Al-Ikhlas

سورة الإخلاص

Súrà 112 · Mákí · 4 àwọn ẹsẹ

112:1 · Al-IkhlasJúzù 30 · ojú. 604

قُلْ هُوَ اللَّهُ أَحَدٌ1

Sọ pé: "Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo.
112:2Júzù 30 · ojú. 604

اللَّهُ الصَّمَدُ2

Allāhu ni Aṣíwájú (tí ẹ̀dá ní bùkátà sí, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn).
112:3Júzù 30 · ojú. 604

لَمْ يَلِدْ وَلَمْ يُولَدْ3

Kò bímọ. Wọn kò sì bí I.
112:4Júzù 30 · ojú. 604

وَلَمْ يَكُنْ لَهُ كُفُوًا أَحَدٌ4

Kò sì sí ẹnì kan tí ó jọ Ọ́."
____________________
Ẹ kíyè sí i! Àwọn kan máa ń ké “Ƙul huwa-llāhu” mẹ́ta fún òkú mùsùlùmí. Nígbà mìíràn, wọ́n lè ké òdidi al-Ƙur’ān fún un. Ìwọ̀nyí kò tọ sunnah rárá. Sūrah al-Haṣr; 59:10 ti fún wa ní àdúà t’ó jẹmọ́ òkú àti alààyè.
Síwájú sí i, ìtúmọ̀ “Ọlọ́hun” ni “Olúwa gbogbo ayé àti ọ̀run àti ohun t’ó wà láààrin méjèèjì”. Nínú èdè al-Ƙur’ān, èyí ni a mọ̀ sí “rọbbu-ssamọ̄wāt wal-’ard wa mọ̄ baenahumọ̄”. Ìdí nìyí tí a ò fi túmọ̀ “Allāhu” sí “Ọlọ́hun”. Nínú èdè Yorùbá, kò fẹ́ẹ̀ sí ìtúmọ̀ tí a fọkàn balẹ̀ sí fún ọ̀rọ̀-orúkọ ńlá náà “Allāhu” àfi lílo ọ̀rọ̀-orúkọ kan èyí tí àwọn Yorùbá máa ń lò ní ọjọ́un àná fún “Ọlọ́hun”. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sí máa mú àríyànjiyàn lọ́wọ́. Nítorí náà, “Allāhu” ni “Allāhu”.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà