Al-Waqi'ah

سورة الواقعة

Súrà 56 · Mákí · 96 àwọn ẹsẹ

56:1Júzù 27 · ojú. 534

إِذَا وَقَعَتِ الْوَاقِعَةُ1

Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀,
56:2Júzù 27 · ojú. 534

لَيْسَ لِوَقْعَتِهَا كَاذِبَةٌ2

- kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-E4983
56:3Júzù 27 · ojú. 534

خَافِضَةٌ رَافِعَةٌ3

ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra).
56:4Júzù 27 · ojú. 534

إِذَا رُجَّتِ الْأَرْضُ رَجًّا4

Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì,
56:5Júzù 27 · ojú. 534

وَبُسَّتِ الْجِبَالُ بَسًّا5

àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú,
56:6Júzù 27 · ojú. 534

فَكَانَتْ هَبَاءً مُنْبَثًّا6

- wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù - E4987
56:7Júzù 27 · ojú. 534

وَكُنْتُمْ أَزْوَاجًا ثَلَاثَةً7

ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.
____________________
Àwọn kristiẹni lérò pé āyah t’ó pín ẹ̀dá sí mẹ́ta ní ọjọ́ Àjíǹde tako āyah t’ó pín wọn sí ìjọ méjì.
Èsì: Kò sí ìtakora láààrin wọn. Nínú sūrah yìí, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ pé oríṣi ìjọ mẹ́ta ni àwọn ẹ̀dá máa pín sí ní ọjọ́ Àjíǹde. Ìjọ ọ̀tún, ìjọ òsì àti ìjọ aṣíwájú. Àmọ́ nínú sūrah al-Balad; 90:18-19 àti sūrah az-Zalzalah; 99:6-8, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pín wọn sí ìjọ méjì. Ìjọ méjì kúkú ni gbogbo ẹ̀dá ní ọ̀run, ìjọ ọ̀tún àti ìjọ òsì nítorí pé, Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún ìjọ ọ̀tún, Ọgbà Iná sì wá fún ìjọ òsì. Àmọ́, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe àtúnpín ìjọ ọ̀tún sí ìjọ ọ̀tún àti ìjọ aṣíwájú nítorí pé, ìgbádùn ìkíní kejì yàtọ̀ gan-an síra wọn. Ìdí nìyí tí Allāhu fi sọ nípa ìgbádùn ìjọ aṣíwájú láti āyah 10 sí āyah 26. Ó sọ nípa ìgbádùn ìjọ ọ̀tún láti āyah 27 sí āyah 40. Ó sì sọ nípa oníran-ànran ìyà ìjọ òsì láti āyah 41 sí āyah 56.
56:8Júzù 27 · ojú. 534

فَأَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ مَا أَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ8

Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún?
56:9Júzù 27 · ojú. 534

وَأَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ مَا أَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ9

Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
56:10Júzù 27 · ojú. 534

وَالسَّابِقُونَ السَّابِقُونَ10

Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú.
56:11Júzù 27 · ojú. 534

أُولَٰئِكَ الْمُقَرَّبُونَ11

Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)
56:12Júzù 27 · ojú. 534

فِي جَنَّاتِ النَّعِيمِ12

nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
56:13Júzù 27 · ojú. 534

ثُلَّةٌ مِنَ الْأَوَّلِينَ13

Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
56:14Júzù 27 · ojú. 534

وَقَلِيلٌ مِنَ الْآخِرِينَ14

Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.
56:15Júzù 27 · ojú. 534

عَلَىٰ سُرُرٍ مَوْضُونَةٍ15

(Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun.
56:16Júzù 27 · ojú. 534

مُتَّكِئِينَ عَلَيْهَا مُتَقَابِلِينَ16

Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn.
56:17Júzù 27 · ojú. 535

يَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَانٌ مُخَلَّدُونَ17

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn
56:18Júzù 27 · ojú. 535

بِأَكْوَابٍ وَأَبَارِيقَ وَكَأْسٍ مِنْ مَعِينٍ18

pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn.
56:19Júzù 27 · ojú. 535

لَا يُصَدَّعُونَ عَنْهَا وَلَا يُنْزِفُونَ19

Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà.
56:20Júzù 27 · ojú. 535

وَفَاكِهَةٍ مِمَّا يَتَخَيَّرُونَ20

Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn).
56:21Júzù 27 · ojú. 535

وَلَحْمِ طَيْرٍ مِمَّا يَشْتَهُونَ21

Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn).
56:22Júzù 27 · ojú. 535

وَحُورٌ عِينٌ22

Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn).
56:23Júzù 27 · ojú. 535

كَأَمْثَالِ اللُّؤْلُؤِ الْمَكْنُونِ23

Wọ́n dà bí òkúta olówó-iyebíye tí wọ́n fi pamọ́.
56:24Júzù 27 · ojú. 535

جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ24

(Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
56:25Júzù 27 · ojú. 535

لَا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا وَلَا تَأْثِيمًا25

Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
56:26Júzù 27 · ojú. 535

إِلَّا قِيلًا سَلَامًا سَلَامًا26

Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà.
56:27Júzù 27 · ojú. 535

وَأَصْحَابُ الْيَمِينِ مَا أَصْحَابُ الْيَمِينِ27

Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún?
56:28Júzù 27 · ojú. 535

فِي سِدْرٍ مَخْضُودٍ28

(Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún,
56:29Júzù 27 · ojú. 535

وَطَلْحٍ مَنْضُودٍ29

àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ t’ó so jìgbìnnì,
56:30Júzù 27 · ojú. 535

وَظِلٍّ مَمْدُودٍ30

àti ibòji t’ó gbòòrò,
56:31Júzù 27 · ojú. 535

وَمَاءٍ مَسْكُوبٍ31

àti omi t’ó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró,
56:32Júzù 27 · ojú. 535

وَفَاكِهَةٍ كَثِيرَةٍ32

àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso,
56:33Júzù 27 · ojú. 535

لَا مَقْطُوعَةٍ وَلَا مَمْنُوعَةٍ33

tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn).
56:34Júzù 27 · ojú. 535

وَفُرُشٍ مَرْفُوعَةٍ34

(Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè.
56:35Júzù 27 · ojú. 535

إِنَّا أَنْشَأْنَاهُنَّ إِنْشَاءً35

Dájúdájú Àwa tún (àwọn obìnrin wọn) dá ní ẹ̀dá ọ̀tun.
56:36Júzù 27 · ojú. 535

فَجَعَلْنَاهُنَّ أَبْكَارًا36

A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá,
56:37Júzù 27 · ojú. 535

عُرُبًا أَتْرَابًا37

olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí.
56:38Júzù 27 · ojú. 535

لِأَصْحَابِ الْيَمِينِ38

(Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
56:39Júzù 27 · ojú. 535

ثُلَّةٌ مِنَ الْأَوَّلِينَ39

Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
56:40Júzù 27 · ojú. 535

وَثُلَّةٌ مِنَ الْآخِرِينَ40

Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.
____________________
Àwọn ẹni àkọ́kọ́ dúró fún àwọn ènìyàn láti àsìkò Ànábì Ādam títí di àsìkò Ànábì ‘Īsā (aleehim sọlātu wa salām). Àwọn ẹni Ìkẹ́yìn sì dúró fún ìjọ Ànábì wa nìkan (sollalāhu 'alayhi wa sallam).
56:41Júzù 27 · ojú. 535

وَأَصْحَابُ الشِّمَالِ مَا أَصْحَابُ الشِّمَالِ41

Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
56:42Júzù 27 · ojú. 535

فِي سَمُومٍ وَحَمِيمٍ42

(Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná àti omi gbígbóná,
56:43Júzù 27 · ojú. 535

وَظِلٍّ مِنْ يَحْمُومٍ43

àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú,
56:44Júzù 27 · ojú. 535

لَا بَارِدٍ وَلَا كَرِيمٍ44

kò tutù, kò sì dára.
56:45Júzù 27 · ojú. 535

إِنَّهُمْ كَانُوا قَبْلَ ذَٰلِكَ مُتْرَفِينَ45

Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn.
56:46Júzù 27 · ojú. 535

وَكَانُوا يُصِرُّونَ عَلَى الْحِنْثِ الْعَظِيمِ46

Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
56:47Júzù 27 · ojú. 535

وَكَانُوا يَقُولُونَ أَئِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ47

Wọ́n sì máa ń wí pé: "Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
56:48Júzù 27 · ojú. 535

