74:55Júzù 29 · ojú. 577

فَمَنْ شَاءَ ذَكَرَهُ55

Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kó rántí rẹ̀.
74:56Júzù 29 · ojú. 577

وَمَا يَذْكُرُونَ إِلَّا أَنْ يَشَاءَ اللَّهُ ۚ هُوَ أَهْلُ التَّقْوَىٰ وَأَهْلُ الْمَغْفِرَةِ56

Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì làforíjìn.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Yasser Salama - Al-Muddaththir · Tlawati