Al-A'la

سورة الأعلى

Súrà 87 · Mákí · 19 àwọn ẹsẹ

87:1Júzù 30 · ojú. 591

سَبِّحِ اسْمَ رَبِّكَ الْأَعْلَى1

Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ.
87:2Júzù 30 · ojú. 591

الَّذِي خَلَقَ فَسَوَّىٰ2

Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba.
87:3Júzù 30 · ojú. 591

وَالَّذِي قَدَّرَ فَهَدَىٰ3

Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà.
____________________
Nínú āyah yìí, mẹ́ta gbòòrò ni ìtọ́sọ́nà náà èyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń ṣe fún àwa ènìyàn àti àlùjànnú. Ìkíní: ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām. Nítorí ìtọ́sọ́nà yìí gan-an ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe sọ àwọn Tírà Rẹ̀ kalẹ̀, tí Ó sì gbé àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ dìde sí wa. Ìkejì: ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí-ọkàn. Nípa èyí ni a fi mọ ohun rere àti ohun burúkú ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìfirinlẹ̀ rẹ̀ sì ń jẹyọ nínú àwọn tírà sánmọ̀ àti nínú ọ̀rọ̀ àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (a.s.w.).
Ìkẹta: ìtọ́sọ́nà òye àtinúwá. Nípa èyí ni a ṣe ń ṣàmúlò àwọn ohun àmúṣọrọ̀ fún ìgbáyé-gbádùn. Ìtọ́sọ́nà yìí kò sì sọ ẹnikẹ́ni di Òjíṣẹ́ Allāhu. Tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá rí ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, kò sí ẹ̀san rere kan fún un lórí rẹ̀ ní ọ̀run. Ó kàn wúlò dànù fún ayé ni.
87:4Júzù 30 · ojú. 591

وَالَّذِي أَخْرَجَ الْمَرْعَىٰ4

Ẹni tí Ó mú koríko tútù (hù) jáde,
87:5Júzù 30 · ojú. 591

فَجَعَلَهُ غُثَاءً أَحْوَىٰ5

Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ t’ó dúdú.
87:6Júzù 30 · ojú. 591

سَنُقْرِئُكَ فَلَا تَنْسَىٰ6

Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé.
87:7Júzù 30 · ojú. 591

إِلَّا مَا شَاءَ اللَّهُ ۚ إِنَّهُ يَعْلَمُ الْجَهْرَ وَمَا يَخْفَىٰ7

Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun t’ó pamọ́.
____________________
Ìyẹn nípasẹ̀ fífí ìdájọ́ kan pa ìdájọ́ t’ó ṣíwájú rẹ̀ rẹ́. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:106.
87:8Júzù 30 · ojú. 591

وَنُيَسِّرُكَ لِلْيُسْرَىٰ8

Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ.
87:9Júzù 30 · ojú. 591

فَذَكِّرْ إِنْ نَفَعَتِ الذِّكْرَىٰ9

Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò.
____________________
Ìyẹn ni pé, wọ́n fẹ́ kí ṣíṣe ìrántí ọ̀rọ̀ Allāhu jìnnà sí àyè ìhunrírà (bí ilé ọtí), ilé eré àti ilé awàdà nítorí pé, àwọn ènìyàn t’ó wà níbẹ̀ kò níí kọbi ara sí olùsọ̀rọ̀. Āyah yìí jọ sūrah an-Nisā’; 4:140 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:68.
87:10Júzù 30 · ojú. 591

سَيَذَّكَّرُ مَنْ يَخْشَىٰ10

Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí.
87:11Júzù 30 · ojú. 592

وَيَتَجَنَّبُهَا الْأَشْقَى11

Olórí-burúkú sì máa takété sí i.
87:12Júzù 30 · ojú. 592

الَّذِي يَصْلَى النَّارَ الْكُبْرَىٰ12

(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná t’ó tóbi.
87:13Júzù 30 · ojú. 592

ثُمَّ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحْيَىٰ13

Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà).
87:14Júzù 30 · ojú. 592

قَدْ أَفْلَحَ مَنْ تَزَكَّىٰ14

Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn rẹ̀) ti jèrè.
87:15Júzù 30 · ojú. 592

وَذَكَرَ اسْمَ رَبِّهِ فَصَلَّىٰ15

Ó tún rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun.
87:16Júzù 30 · ojú. 592

بَلْ تُؤْثِرُونَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا16

Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé.
87:17Júzù 30 · ojú. 592

وَالْآخِرَةُ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰ17

Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé.
87:18Júzù 30 · ojú. 592

إِنَّ هَٰذَا لَفِي الصُّحُفِ الْأُولَىٰ18

Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́,
87:19Júzù 30 · ojú. 592

صُحُفِ إِبْرَاهِيمَ وَمُوسَىٰ19

tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà