As-Saffat

سورة الصافات

Súrà 37 · Mákí · 182 àwọn ẹsẹ

37:1Júzù 23 · ojú. 446

وَالصَّافَّاتِ صَفًّا1

(Allāhu búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika olùtò-lọ́wọ̀ọ̀wọ́ tààrà;
37:2Júzù 23 · ojú. 446

فَالزَّاجِرَاتِ زَجْرًا2

àti àwọn mọlāika t’ó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà;
37:3Júzù 23 · ojú. 446

فَالتَّالِيَاتِ ذِكْرًا3

àti àwọn mọlāika òǹké-tírà ìrántí.
37:4Júzù 23 · ojú. 446

إِنَّ إِلَٰهَكُمْ لَوَاحِدٌ4

Dájúdájú Ọlọ́hun yín, Ọ̀kan ṣoṣo ni;
37:5Júzù 23 · ojú. 446

رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَرَبُّ الْمَشَارِقِ5

Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn.
37:6Júzù 23 · ojú. 446

إِنَّا زَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِزِينَةٍ الْكَوَاكِبِ6

Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́
37:7Júzù 23 · ojú. 446

وَحِفْظًا مِنْ كُلِّ شَيْطَانٍ مَارِدٍ7

àti ìṣọ́ níbi (aburú) gbogbo èṣù olóríkunkun.
37:8Júzù 23 · ojú. 446

لَا يَسَّمَّعُونَ إِلَى الْمَلَإِ الْأَعْلَىٰ وَيُقْذَفُونَ مِنْ كُلِّ جَانِبٍ8

(Àwọn èṣù) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika t’ó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀). (Àwọn mọlāika) yó sì máa ku (àwọn èṣù) lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀).
37:9Júzù 23 · ojú. 446

دُحُورًا ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ وَاصِبٌ9

Wọ́n ń lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn.
37:10Júzù 23 · ojú. 446

إِلَّا مَنْ خَطِفَ الْخَطْفَةَ فَأَتْبَعَهُ شِهَابٌ ثَاقِبٌ10

(Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní kíkún) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná t’ó máa jó o tẹ̀lé e.
37:11Júzù 23 · ojú. 446

فَاسْتَفْتِهِمْ أَهُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَمْ مَنْ خَلَقْنَا ۚ إِنَّا خَلَقْنَاهُمْ مِنْ طِينٍ لَازِبٍ11

Bi wọ́n léèrè wò pé ṣé àwọn ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (ènìyàn) tí A dá? Dájúdájú Àwa dá wọn láti ara erùpẹ̀ t’ó lẹ̀ mọ́ra wọn.
37:12Júzù 23 · ojú. 446

بَلْ عَجِبْتَ وَيَسْخَرُونَ12

Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́.
37:13Júzù 23 · ojú. 446

وَإِذَا ذُكِّرُوا لَا يَذْكُرُونَ13

Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí.
37:14Júzù 23 · ojú. 446

وَإِذَا رَأَوْا آيَةً يَسْتَسْخِرُونَ14

Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́.
37:15Júzù 23 · ojú. 446

وَقَالُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُبِينٌ15

Wọ́n sì wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.
37:16Júzù 23 · ojú. 446

أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ16

Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
37:17Júzù 23 · ojú. 446

أَوَآبَاؤُنَا الْأَوَّلُونَ17

Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?"
37:18Júzù 23 · ojú. 446

قُلْ نَعَمْ وَأَنْتُمْ دَاخِرُونَ18

Sọ pé: "Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ."
37:19Júzù 23 · ojú. 446

فَإِنَّمَا هِيَ زَجْرَةٌ وَاحِدَةٌ فَإِذَا هُمْ يَنْظُرُونَ19

Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn.
37:20Júzù 23 · ojú. 446

وَقَالُوا يَا وَيْلَنَا هَٰذَا يَوْمُ الدِّينِ20

Wọ́n á wí pé: "Ègbé wa! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san."
37:21Júzù 23 · ojú. 446

هَٰذَا يَوْمُ الْفَصْلِ الَّذِي كُنْتُمْ بِهِ تُكَذِّبُونَ21

Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè nírọ́.
37:22Júzù 23 · ojú. 446

۞ احْشُرُوا الَّذِينَ ظَلَمُوا وَأَزْوَاجَهُمْ وَمَا كَانُوا يَعْبُدُونَ22

Ẹ kó àwọn t’ó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún
37:23Júzù 23 · ojú. 446

مِنْ دُونِ اللَّهِ فَاهْدُوهُمْ إِلَىٰ صِرَاطِ الْجَحِيمِ23

lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm.
37:24Júzù 23 · ojú. 446

وَقِفُوهُمْ ۖ إِنَّهُمْ مَسْئُولُونَ24

Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè.
37:25Júzù 23 · ojú. 447

مَا لَكُمْ لَا تَنَاصَرُونَ25

Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ranra yín lọ́wọ́?
37:26Júzù 23 · ojú. 447

بَلْ هُمُ الْيَوْمَ مُسْتَسْلِمُونَ26

Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni.
37:27Júzù 23 · ojú. 447

وَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَسَاءَلُونَ27

Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mu’minūn; 23:101.
37:28Júzù 23 · ojú. 447

قَالُوا إِنَّكُمْ كُنْتُمْ تَأْتُونَنَا عَنِ الْيَمِينِ28

(Àwọn ènìyàn) wí pé: "Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà)."
____________________
Gbígba ọ̀tún wọlé sí ni lára ni pé, wọ́n ń lo orúkọ ’Islām láti fi pe àwọn ènìyàn lọ síbi ìṣẹbọ dípò mímú Allāhu ní Ọ̀kan ṣoṣo. Àpẹẹrẹ àwọn wọ̀nyí ni àwọn àáfà tí wọ́n bá àwọn àlùjọ̀nnú dòwò pọ̀ tán, tí wọ́n sọra wọn di oníṣẹ́-ìyanu àti àwọn onibidiah bí ìjọ Ahmadiyyah àti ìjọ Tijāniyyah.
37:29Júzù 23 · ojú. 447

قَالُوا بَلْ لَمْ تَكُونُوا مُؤْمِنِينَ29

(Àwọn àlùjànnú) wí pé: "Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
37:30Júzù 23 · ojú. 447

وَمَا كَانَ لَنَا عَلَيْكُمْ مِنْ سُلْطَانٍ ۖ بَلْ كُنْتُمْ قَوْمًا طَاغِينَ30

Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu àlà.
37:31Júzù 23 · ojú. 447

فَحَقَّ عَلَيْنَا قَوْلُ رَبِّنَا ۖ إِنَّا لَذَائِقُونَ31

Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò.
37:32Júzù 23 · ojú. 447

فَأَغْوَيْنَاكُمْ إِنَّا كُنَّا غَاوِينَ32

Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà."
37:33Júzù 23 · ojú. 447

فَإِنَّهُمْ يَوْمَئِذٍ فِي الْعَذَابِ مُشْتَرِكُونَ33

Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà.
37:34Júzù 23 · ojú. 447

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَفْعَلُ بِالْمُجْرِمِينَ34

Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
37:35Júzù 23 · ojú. 447

إِنَّهُمْ كَانُوا إِذَا قِيلَ لَهُمْ لَا إِلَٰهَ إِلَّا اللَّهُ يَسْتَكْبِرُونَ35

Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé "Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.", wọn yóò máa ṣègbéraga.
37:36Júzù 23 · ojú. 447

وَيَقُولُونَ أَئِنَّا لَتَارِكُو آلِهَتِنَا لِشَاعِرٍ مَجْنُونٍ36

Wọ́n sì ń wí pé: "Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan?"
37:37Júzù 23 · ojú. 447

بَلْ جَاءَ بِالْحَقِّ وَصَدَّقَ الْمُرْسَلِينَ37

Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà.
37:38Júzù 23 · ojú. 447

إِنَّكُمْ لَذَائِقُو الْعَذَابِ الْأَلِيمِ38

Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.
37:39Júzù 23 · ojú. 447

وَمَا تُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ39

A ò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
37:40Júzù 23 · ojú. 447

إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ40

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà.
37:41Júzù 23 · ojú. 447

أُولَٰئِكَ لَهُمْ رِزْقٌ مَعْلُومٌ41

Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀;
37:42Júzù 23 · ojú. 447

فَوَاكِهُ ۖ وَهُمْ مُكْرَمُونَ42

àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé
37:43Júzù 23 · ojú. 447

فِي جَنَّاتِ النَّعِيمِ43

nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
37:44Júzù 23 · ojú. 447

عَلَىٰ سُرُرٍ مُتَقَابِلِينَ44

Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn.
37:45Júzù 23 · ojú. 447

يُطَافُ عَلَيْهِمْ بِكَأْسٍ مِنْ مَعِينٍ45

Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.
37:46Júzù 23 · ojú. 447

بَيْضَاءَ لَذَّةٍ لِلشَّارِبِينَ46

Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn t’ó máa mu ún.
37:47Júzù 23 · ojú. 447

لَا فِيهَا غَوْلٌ وَلَا هُمْ عَنْهَا يُنْزَفُونَ47

Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀.
37:48Júzù 23 · ojú. 447

وَعِنْدَهُمْ قَاصِرَاتُ الطَّرْفِ عِينٌ48

Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn.
37:49Júzù 23 · ojú. 447

كَأَنَّهُنَّ بَيْضٌ مَكْنُونٌ49

Wọ́n dà bí tinú ẹyin.
____________________
Àwọn kristiẹni, nínú ọ̀rọ̀ wọn kan tí wọ́n ń fi tàbùkù àwọn ìkẹ́ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, wọ́n sọ pé, “Nítorí ọ̀wọ́n èso ní erúkùsù ilẹ̀ Lárúbáwá ni Allāhu fi ṣàdéhùn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso fún àwọn mùsùlùmí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀; nítorí pé àwọn Lárúbáwá fẹ́ràn ọtí àmupara ni Allāhu fi bá wọn pèsè ọtí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sílẹ̀ dè wọ́n nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀; nítorí pé àwọn Lárúbáwá fẹ́ràn àgbèrè ṣíṣe ni Allāhu fi bá wọn pèsè obìnrin ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sílẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn mùsùlùmí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀!”
Èsì: Ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn kristiẹni wọ̀nyí, yàtọ̀ sí pé ó ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí aláwàdà kẹríkẹrì, ó tún jẹ́ kí á mọ̀ pé wọn kò retí ìkẹ́ kan kan lọ́run ní tiwọn. Tí ó bá jẹ́ pé, wọ́n ń retí ìkẹ́ kan ní ọ̀run, irú ìkẹ́ wo gan-an ni wọ́n ń retí nígbà náà? Síwájú sí i, kì í kúkú ṣe Lárúbáwá nìkan ni mùsùlùmí. Gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ni mùsùlùmí. Àwọn kristiẹni ṣe wá ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé nítorí Lárúbáwá nìkan ni Allāhu fi dá Ọgbà Ìdẹ̀ra! Ìgbádùn inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wulẹ̀ pọ̀ tayọ èso, ọtí tí kìí pani àti obìnrin. Àmọ́ sá, kò wulẹ̀ sí ìgbádùn kan kan fún àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́run bí kò ṣe Iná gbére.
37:50Júzù 23 · ojú. 447

فَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَسَاءَلُونَ50

Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè.
37:51Júzù 23 · ojú. 447

قَالَ قَائِلٌ مِنْهُمْ إِنِّي كَانَ لِي قَرِينٌ51

Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan
37:52Júzù 23 · ojú. 448

يَقُولُ أَإِنَّكَ لَمِنَ الْمُصَدِّقِينَ52

tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde?
37:53Júzù 23 · ojú. 448

أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَدِينُونَ53

Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?”
37:54Júzù 23 · ojú. 448

قَالَ هَلْ أَنْتُمْ مُطَّلِعُونَ54

Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)?"
37:55Júzù 23 · ojú. 448

فَاطَّلَعَ فَرَآهُ فِي سَوَاءِ الْجَحِيمِ55

Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm.
37:56Júzù 23 · ojú. 448

قَالَ تَاللَّهِ إِنْ كِدْتَ لَتُرْدِينِ56

Ó (sì) sọ pé: "Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán.
37:57Júzù 23 · ojú. 448

وَلَوْلَا نِعْمَةُ رَبِّي لَكُنْتُ مِنَ الْمُحْضَرِينَ57

Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná.
37:58Júzù 23 · ojú. 448

أَفَمَا نَحْنُ بِمَيِّتِينَ58

Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí?
37:59Júzù 23 · ojú. 448

إِلَّا مَوْتَتَنَا الْأُولَىٰ وَمَا نَحْنُ بِمُعَذَّبِينَ59

Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà.
37:60Júzù 23 · ojú. 448

إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ60

Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá."
37:61Júzù 23 · ojú. 448

لِمِثْلِ هَٰذَا فَلْيَعْمَلِ الْعَامِلُونَ61

Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ.
37:62Júzù 23 · ojú. 448

أَذَٰلِكَ خَيْرٌ نُزُلًا أَمْ شَجَرَةُ الزَّقُّومِ62

Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)?
37:63Júzù 23 · ojú. 448

إِنَّا جَعَلْنَاهَا فِتْنَةً لِلظَّالِمِينَ63

Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí.
37:64Júzù 23 · ojú. 448

إِنَّهَا شَجَرَةٌ تَخْرُجُ فِي أَصْلِ الْجَحِيمِ64

Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm.
37:65Júzù 23 · ojú. 448

طَلْعُهَا كَأَنَّهُ رُءُوسُ الشَّيَاطِينِ65

Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn èṣù.
37:66Júzù 23 · ojú. 448

فَإِنَّهُمْ لَآكِلُونَ مِنْهَا فَمَالِئُونَ مِنْهَا الْبُطُونَ66

Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, wọn yóò fi kún inú wọn bámúbámú.
37:67Júzù 23 · ojú. 448

ثُمَّ إِنَّ لَهُمْ عَلَيْهَا لَشَوْبًا مِنْ حَمِيمٍ67

Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu n̄ǹkan mímu àwọyúnwẹ̀jẹ̀ gbígbóná lé e lórí.
37:68Júzù 23 · ojú. 448

ثُمَّ إِنَّ مَرْجِعَهُمْ لَإِلَى الْجَحِيمِ68

Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm.
37:69Júzù 23 · ojú. 448

إِنَّهُمْ أَلْفَوْا آبَاءَهُمْ ضَالِّينَ69

Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà.
37:70Júzù 23 · ojú. 448

فَهُمْ عَلَىٰ آثَارِهِمْ يُهْرَعُونَ70

Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn.
37:71Júzù 23 · ojú. 448

وَلَقَدْ ضَلَّ قَبْلَهُمْ أَكْثَرُ الْأَوَّلِينَ71

Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn.
37:72Júzù 23 · ojú. 448

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا فِيهِمْ مُنْذِرِينَ72

Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn.
37:73Júzù 23 · ojú. 448

فَانْظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُنْذَرِينَ73

Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí.
37:74Júzù 23 · ojú. 448

إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ74

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà.
37:75Júzù 23 · ojú. 448

وَلَقَدْ نَادَانَا نُوحٌ فَلَنِعْمَ الْمُجِيبُونَ75

Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè.
37:76Júzù 23 · ojú. 448

وَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ76

A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá.
37:77Júzù 23 · ojú. 449

وَجَعَلْنَا ذُرِّيَّتَهُ هُمُ الْبَاقِينَ77

A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀.
37:78Júzù 23 · ojú. 449

وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ78

A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
37:79Júzù 23 · ojú. 449

سَلَامٌ عَلَىٰ نُوحٍ فِي الْعَالَمِينَ79

Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá.
37:80Júzù 23 · ojú. 449

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ80

Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
37:81Júzù 23 · ojú. 449

إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ81

Dájúdájú òun wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
37:82Júzù 23 · ojú. 449

ثُمَّ أَغْرَقْنَا الْآخَرِينَ82

Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami.
37:83Júzù 23 · ojú. 449

۞ وَإِنَّ مِنْ شِيعَتِهِ لَإِبْرَاهِيمَ83

Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀.
____________________
Ìyẹn ni pé, ẹ̀sìn Ànábì Nūh ni ẹ̀sìn Ànábì ’Ibrọ̄hīm (aleehimọ sọlātu wa salām), ẹ̀sìn ’Islām.
37:84Júzù 23 · ojú. 449

إِذْ جَاءَ رَبَّهُ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ84

(Ẹ rántí) nígbà tí òun náà dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́.
37:85Júzù 23 · ojú. 449

إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَاذَا تَعْبُدُونَ85

(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún?
37:86Júzù 23 · ojú. 449

أَئِفْكًا آلِهَةً دُونَ اللَّهِ تُرِيدُونَ86

Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu?
37:87Júzù 23 · ojú. 449

فَمَا ظَنُّكُمْ بِرَبِّ الْعَالَمِينَ87

Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”
37:88Júzù 23 · ojú. 449

فَنَظَرَ نَظْرَةً فِي النُّجُومِ88

Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ gan-an.
37:89Júzù 23 · ojú. 449

فَقَالَ إِنِّي سَقِيمٌ89

Ó sì sọ pé: "Dájúdájú ó rẹ̀ mí."
37:90Júzù 23 · ojú. 449

فَتَوَلَّوْا عَنْهُ مُدْبِرِينَ90

Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ.
37:91Júzù 23 · ojú. 449

فَرَاغَ إِلَىٰ آلِهَتِهِمْ فَقَالَ أَلَا تَأْكُلُونَ91

Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni?
37:92Júzù 23 · ojú. 449

مَا لَكُمْ لَا تَنْطِقُونَ92

Kí ni ó ṣe yín tí ẹ ò sọ̀rọ̀?"
37:93Júzù 23 · ojú. 449

فَرَاغَ عَلَيْهِمْ ضَرْبًا بِالْيَمِينِ93

Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú).
37:94Júzù 23 · ojú. 449

فَأَقْبَلُوا إِلَيْهِ يَزِفُّونَ94

(Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́.
37:95Júzù 23 · ojú. 449

قَالَ أَتَعْبُدُونَ مَا تَنْحِتُونَ95

Ó sọ pé: "Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni?
37:96Júzù 23 · ojú. 449

وَاللَّهُ خَلَقَكُمْ وَمَا تَعْمَلُونَ96

Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."
37:97Júzù 23 · ojú. 449

قَالُوا ابْنُوا لَهُ بُنْيَانًا فَأَلْقُوهُ فِي الْجَحِيمِ97

Wọ́n wí pé: "Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná."
37:98Júzù 23 · ojú. 449

فَأَرَادُوا بِهِ كَيْدًا فَجَعَلْنَاهُمُ الْأَسْفَلِينَ98

Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ.
37:99Júzù 23 · ojú. 449

وَقَالَ إِنِّي ذَاهِبٌ إِلَىٰ رَبِّي سَيَهْدِينِ99

Ó sọ pé: "Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀).
____________________
Ìyẹn ìlú Ṣām.
37:100Júzù 23 · ojú. 449

رَبِّ هَبْ لِي مِنَ الصَّالِحِينَ100

Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere."
37:101Júzù 23 · ojú. 449

فَبَشَّرْنَاهُ بِغُلَامٍ حَلِيمٍ101

A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin aláfaradà.
37:102Júzù 23 · ojú. 449

فَلَمَّا بَلَغَ مَعَهُ السَّعْيَ قَالَ يَا بُنَيَّ إِنِّي أَرَىٰ فِي الْمَنَامِ أَنِّي أَذْبَحُكَ فَانْظُرْ مَاذَا تَرَىٰ ۚ قَالَ يَا أَبَتِ افْعَلْ مَا تُؤْمَرُ ۖ سَتَجِدُنِي إِنْ شَاءَ اللَّهُ مِنَ الصَّابِرِينَ102

Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: "Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́."
37:103Júzù 23 · ojú. 450

فَلَمَّا أَسْلَمَا وَتَلَّهُ لِلْجَبِينِ103

Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀,
____________________
Ìtúmọ̀ “jẹbīn” ni iwájú orí.
37:104Júzù 23 · ojú. 450

وَنَادَيْنَاهُ أَنْ يَا إِبْرَاهِيمُ104

A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm,
37:105Júzù 23 · ojú. 450

قَدْ صَدَّقْتَ الرُّؤْيَا ۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ105

o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
37:106Júzù 23 · ojú. 450

إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْبَلَاءُ الْمُبِينُ106

Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé.
37:107Júzù 23 · ojú. 450

وَفَدَيْنَاهُ بِذِبْحٍ عَظِيمٍ107

A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀.
37:108Júzù 23 · ojú. 450

وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ108

A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
37:109Júzù 23 · ojú. 450

سَلَامٌ عَلَىٰ إِبْرَاهِيمَ109

Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.
37:110Júzù 23 · ojú. 450

كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ110

Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
37:111Júzù 23 · ojú. 450

إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ111

Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
37:112Júzù 23 · ojú. 450

وَبَشَّرْنَاهُ بِإِسْحَاقَ نَبِيًّا مِنَ الصَّالِحِينَ112

A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere.
37:113Júzù 23 · ojú. 450

وَبَارَكْنَا عَلَيْهِ وَعَلَىٰ إِسْحَاقَ ۚ وَمِنْ ذُرِّيَّتِهِمَا مُحْسِنٌ وَظَالِمٌ لِنَفْسِهِ مُبِينٌ113

Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (t’ó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì.
____________________
Bẹ̀rẹ̀ láti āyah 100 títí dé āyah 113, ó ti hàn kedere pé: (ìkíní) Ànábì ’Ismā‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni àkọ́bí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām); (ìkejì) Ànábì ’Ismā‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni ẹni tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa láṣẹ pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) pa láti fi jọ́sìn fún Òun; (ìkẹta) Kò sí ohun t’ó jẹmọ́ ẹ̀jẹ́ àti ìmúṣẹ ẹ̀jẹ́ nínú àlá àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà; (ìkẹrin) Ìkíní kejì àwọn ọmọ méjèèjì náà ni ẹni ìbùkún. Àmọ́, àwọn kristiẹni, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti àṣà wọn, orúkọ burúkú ni wọ́n ń fún Ànábì ’Ismā‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Hūd; 11:71.
37:114Júzù 23 · ojú. 450

وَلَقَدْ مَنَنَّا عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَارُونَ114

Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
37:115Júzù 23 · ojú. 450

وَنَجَّيْنَاهُمَا وَقَوْمَهُمَا مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ115

A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá.
37:116Júzù 23 · ojú. 450

وَنَصَرْنَاهُمْ فَكَانُوا هُمُ الْغَالِبِينَ116

A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn).
37:117Júzù 23 · ojú. 450

وَآتَيْنَاهُمَا الْكِتَابَ الْمُسْتَبِينَ117

A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà t’ó yanjú.
37:118Júzù 23 · ojú. 450

وَهَدَيْنَاهُمَا الصِّرَاطَ الْمُسْتَقِيمَ118

A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà.
37:119Júzù 23 · ojú. 450

وَتَرَكْنَا عَلَيْهِمَا فِي الْآخِرِينَ119

A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
37:120Júzù 23 · ojú. 450

سَلَامٌ عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَارُونَ120

Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
37:121Júzù 23 · ojú. 450

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ121

Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
37:122Júzù 23 · ojú. 450

إِنَّهُمَا مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ122

Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
37:123Júzù 23 · ojú. 450

وَإِنَّ إِلْيَاسَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ123

Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
37:124Júzù 23 · ojú. 450

إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ أَلَا تَتَّقُونَ124

(Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni?
37:125Júzù 23 · ojú. 450

أَتَدْعُونَ بَعْلًا وَتَذَرُونَ أَحْسَنَ الْخَالِقِينَ125

Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀,
____________________
Ṣé ẹlẹ́dàá mìíràn wà lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni? Ẹ yiri àwọn gbólóhùn wọ̀nyí wò: أَحْسَنَ ٱلْخَٰلِقِينَ Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá. (Ó tún wà nínú sūrah al-Mu’minūn; 23:14)
Irúfẹ́ gbólóhùn yìí nìwọ̀nyí: وَأَنتَ خَيْرُ ٱلرَّٰزِقِينَ Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùpèsè. (sūrah al-Mọ̄’idah; 5:114); وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Òun l’Ó sì dára jùlọ nínú àwọn olùdájọ́. (sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:87);
وَأَنتَ أَرْحَمُ ٱلرَّٰحِمِينَ Ìwọ sì ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú. (sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:151); وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Òun sì yára jùlọ nínú àwọn oníṣirò. (sūrah al-’Ani‘ām; 6:62); àti وَٱللَّهُ خَيْرُ ٱلْمَٰكِرِينَ Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn adéte. (āl-‘Imrọ̄n; 3:54).
Àwọn gbólóhùn wọ̀nyẹn ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń jẹ́ Ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́dàá, olùpèsè, olùdájọ́, aláàánú, oníṣirò àti eléte. Kíyè sí i, nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa ń ṣe fún àwọn ẹ̀dá Rẹ̀, àmọ́ tí a tún ń rí àwọn kan nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ tí àwọn náà máa ń ṣe wọ́n ni dídá ẹ̀dá, ìpèsè, ẹjọ́ dídá, àánú ṣíṣe, ìṣírò iṣẹ́ àti ète dídá. Ṣùgbọ́n ìkọ̀ọ̀kan àwọn iṣẹ́ náà bùkátà sí àlàyé.
Dídá ẹ̀dá: Ní òdodo ni pé, kò sí ẹ̀dá kan láyé àti lọ́run, ìbáà mọ bíi ọmọ iná igún, àfi kí Allāhu jẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Kódà àdámọ́, ẹ̀dá kan nínú ẹ̀dá Allahu ni. Àmọ́ ohun tí a gbà lérò pẹ̀lú fífi dídá ẹ̀dá tì sọ́dọ̀ ẹ̀dá ni ṣíṣe iṣẹ́-ọnà bíi ère gbígbẹ́ àti yíya àwòrán n̄ǹkan ẹlẹ́mìí. Èdè abunikù fún agbẹ́gilére ni “ẹlẹ́dàá”. Tí agbẹ́gilére bá mọ súná burúkú tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún òun, tí ó sì mọ̀ pé dájúdájú òun kò lè fi ẹ̀mí sára ère rẹ̀ t’ó ń gbẹ́ kalẹ̀, bóyá ó máa mọ̀ ọ́n ní ọ̀ràn. Ìdí nìyí tí hadīth kan fi sọ pé, lára ìyà tí ń bẹ nílẹ̀ ní ọ̀run nínú Iná de agbẹ́gi-lére ni pé, wọ́n máa sọ fún un pé kí ó fi ẹ̀mí sára ère rẹ̀. Kò sì níí lè ṣe bẹ́ẹ̀. Wàyí, wọ́n ń pé agbẹ́gilére ní “ẹlẹ́dàá” nítorí pé, wọ́n ń fi iṣẹ́-ọnà wọn jọ ẹ̀dá tí Allāhu dá. Tí a bá wá lo orúkọ “ẹlẹ́dàá” fún wọn, dípò oníṣẹ́-ọnà, tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ń jẹ́ Ẹlẹ́dàá, ta ni Ẹlẹ́dàá t’ó dára jùlọ tí ẹ̀dá tirẹ̀ jẹ́ ojúlówó? Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni. Ìdí nìyí tí Allāhu fi sọ pé, “Òun ni Ẹni t’ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá.” Pípe “oníṣẹ́-ọnà” ni “ẹlẹ́dàá” kò sì túmọ̀ sí pé ẹ̀dá kan wà t’ó ṣẹ̀dá ara rẹ̀ tàbí pé ẹ̀dá kan wà t’ó ń dá ẹ̀dá mìíràn bí kò ṣe ṣíṣe iṣẹ́-ọnà. Nítorí náà, ìtúmọ̀ àwọn ẹlẹ́dàá nínú āyah yìí ni “àwọn oníṣẹ́-ọnà tàbí àwọn agbẹ́gilére”.
Ìpèsè: Àwọn ẹ̀dá kan gbàgbọ́ pé àwọn òrìṣà kan ń pèsè ìjẹ-ìmu àti owó fún àwọn. Bí àpẹẹrẹ, Yorùbá gbàgbọ́ pé òrìṣà Ajé ń ṣe ìjẹ-ìmu, owó àti okòwò tí wọ́n sọ di “ọrọ̀-Ajé. Àwọn t’ó ń bọ́ ẹlòmíìràn náà ń sọra wọn di olùpèsè. Yàtọ̀ sí pé Allāhu ti fi rinlẹ̀ pé Òun nìkan ni Olùpèsè fún gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Tí èyí kò bá tí ì dá àwọn kan lójú bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì fẹ́ gbé gbogbo ìpèsè olúkùlùkù lórí ìwọ̀n, ó máa hàn sí wọn kedere pé, ìpèsè ti Allāhu pọ̀ jùlọ, kò sì ṣe é kà. Àti pé nínú ìpèsè Rẹ̀ ni wọ́n ti fún àwọn òrìṣà.
Ẹjọ́ dídá; A kúkú ní àwọn adájọ́ láààrin àwọn ènìyàn, yálà nílé ẹjọ́ tàbí ní àyè mìíràn. Àmọ́ kò sí adájọ́ tí ó jẹ́ arínú-róde. Àti pé ó wà nínú àwọn adájọ́ t’ó ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti fi ẹjọ́ ṣègbè. Allāhu nìkan ṣoṣo ni kì í fí ẹjọ́ ṣègbè. Àti pé ìdájọ́ Rẹ̀ dúró sórí mímọ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba olùrojọ́. Nítorí náà, ìdí nìyí tí Allāhu fi mọ ẹjọ́ da jùlọ nínú àwọn adájọ́. Ìdájọ́ Rẹ̀ sì ni òpin.
Àánú Ṣíṣe: Ojú àánú àti ọkàn àánú ń bẹ lára àwọn ẹ̀dá kan, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọ́n fi ń pè wọ́n ní ẹlẹ́yinjú-àánú. Àmọ́ Allāhu ní àánú ẹ̀dá Rẹ̀ púpọ̀ jùlọ. Àti pé, nínú àánú tí Allāhu fi sí àwọn ẹ̀dá kan lọ́kàn ni wọ́n fi di aláàánú. Nítorí náà, Allāhu ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú.
Bí àlàyé ṣe máa lọ nìyẹn lórí irú àwọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀ nínú al-Ƙur’ān, gẹ́gẹ́ bíi gbólóhùn “Olùyára jùlọ nínú àwọn olùṣírò-iṣẹ́”. Àmọ́ ní ti ète dídá, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
37:126Júzù 23 · ojú. 450

