Al-Mutaffifin

سورة المطففين

Súrà 83 · Mákí · 36 àwọn ẹsẹ

83:1Júzù 30 · ojú. 587

وَيْلٌ لِلْمُطَفِّفِينَ1

Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù,
83:2Júzù 30 · ojú. 587

الَّذِينَ إِذَا اكْتَالُوا عَلَى النَّاسِ يَسْتَوْفُونَ2

àwọn (òǹtajà) t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún,
____________________
“Àwọn ènìyàn” ní àyè yìí dúró fún bíi “ àwọn olóko”.
83:3Júzù 30 · ojú. 587

وَإِذَا كَالُوهُمْ أَوْ وَزَنُوهُمْ يُخْسِرُونَ3

nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù.
83:4Júzù 30 · ojú. 587

أَلَا يَظُنُّ أُولَٰئِكَ أَنَّهُمْ مَبْعُوثُونَ4

Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde
83:5Júzù 30 · ojú. 588

لِيَوْمٍ عَظِيمٍ5

ní Ọjọ́ ńlá kan?
83:6Júzù 30 · ojú. 588

يَوْمَ يَقُومُ النَّاسُ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ6

Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde nàró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
83:7Júzù 30 · ojú. 588

كَلَّا إِنَّ كِتَابَ الْفُجَّارِ لَفِي سِجِّينٍ7

Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni ibi kúkú wà nínú Sijjīn.
83:8Júzù 30 · ojú. 588

وَمَا أَدْرَاكَ مَا سِجِّينٌ8

Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Sijjīn!
83:9Júzù 30 · ojú. 588

كِتَابٌ مَرْقُومٌ9

Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn).
83:10Júzù 30 · ojú. 588

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ10

Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́,
83:11Júzù 30 · ojú. 588

الَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوْمِ الدِّينِ11

àwọn t’ó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́.
83:12Júzù 30 · ojú. 588

وَمَا يُكَذِّبُ بِهِ إِلَّا كُلُّ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ12

Kò sì sí ẹni t’ó ń pè é nírọ́ àfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀.
83:13Júzù 30 · ojú. 588

إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ آيَاتُنَا قَالَ أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ13

Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: "Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)."
83:14Júzù 30 · ojú. 588

كَلَّا ۖ بَلْ ۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ مَا كَانُوا يَكْسِبُونَ14

Rárá kò rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ibi l’ó jọba lórí ọkàn wọn.
83:15Júzù 30 · ojú. 588

كَلَّا إِنَّهُمْ عَنْ رَبِّهِمْ يَوْمَئِذٍ لَمَحْجُوبُونَ15

Ní ti òdodo, dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn.
83:16Júzù 30 · ojú. 588

ثُمَّ إِنَّهُمْ لَصَالُو الْجَحِيمِ16

Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm.
83:17Júzù 30 · ojú. 588

ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا الَّذِي كُنْتُمْ بِهِ تُكَذِّبُونَ17

Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: "Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè nírọ́."
83:18Júzù 30 · ojú. 588

كَلَّا إِنَّ كِتَابَ الْأَبْرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ18

Bẹ́ẹ̀ ni. Dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn.
83:19Júzù 30 · ojú. 588

وَمَا أَدْرَاكَ مَا عِلِّيُّونَ19

Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ ‘illiyyūn!
83:20Júzù 30 · ojú. 588

كِتَابٌ مَرْقُومٌ20

Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn).
83:21Júzù 30 · ojú. 588

يَشْهَدُهُ الْمُقَرَّبُونَ21

Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i.
83:22Júzù 30 · ojú. 588

إِنَّ الْأَبْرَارَ لَفِي نَعِيمٍ22

Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn.
83:23Júzù 30 · ojú. 588

عَلَى الْأَرَائِكِ يَنْظُرُونَ23

Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.
83:24Júzù 30 · ojú. 588

تَعْرِفُ فِي وُجُوهِهِمْ نَضْرَةَ النَّعِيمِ24

Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn.
83:25Júzù 30 · ojú. 588

يُسْقَوْنَ مِنْ رَحِيقٍ مَخْتُومٍ25

Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí.
83:26Júzù 30 · ojú. 588

خِتَامُهُ مِسْكٌ ۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلْيَتَنَافَسِ الْمُتَنَافِسُونَ26

Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn.
83:27Júzù 30 · ojú. 588

وَمِزَاجُهُ مِنْ تَسْنِيمٍ27

Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà).
83:28Júzù 30 · ojú. 588

عَيْنًا يَشْرَبُ بِهَا الْمُقَرَّبُونَ28

(Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu.
83:29Júzù 30 · ojú. 588

إِنَّ الَّذِينَ أَجْرَمُوا كَانُوا مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا يَضْحَكُونَ29

Dájúdájú àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín.
83:30Júzù 30 · ojú. 588

وَإِذَا مَرُّوا بِهِمْ يَتَغَامَزُونَ30

Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn adẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́.
83:31Júzù 30 · ojú. 588

وَإِذَا انْقَلَبُوا إِلَىٰ أَهْلِهِمُ انْقَلَبُوا فَكِهِينَ31

Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí.
83:32Júzù 30 · ojú. 588

وَإِذَا رَأَوْهُمْ قَالُوا إِنَّ هَٰؤُلَاءِ لَضَالُّونَ32

Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: "Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà."
83:33Júzù 30 · ojú. 588

وَمَا أُرْسِلُوا عَلَيْهِمْ حَافِظِينَ33

Àwa kò sì rán wọn níṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn.
83:34Júzù 30 · ojú. 589

فَالْيَوْمَ الَّذِينَ آمَنُوا مِنَ الْكُفَّارِ يَضْحَكُونَ34

Nítorí náà, ní òní àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín.
83:35Júzù 30 · ojú. 589

عَلَى الْأَرَائِكِ يَنْظُرُونَ35

Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.
83:36Júzù 30 · ojú. 589

هَلْ ثُوِّبَ الْكُفَّارُ مَا كَانُوا يَفْعَلُونَ36

Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)?

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà