An-Najm

سورة النجم

Súrà 53 · Mákí · 62 àwọn ẹsẹ

53:1Júzù 27 · ojú. 526

وَالنَّجْمِ إِذَا هَوَىٰ1

(Allāhu búra pẹ̀lú) ìràwọ̀ nígbà tí ó bá jábọ́.
53:2Júzù 27 · ojú. 526

مَا ضَلَّ صَاحِبُكُمْ وَمَا غَوَىٰ2

Ẹni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù.
53:3Júzù 27 · ojú. 526

وَمَا يَنْطِقُ عَنِ الْهَوَىٰ3

Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú.
53:4Júzù 27 · ojú. 526

إِنْ هُوَ إِلَّا وَحْيٌ يُوحَىٰ4

Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i.
53:5Júzù 27 · ojú. 526

عَلَّمَهُ شَدِيدُ الْقُوَىٰ5

Alágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l’ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān).
53:6Júzù 27 · ojú. 526

ذُو مِرَّةٍ فَاسْتَوَىٰ6

Ó ní àlàáfíà t’ó péye. Nítorí náà, ó dúró wámúwámú,
53:7Júzù 27 · ojú. 526

وَهُوَ بِالْأُفُقِ الْأَعْلَىٰ7

nígbà tí ó wà nínú òfurufú lókè pátápátá.
53:8Júzù 27 · ojú. 526

ثُمَّ دَنَا فَتَدَلَّىٰ8

Lẹ́yìn náà, ó sún mọ́ (Ànábì). Ó sì sọ̀kalẹ̀ (tọ̀ ọ́ wá).
53:9Júzù 27 · ojú. 526

فَكَانَ قَابَ قَوْسَيْنِ أَوْ أَدْنَىٰ9

(Àlàfo ààrin àwọn méjèèjì) sì tó ìwọ̀n ọrún ọfà méjì, tàbí kí ó kéré (sí ìyẹn).
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:74.
53:10Júzù 27 · ojú. 526

فَأَوْحَىٰ إِلَىٰ عَبْدِهِ مَا أَوْحَىٰ10

Allāhu sì fún ẹrúsìn Rẹ̀ ní ìmísí t’Ó fún un.
53:11Júzù 27 · ojú. 526

مَا كَذَبَ الْفُؤَادُ مَا رَأَىٰ11

Ọkàn (Ànábì) kò parọ́ ohun t’ó rí.
53:12Júzù 27 · ojú. 526

أَفَتُمَارُونَهُ عَلَىٰ مَا يَرَىٰ12

Ṣé ẹ óò jà á níyàn nípa ohun t’ó rí ni?
53:13Júzù 27 · ojú. 526

وَلَقَدْ رَآهُ نَزْلَةً أُخْرَىٰ13

Àti pé dájúdájú ó rí i nígbà kejì
____________________
Gbólóhùn “rọ’āhu” jẹyọ nínú āyah yìí. Ó tún jẹyọ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah at-Tẹkwīr; 81:23. Ìtúmọ̀ rẹ̀ sì ni pé, “Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rí i.” Ta ni ó rí? Ṣé Allāhu ni tàbí mọlāika Jibrīl? Àní sẹ́, ta ni ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ẹnì kẹta yìí “hu” t’ó jẹyọ nínú gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí? Kí á má gbàgbé pé āyah yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa ìrìn-àjò òru àti ìgun sánmọ̀ tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ṣe ni.
Èsì: Àwọn igun kan nínú àwọn àáfà sọ pé, mọlāika Jibrīl ni Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rí. Igun kejì sì sọ pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni ó rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igun yìí fi kún un pé ọkàn l’ó fi rí Allāhu, kì í ṣe ojú. Ṣebí bí ẹ̀dá ṣe ní ojú ìta, ni ó ní ojú inú. Àmọ́ èyí tí ó gbéwọ̀n jùlọ lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām ni pé, orúkọ mọlāika Jibrīl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni “hu” yẹn ń rọ́pò. Ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni hadīth tí ìyá wa ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā) gbàwá lórí ọ̀rọ̀ náà pé, “Èmi ni àkọ́kọ́ nínú ìjọ yìí tí ó béèrè nípa ìyẹn lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ó sì sọ pé. “Jibrīl ni mo rí.” (Muslim). Bákan náà, nínú ẹ̀gbàwá Abū Tharr (rọdiyallāhu 'anhu), ó sọ pé, mo bi Òjíṣẹ́ Allāhu ní ìbéèrè pé, “Ṣé o fojú rí Olúwa rẹ bí?” Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì sọ pé: “Ìmọ́lẹ̀ kan (dí mi lọ́wọ́), báwo ni mo ṣe máa rí I nígbà náà!” (Muslim) Irú èyí náà l’ó ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:143.
Tọ́ọ̀, ó ṣeé ṣe kí á rí ọ̀rọ̀ mìíràn kan láti ọ̀dọ̀ àwọn Sọhābah (r.ahm.), bíi ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu) wá pé, “Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi ọkàn rẹ̀ rí Allāhu ni.” Ìyẹn ni pé, ó fojú inú rí I, kì í ṣe ojú ìta. Kíyè sí i, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó lágbára tó èyí tí ó tọ̀dọ̀ Ànábì fúnra rẹ̀ wá tààrà lórí ọ̀rọ̀ náà. Ẹ̀gbàwá ‘Ā’iṣah àti ẹ̀gbàwá Abū Tharr sì ni ẹ̀gbàwá t’ó ti ọ̀dọ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) wá lórí ọ̀rọ̀ náà. Má ṣe fọkàn sí ibò míìràn. Àti pé, sūrah al-’Ani‘ām; 6:103 àti sūrah aṣ-Ṣūrā; 42:51 ti fi rinlẹ̀ pé, ojú kan kò lè fojú rinjú pẹ̀lú Allāhu, yálà fún gbígba iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu tàbí fún n̄ǹkan mìíràn. Àmọ́ sá, rírí Allāhu sójú máa wáyé fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nìkan lọ́jọ́ Àjíǹde. Èyí sì wà ní ìbámu sí sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:22-23.
53:14Júzù 27 · ojú. 526

عِنْدَ سِدْرَةِ الْمُنْتَهَىٰ14

níbi igi sidirah al-Muntahā,
53:15Júzù 27 · ojú. 526

عِنْدَهَا جَنَّةُ الْمَأْوَىٰ15

nítòsí rẹ̀ ni Ọgbà Ibùgbé (gbére) wà.
53:16Júzù 27 · ojú. 526

إِذْ يَغْشَى السِّدْرَةَ مَا يَغْشَىٰ16

(Rántí) nígbà tí ohun t’ó bo igi Sidirah bò ó mọ́lẹ̀.
53:17Júzù 27 · ojú. 526

مَا زَاغَ الْبَصَرُ وَمَا طَغَىٰ17

Ojú (Ànábì) kò yẹ̀, kò sì tayọ ẹnu-àlà.
53:18Júzù 27 · ojú. 526

لَقَدْ رَأَىٰ مِنْ آيَاتِ رَبِّهِ الْكُبْرَىٰ18

Dájúdájú ó rí nínú àwọn àmì Olúwa rẹ̀, t’ó tóbi jùlọ.
53:19Júzù 27 · ojú. 526

أَفَرَأَيْتُمُ اللَّاتَ وَالْعُزَّىٰ19

Ẹ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā,
53:20Júzù 27 · ojú. 526

وَمَنَاةَ الثَّالِثَةَ الْأُخْرَىٰ20

àti Mọnāh, òrìṣà kẹta mìíràn.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hajj 22:52.
53:21Júzù 27 · ojú. 526

أَلَكُمُ الذَّكَرُ وَلَهُ الْأُنْثَىٰ21

Ṣé ọmọkùnrin ni tiyín, ọmọbìnrin sì ni tiRẹ̀?
53:22Júzù 27 · ojú. 526

تِلْكَ إِذًا قِسْمَةٌ ضِيزَىٰ22

Ìpín àbòsí nìyẹn nígbà náà.
53:23Júzù 27 · ojú. 526

إِنْ هِيَ إِلَّا أَسْمَاءٌ سَمَّيْتُمُوهَا أَنْتُمْ وَآبَاؤُكُمْ مَا أَنْزَلَ اللَّهُ بِهَا مِنْ سُلْطَانٍ ۚ إِنْ يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَمَا تَهْوَى الْأَنْفُسُ ۖ وَلَقَدْ جَاءَهُمْ مِنْ رَبِّهِمُ الْهُدَىٰ23

(Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fi sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ àti ohun tí ẹ̀mí (wọn) ń fẹ́. Ìmọ̀nà kúkú ti dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.
53:24Júzù 27 · ojú. 526

أَمْ لِلْإِنْسَانِ مَا تَمَنَّىٰ24

Tàbí ti ènìyàn ni n̄ǹkan t’ó bá ń fẹ́!
53:25Júzù 27 · ojú. 526

فَلِلَّهِ الْآخِرَةُ وَالْأُولَىٰ25

Ti Allāhu sì ni ọ̀run àti ayé.
53:26Júzù 27 · ojú. 526

۞ وَكَمْ مِنْ مَلَكٍ فِي السَّمَاوَاتِ لَا تُغْنِي شَفَاعَتُهُمْ شَيْئًا إِلَّا مِنْ بَعْدِ أَنْ يَأْذَنَ اللَّهُ لِمَنْ يَشَاءُ وَيَرْضَىٰ26

Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn mọlāika t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀, tí ìṣìpẹ̀ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan àyàfi lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu bá yọ̀ǹda fún ẹni tí Ó bá fẹ́, tí Ó sì yọ́nú sí.
53:27Júzù 27 · ojú. 527

إِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ لَيُسَمُّونَ الْمَلَائِكَةَ تَسْمِيَةَ الْأُنْثَىٰ27

Dájúdájú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn mọlāika ní orúkọ obìnrin.
53:28Júzù 27 · ojú. 527

وَمَا لَهُمْ بِهِ مِنْ عِلْمٍ ۖ إِنْ يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ ۖ وَإِنَّ الظَّنَّ لَا يُغْنِي مِنَ الْحَقِّ شَيْئًا28

Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ. Dájúdájú àròsọ kò sì níí rọrọ̀ kiní kan lára òdodo.
53:29Júzù 27 · ojú. 527

فَأَعْرِضْ عَنْ مَنْ تَوَلَّىٰ عَنْ ذِكْرِنَا وَلَمْ يُرِدْ إِلَّا الْحَيَاةَ الدُّنْيَا29

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni t’ó kẹ̀yìn sí ìrántí Wa, tí kò sì gbèrò kiní kan àfi ìṣẹ̀mí ayé.
53:30Júzù 27 · ojú. 527

ذَٰلِكَ مَبْلَغُهُمْ مِنَ الْعِلْمِ ۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنْ ضَلَّ عَنْ سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ اهْتَدَىٰ30

Ìyẹn ni òdíwọ̀n (àti òpin) ìmọ̀ wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó mọ̀nà.
53:31Júzù 27 · ojú. 527

وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ لِيَجْزِيَ الَّذِينَ أَسَاءُوا بِمَا عَمِلُوا وَيَجْزِيَ الَّذِينَ أَحْسَنُوا بِالْحُسْنَى31

Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ nítorí kí Ó lè san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere.
53:32Júzù 27 · ojú. 527

الَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَائِرَ الْإِثْمِ وَالْفَوَاحِشَ إِلَّا اللَّمَمَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ وَاسِعُ الْمَغْفِرَةِ ۚ هُوَ أَعْلَمُ بِكُمْ إِذْ أَنْشَأَكُمْ مِنَ الْأَرْضِ وَإِذْ أَنْتُمْ أَجِنَّةٌ فِي بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ ۖ فَلَا تُزَكُّوا أَنْفُسَكُمْ ۖ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ اتَّقَىٰ32

Àwọn t’ó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́. Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀).
53:33Júzù 27 · ojú. 527

أَفَرَأَيْتَ الَّذِي تَوَلَّىٰ33

Sọ fún mi nípa ẹni t’ó gbúnrí (kúrò níbi òdodo),
53:34Júzù 27 · ojú. 527

وَأَعْطَىٰ قَلِيلًا وَأَكْدَىٰ34

tí ó fi díẹ̀ tọrẹ, tí ó sì di ìyókù mọ́wọ́!
53:35Júzù 27 · ojú. 527

أَعِنْدَهُ عِلْمُ الْغَيْبِ فَهُوَ يَرَىٰ35

Ṣé ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí ó sì ń rí i (pé ẹlòmíìràn l’ó ma bá òun jìyà lọ́run)?
53:36Júzù 27 · ojú. 527

أَمْ لَمْ يُنَبَّأْ بِمَا فِي صُحُفِ مُوسَىٰ36

Tàbí wọn kò fún un ní ìró ohun t’ó wà nínú tírà (Ànábì) Mūsā ni,
53:37Júzù 27 · ojú. 527

وَإِبْرَاهِيمَ الَّذِي وَفَّىٰ37

àti (tírà Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ẹni t’ó mú (òfin Allāhu) ṣẹ,
53:38Júzù 27 · ojú. 527

أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ38

pé dájúdájú ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nahl; 16:25.
53:39Júzù 27 · ojú. 527

وَأَنْ لَيْسَ لِلْإِنْسَانِ إِلَّا مَا سَعَىٰ39

Àti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun t’ó ṣe níṣẹ́.
53:40Júzù 27 · ojú. 527

وَأَنَّ سَعْيَهُ سَوْفَ يُرَىٰ40

Àti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án.
53:41Júzù 27 · ojú. 527

ثُمَّ يُجْزَاهُ الْجَزَاءَ الْأَوْفَىٰ41

Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san t’ó kún jùlọ.
53:42Júzù 27 · ojú. 527

وَأَنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ الْمُنْتَهَىٰ42

Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá).
53:43Júzù 27 · ojú. 527

وَأَنَّهُ هُوَ أَضْحَكَ وَأَبْكَىٰ43

Dájúdájú Òun l’Ó ń pa (ẹ̀dá) ní ẹ̀rín. Ó sì ń pa (ẹ̀dá) ní ẹkún.
53:44Júzù 27 · ojú. 527