أَوَآبَاؤُنَا الْأَوَّلُونَ48

Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?"
56:49Júzù 27 · ojú. 535

قُلْ إِنَّ الْأَوَّلِينَ وَالْآخِرِينَ49

Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn,
56:50Júzù 27 · ojú. 535

لَمَجْمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَاتِ يَوْمٍ مَعْلُومٍ50

dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀."
56:51Júzù 27 · ojú. 536

ثُمَّ إِنَّكُمْ أَيُّهَا الضَّالُّونَ الْمُكَذِّبُونَ51

Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́,
56:52Júzù 27 · ojú. 536

لَآكِلُونَ مِنْ شَجَرٍ مِنْ زَقُّومٍ52

dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ).
56:53Júzù 27 · ojú. 536

فَمَالِئُونَ مِنْهَا الْبُطُونَ53

Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà.
56:54Júzù 27 · ojú. 536

فَشَارِبُونَ عَلَيْهِ مِنَ الْحَمِيمِ54

Ẹ̀yin yó sì máa mu omi gbígbóná lé e lórí.
56:55Júzù 27 · ojú. 536

فَشَارِبُونَ شُرْبَ الْهِيمِ55

Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ.
56:56Júzù 27 · ojú. 536

هَٰذَا نُزُلُهُمْ يَوْمَ الدِّينِ56

Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san.
56:57Júzù 27 · ojú. 536

نَحْنُ خَلَقْنَاكُمْ فَلَوْلَا تُصَدِّقُونَ57

Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ lódodo!
56:58Júzù 27 · ojú. 536

أَفَرَأَيْتُمْ مَا تُمْنُونَ58

Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́),
56:59Júzù 27 · ojú. 536

أَأَنْتُمْ تَخْلُقُونَهُ أَمْ نَحْنُ الْخَالِقُونَ59

ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀?
56:60Júzù 27 · ojú. 536

نَحْنُ قَدَّرْنَا بَيْنَكُمُ الْمَوْتَ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ60

Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Àwa kò sì lè kágara
56:61Júzù 27 · ojú. 536

عَلَىٰ أَنْ نُبَدِّلَ أَمْثَالَكُمْ وَنُنْشِئَكُمْ فِي مَا لَا تَعْلَمُونَ61

láti fi irú yín pààrọ̀ yín, kí á sì tun yín dá sínú ohun tí ẹ kò mọ̀.
56:62Júzù 27 · ojú. 536

وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ النَّشْأَةَ الْأُولَىٰ فَلَوْلَا تَذَكَّرُونَ62

Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́, ẹ ò ṣe lo ìrántí?
56:63Júzù 27 · ojú. 536

أَفَرَأَيْتُمْ مَا تَحْرُثُونَ63

Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀,
56:64Júzù 27 · ojú. 536

أَأَنْتُمْ تَزْرَعُونَهُ أَمْ نَحْنُ الزَّارِعُونَ64

ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde ni tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde?
56:65Júzù 27 · ojú. 536

لَوْ نَشَاءُ لَجَعَلْنَاهُ حُطَامًا فَظَلْتُمْ تَفَكَّهُونَ65

Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀).
56:66Júzù 27 · ojú. 536

إِنَّا لَمُغْرَمُونَ66

(Ẹ̀yin yó sì wí pé:) "Dájúdájú àwa ti di onígbèsè."
56:67Júzù 27 · ojú. 536

بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ67

(Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) "Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni."
56:68Júzù 27 · ojú. 536

أَفَرَأَيْتُمُ الْمَاءَ الَّذِي تَشْرَبُونَ68

Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu,
56:69Júzù 27 · ojú. 536

أَأَنْتُمْ أَنْزَلْتُمُوهُ مِنَ الْمُزْنِ أَمْ نَحْنُ الْمُنْزِلُونَ69

ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀?
56:70Júzù 27 · ojú. 536

لَوْ نَشَاءُ جَعَلْنَاهُ أُجَاجًا فَلَوْلَا تَشْكُرُونَ70

Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi t’ó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́?
56:71Júzù 27 · ojú. 536

أَفَرَأَيْتُمُ النَّارَ الَّتِي تُورُونَ71

Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá,
56:72Júzù 27 · ojú. 536

أَأَنْتُمْ أَنْشَأْتُمْ شَجَرَتَهَا أَمْ نَحْنُ الْمُنْشِئُونَ72

ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá?
56:73Júzù 27 · ojú. 536

نَحْنُ جَعَلْنَاهَا تَذْكِرَةً وَمَتَاعًا لِلْمُقْوِينَ73

Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò.
56:74Júzù 27 · ojú. 536

فَسَبِّحْ بِاسْمِ رَبِّكَ الْعَظِيمِ74

Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.
56:75Júzù 27 · ojú. 536

۞ فَلَا أُقْسِمُ بِمَوَاقِعِ النُّجُومِ75

Mò ń búra pẹ̀lú àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀.
56:76Júzù 27 · ojú. 536

وَإِنَّهُ لَقَسَمٌ لَوْ تَعْلَمُونَ عَظِيمٌ76

Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀.
56:77Júzù 27 · ojú. 537

إِنَّهُ لَقُرْآنٌ كَرِيمٌ77

Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé,
56:78Júzù 27 · ojú. 537

فِي كِتَابٍ مَكْنُونٍ78

(t’ó wà) nínú Tírà ààbò (nínú Laohul-Mahfūṭḥ).

لَا يَمَسُّهُ إِلَّا الْمُطَهَّرُونَ79

Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika).
56:80Júzù 27 · ojú. 537

تَنْزِيلٌ مِنْ رَبِّ الْعَالَمِينَ80

Wọ́n sọ̀ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
56:81Júzù 27 · ojú. 537

أَفَبِهَٰذَا الْحَدِيثِ أَنْتُمْ مُدْهِنُونَ81

Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè nírọ́?
56:82Júzù 27 · ojú. 537

وَتَجْعَلُونَ رِزْقَكُمْ أَنَّكُمْ تُكَذِّبُونَ82

Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo nírọ́.
____________________
Ìyẹn ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ ń dúpẹ́ fún ìràwọ̀ nítorí pé, wọ́n gbàgbọ́ pé òhun l’ó ń rọ̀jò lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Irọ́ ni èyí àti àìgbàgbọ́ nínú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), Ẹni t’Ó ń rọ̀jò fún ẹ̀dá Rẹ̀.
56:83Júzù 27 · ojú. 537

فَلَوْلَا إِذَا بَلَغَتِ الْحُلْقُومَ83

Kí ni ó máa ti rí (fun yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun,
56:84Júzù 27 · ojú. 537

وَأَنْتُمْ حِينَئِذٍ تَنْظُرُونَ84

tí ẹ̀yin yó sì máa wòran nígbà yẹn?
56:85Júzù 27 · ojú. 537

وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنْكُمْ وَلَٰكِنْ لَا تُبْصِرُونَ85

Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mujādilah; 58:7.
56:86Júzù 27 · ojú. 537

فَلَوْلَا إِنْ كُنْتُمْ غَيْرَ مَدِينِينَ86

Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀,
56:87Júzù 27 · ojú. 537

تَرْجِعُونَهَا إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ87

kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
56:88Júzù 27 · ojú. 537

فَأَمَّا إِنْ كَانَ مِنَ الْمُقَرَّبِينَ88

Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa),
56:89Júzù 27 · ojú. 537

فَرَوْحٌ وَرَيْحَانٌ وَجَنَّتُ نَعِيمٍ89

ìsinmi, èsè t’ó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀).
56:90Júzù 27 · ojú. 537

وَأَمَّا إِنْ كَانَ مِنْ أَصْحَابِ الْيَمِينِ90

Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún,
56:91Júzù 27 · ojú. 537

فَسَلَامٌ لَكَ مِنْ أَصْحَابِ الْيَمِينِ91

àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
56:92Júzù 27 · ojú. 537

وَأَمَّا إِنْ كَانَ مِنَ الْمُكَذِّبِينَ الضَّالِّينَ92

Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà,
56:93Júzù 27 · ojú. 537

فَنُزُلٌ مِنْ حَمِيمٍ93

n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi gbígbóná
56:94Júzù 27 · ojú. 537

وَتَصْلِيَةُ جَحِيمٍ94

àti wíwọ inú iná Jẹhīm.
56:95Júzù 27 · ojú. 537

إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ حَقُّ الْيَقِينِ95

Dájúdájú èyí, òhun ni òdodo t’ó dájú.
56:96Júzù 27 · ojú. 537

فَسَبِّحْ بِاسْمِ رَبِّكَ الْعَظِيمِ96

Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Yasser Salama - Al-Waqi'ah · Tlawati