اللَّهَ رَبَّكُمْ وَرَبَّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ126

(ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́?"
37:127Júzù 23 · ojú. 451

فَكَذَّبُوهُ فَإِنَّهُمْ لَمُحْضَرُونَ127

Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná.
37:128Júzù 23 · ojú. 451

إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ128

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà.
37:129Júzù 23 · ojú. 451

وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ129

A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
37:130Júzù 23 · ojú. 451

سَلَامٌ عَلَىٰ إِلْ يَاسِينَ130

Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās.
37:131Júzù 23 · ojú. 451

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ131

Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
37:132Júzù 23 · ojú. 451

إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ132

Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
37:133Júzù 23 · ojú. 451

وَإِنَّ لُوطًا لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ133

Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
37:134Júzù 23 · ojú. 451

إِذْ نَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ أَجْمَعِينَ134

(Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là.
37:135Júzù 23 · ojú. 451

إِلَّا عَجُوزًا فِي الْغَابِرِينَ135

Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:171.
37:136Júzù 23 · ojú. 451

ثُمَّ دَمَّرْنَا الْآخَرِينَ136

Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.
37:137Júzù 23 · ojú. 451

وَإِنَّكُمْ لَتَمُرُّونَ عَلَيْهِمْ مُصْبِحِينَ137

Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀
37:138Júzù 23 · ojú. 451

وَبِاللَّيْلِ ۗ أَفَلَا تَعْقِلُونَ138

àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?
37:139Júzù 23 · ojú. 451

وَإِنَّ يُونُسَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ139

Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
37:140Júzù 23 · ojú. 451

إِذْ أَبَقَ إِلَى الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ140

(Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́.
37:141Júzù 23 · ojú. 451

فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ الْمُدْحَضِينَ141

Ó sì bá wọn muje pọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí aje ṣí mọ́ lórí.
____________________
Ìyẹn ni pé, nígbà tí ọkọ̀ ojú-omi takú sórí omi, wọ́n jọ fẹnu kò pé kí àwọn kọ orúkọ àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú-omi sí ara fọ́nrán ọ̀pá kọ̀ọ̀kan. Wọ́n sì jọ fẹnu kò pé ẹni tí wọ́n bá yọ fọ́nrán orúkọ rẹ̀ jáde nínú koto fọ́nrán ni wọn yóò jù sínú odò nítorí kí ọkọ t’ó takú lè lágbára láti rìn. Fọ́nrán orúkọ ti Ànábì Yūnus ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni wọ́n rí mú jáde. Wọ́n sì jù ú sínú odò. Ó sì ṣe wẹ́kú ẹnu ẹja.
37:142Júzù 23 · ojú. 451

فَالْتَقَمَهُ الْحُوتُ وَهُوَ مُلِيمٌ142

Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi.
37:143Júzù 23 · ojú. 451

فَلَوْلَا أَنَّهُ كَانَ مِنَ الْمُسَبِّحِينَ143

Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu,
37:144Júzù 23 · ojú. 451

لَلَبِثَ فِي بَطْنِهِ إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ144

dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.
37:145Júzù 23 · ojú. 451

۞ فَنَبَذْنَاهُ بِالْعَرَاءِ وَهُوَ سَقِيمٌ145

Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera.
37:146Júzù 23 · ojú. 451

وَأَنْبَتْنَا عَلَيْهِ شَجَرَةً مِنْ يَقْطِينٍ146

A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó.
37:147Júzù 23 · ojú. 451

وَأَرْسَلْنَاهُ إِلَىٰ مِائَةِ أَلْفٍ أَوْ يَزِيدُونَ147

A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i.
____________________
Ọ̀kẹ́ márùn-ún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000). Wàyí, àwọn kristiẹni lérò pé Allāhu kò nímọ̀ nípa pàtó òǹkà ìjọ Ànábì Yūnus ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’Ó fi mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ wá pẹ̀lú “ ’ao” - “tàbí”. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:74 fún àlàyé lórí rẹ̀.
37:148Júzù 23 · ojú. 451

فَآمَنُوا فَمَتَّعْنَاهُمْ إِلَىٰ حِينٍ148

Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀.
37:149Júzù 23 · ojú. 451

فَاسْتَفْتِهِمْ أَلِرَبِّكَ الْبَنَاتُ وَلَهُمُ الْبَنُونَ149

Bi wọ́n léèrè wò pé: "Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin?
37:150Júzù 23 · ojú. 451

أَمْ خَلَقْنَا الْمَلَائِكَةَ إِنَاثًا وَهُمْ شَاهِدُونَ150

Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí?"
37:151Júzù 23 · ojú. 451

أَلَا إِنَّهُمْ مِنْ إِفْكِهِمْ لَيَقُولُونَ151

Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé:
37:152Júzù 23 · ojú. 451

وَلَدَ اللَّهُ وَإِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ152

"Allāhu bímọ." Dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n.
37:153Júzù 23 · ojú. 451

أَصْطَفَى الْبَنَاتِ عَلَى الْبَنِينَ153

Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni?
37:154Júzù 23 · ojú. 452

مَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ154

Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí?
37:155Júzù 23 · ojú. 452

أَفَلَا تَذَكَّرُونَ155

Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
37:156Júzù 23 · ojú. 452

أَمْ لَكُمْ سُلْطَانٌ مُبِينٌ156

Tàbí ẹ ní ẹ̀rí t’ó yanjú lọ́wọ́ ni?
37:157Júzù 23 · ojú. 452

فَأْتُوا بِكِتَابِكُمْ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ157

Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
37:158Júzù 23 · ojú. 452

وَجَعَلُوا بَيْنَهُ وَبَيْنَ الْجِنَّةِ نَسَبًا ۚ وَلَقَدْ عَلِمَتِ الْجِنَّةُ إِنَّهُمْ لَمُحْضَرُونَ158

Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni.
37:159Júzù 23 · ojú. 452

سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ159

Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
37:160Júzù 23 · ojú. 452

إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ160

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà.
37:161Júzù 23 · ojú. 452

فَإِنَّكُمْ وَمَا تَعْبُدُونَ161

Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu),
37:162Júzù 23 · ojú. 452

مَا أَنْتُمْ عَلَيْهِ بِفَاتِنِينَ162

ẹ ò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà
37:163Júzù 23 · ojú. 452

إِلَّا مَنْ هُوَ صَالِ الْجَحِيمِ163

àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm.
37:164Júzù 23 · ojú. 452

وَمَا مِنَّا إِلَّا لَهُ مَقَامٌ مَعْلُومٌ164

Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀.
37:165Júzù 23 · ojú. 452

وَإِنَّا لَنَحْنُ الصَّافُّونَ165

Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.
37:166Júzù 23 · ojú. 452

وَإِنَّا لَنَحْنُ الْمُسَبِّحُونَ166

Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu).
37:167Júzù 23 · ojú. 452

وَإِنْ كَانُوا لَيَقُولُونَ167

Wọ́n kúkú ń wí pé:
37:168Júzù 23 · ojú. 452

لَوْ أَنَّ عِنْدَنَا ذِكْرًا مِنَ الْأَوَّلِينَ168

"Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́,
37:169Júzù 23 · ojú. 452

لَكُنَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ169

dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà."
37:170Júzù 23 · ojú. 452

فَكَفَرُوا بِهِ ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ170

Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
37:171Júzù 23 · ojú. 452

وَلَقَدْ سَبَقَتْ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا الْمُرْسَلِينَ171

Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́.
37:172Júzù 23 · ojú. 452

إِنَّهُمْ لَهُمُ الْمَنْصُورُونَ172

Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún.
37:173Júzù 23 · ojú. 452

وَإِنَّ جُنْدَنَا لَهُمُ الْغَالِبُونَ173

Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí.
37:174Júzù 23 · ojú. 452

فَتَوَلَّ عَنْهُمْ حَتَّىٰ حِينٍ174

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀.
37:175Júzù 23 · ojú. 452

وَأَبْصِرْهُمْ فَسَوْفَ يُبْصِرُونَ175

Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
37:176Júzù 23 · ojú. 452

أَفَبِعَذَابِنَا يَسْتَعْجِلُونَ176

Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?
37:177Júzù 23 · ojú. 452

فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمْ فَسَاءَ صَبَاحُ الْمُنْذَرِينَ177

Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí agboolé wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún.
37:178Júzù 23 · ojú. 452

وَتَوَلَّ عَنْهُمْ حَتَّىٰ حِينٍ178

Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná.
37:179Júzù 23 · ojú. 452

وَأَبْصِرْ فَسَوْفَ يُبْصِرُونَ179

Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
37:180Júzù 23 · ojú. 452

سُبْحَانَ رَبِّكَ رَبِّ الْعِزَّةِ عَمَّا يَصِفُونَ180

Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
37:181Júzù 23 · ojú. 452

وَسَلَامٌ عَلَى الْمُرْسَلِينَ181

Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́
37:182Júzù 23 · ojú. 452

وَالْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ182

Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Yasser Salama - As-Saffat · Tlawati