وَأَنَّهُ هُوَ أَمَاتَ وَأَحْيَا44

Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ (ẹ̀dá) di òkú. Ó sì ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè.
53:45Júzù 27 · ojú. 528

وَأَنَّهُ خَلَقَ الزَّوْجَيْنِ الذَّكَرَ وَالْأُنْثَىٰ45

Dájúdájú Òun l’Ó dá ẹ̀dá ní oríṣi méjì, ọkùnrin àti obìnrin,
____________________
Ẹ̀dá ènìyàn ni èròǹgbà nínú āyah yìí, kì í ṣe ẹ̀dá mìíràn. Āyah 46 l’ó fi èyí rinlẹ̀.
53:46Júzù 27 · ojú. 528

مِنْ نُطْفَةٍ إِذَا تُمْنَىٰ46

láti ara àtọ̀ nígbà tí wọ́n bá dà á sínú àpòlùkẹ́.
53:47Júzù 27 · ojú. 528

وَأَنَّ عَلَيْهِ النَّشْأَةَ الْأُخْرَىٰ47

Dájúdájú Òun l’Ó máa ṣe ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn fún àjíǹde,
53:48Júzù 27 · ojú. 528

وَأَنَّهُ هُوَ أَغْنَىٰ وَأَقْنَىٰ48

Dájúdájú Òun l’Ó ń ṣe púpọ̀, Ó sì ń ṣe kékeré (oore fún ẹ̀dá).
53:49Júzù 27 · ojú. 528

وَأَنَّهُ هُوَ رَبُّ الشِّعْرَىٰ49

Dájúdájú Òun sì ni Olúwa ìràwọ̀ Ṣi‘rọ̄ (tí wọ́n sọ di òrìṣà).
53:50Júzù 27 · ojú. 528

وَأَنَّهُ أَهْلَكَ عَادًا الْأُولَىٰ50

Dájúdájú Òun l’Ó pa ìran ‘Ād rẹ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́;
53:51Júzù 27 · ojú. 528

وَثَمُودَ فَمَا أَبْقَىٰ51

àti ìran Thamūd, kò sì ṣẹ́ wọn kù;
53:52Júzù 27 · ojú. 528

وَقَوْمَ نُوحٍ مِنْ قَبْلُ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا هُمْ أَظْلَمَ وَأَطْغَىٰ52

àti ìjọ Nūh t’ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ alábòsí jùlọ, wọ́n sì tayọ ẹnu-àlà jùlọ;
53:53Júzù 27 · ojú. 528

وَالْمُؤْتَفِكَةَ أَهْوَىٰ53

àti ìlú tí wọ́n dàwó (ìlú Ànábì Lūt) t’Ó yẹ̀ lulẹ̀ (láti òkè).
53:54Júzù 27 · ojú. 528

فَغَشَّاهَا مَا غَشَّىٰ54

Ohun t’ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀.
53:55Júzù 27 · ojú. 528

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكَ تَتَمَارَىٰ55

Nítorí náà, èwo nínú ìdẹ̀ra Olúwa rẹ ni ìwọ (ènìyàn) ń jà níyàn?
53:56Júzù 27 · ojú. 528

هَٰذَا نَذِيرٌ مِنَ النُّذُرِ الْأُولَىٰ56

Èyí ni ìkìlọ̀ kan nínú àwọn ìkìlọ̀ àkọ́kọ́.
53:57Júzù 27 · ojú. 528

أَزِفَتِ الْآزِفَةُ57

Ohun t’ó súnmọ́ súnmọ́.
____________________
“Ohun t’ó súnmọ́” jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ àjíǹde.
53:58Júzù 27 · ojú. 528

لَيْسَ لَهَا مِنْ دُونِ اللَّهِ كَاشِفَةٌ58

Lẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni t’ó lè ṣàfi hàn (Àkókò náà).
53:59Júzù 27 · ojú. 528

أَفَمِنْ هَٰذَا الْحَدِيثِ تَعْجَبُونَ59

Ṣé ọ̀rọ̀ yìí l’ó ń ṣe yín ní kàyéfì?
53:60Júzù 27 · ojú. 528

وَتَضْحَكُونَ وَلَا تَبْكُونَ60

Ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín, ẹ ò sì sunkún!
53:61Júzù 27 · ojú. 528

وَأَنْتُمْ سَامِدُونَ61

Afọ́nú-fọ́ra ni yín.
53:62Júzù 27 · ojú. 528

فَاسْجُدُوا لِلَّهِ وَاعْبُدُوا ۩62

Nítorí náà, ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, kí ẹ jọ́sìn (fún Un).

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Yasser Salama - An-Najm · Tlawati