Al-Alaq

سورة العلق

Súrà 96 · Mákí · 19 àwọn ẹsẹ

96:1Júzù 30 · ojú. 597

اقْرَأْ بِاسْمِ رَبِّكَ الَّذِي خَلَقَ1

Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.
96:2Júzù 30 · ojú. 597

خَلَقَ الْإِنْسَانَ مِنْ عَلَقٍ2

Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.
96:3Júzù 30 · ojú. 597

اقْرَأْ وَرَبُّكَ الْأَكْرَمُ3

Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.
96:4Júzù 30 · ojú. 597

الَّذِي عَلَّمَ بِالْقَلَمِ4

Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.
96:5Júzù 30 · ojú. 597

عَلَّمَ الْإِنْسَانَ مَا لَمْ يَعْلَمْ5

Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.
96:6Júzù 30 · ojú. 597

كَلَّا إِنَّ الْإِنْسَانَ لَيَطْغَىٰ6

Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-àlà
96:7Júzù 30 · ojú. 597

أَنْ رَآهُ اسْتَغْنَىٰ7

nítorí pé ó ríra rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.
96:8Júzù 30 · ojú. 597

إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ الرُّجْعَىٰ8

Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.
96:9Júzù 30 · ojú. 597

أَرَأَيْتَ الَّذِي يَنْهَىٰ9

Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń kọ̀
96:10Júzù 30 · ojú. 597

عَبْدًا إِذَا صَلَّىٰ10

fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!
96:11Júzù 30 · ojú. 597

أَرَأَيْتَ إِنْ كَانَ عَلَى الْهُدَىٰ11

Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)
96:12Júzù 30 · ojú. 597

أَوْ أَمَرَ بِالتَّقْوَىٰ12

tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!
96:13Júzù 30 · ojú. 598

أَرَأَيْتَ إِنْ كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ13

Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?
96:14Júzù 30 · ojú. 598

أَلَمْ يَعْلَمْ بِأَنَّ اللَّهَ يَرَىٰ14

Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)
96:15Júzù 30 · ojú. 598

كَلَّا لَئِنْ لَمْ يَنْتَهِ لَنَسْفَعًا بِالنَّاصِيَةِ15

Bẹ́ẹ̀ ni (Allāhu ń rí i.) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí i lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);
96:16Júzù 30 · ojú. 598

نَاصِيَةٍ كَاذِبَةٍ خَاطِئَةٍ16

àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
96:17Júzù 30 · ojú. 598

فَلْيَدْعُ نَادِيَهُ17

Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.
96:18Júzù 30 · ojú. 598

سَنَدْعُ الزَّبَانِيَةَ18

Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.
96:19Júzù 30 · ojú. 598

كَلَّا لَا تُطِعْهُ وَاسْجُدْ وَاقْتَرِبْ ۩19

Rárá o, má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o súnmọ́ (Allāhu).

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Salah Bukhatir - Al-Alaq · Tlawati