Al-Qari'ah

سورة القارعة

Súrà 101 · Mákí · 11 àwọn ẹsẹ

101:1Júzù 30 · ojú. 600

الْقَارِعَةُ1

Àkókò ìjáyà.
101:2Júzù 30 · ojú. 600

مَا الْقَارِعَةُ2

Kí ni Àkókò ìjáyà?
101:3Júzù 30 · ojú. 600

وَمَا أَدْرَاكَ مَا الْقَارِعَةُ3

Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà?
101:4Júzù 30 · ojú. 600

يَوْمَ يَكُونُ النَّاسُ كَالْفَرَاشِ الْمَبْثُوثِ4

(Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta,
101:5Júzù 30 · ojú. 600

وَتَكُونُ الْجِبَالُ كَالْعِهْنِ الْمَنْفُوشِ5

àwọn àpáta yó sì dà bí òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù.
101:6Júzù 30 · ojú. 600

فَأَمَّا مَنْ ثَقُلَتْ مَوَازِينُهُ6

Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀ wọ̀n,
101:7Júzù 30 · ojú. 600

فَهُوَ فِي عِيشَةٍ رَاضِيَةٍ7

ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó yọ́nú sí.
101:8Júzù 30 · ojú. 600

وَأَمَّا مَنْ خَفَّتْ مَوَازِينُهُ8

Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́,
101:9Júzù 30 · ojú. 600

فَأُمُّهُ هَاوِيَةٌ9

Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀.
101:10Júzù 30 · ojú. 600

وَمَا أَدْرَاكَ مَا هِيَهْ10

Kí sì ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀?
101:11Júzù 30 · ojú. 600

نَارٌ حَامِيَةٌ11

(Òhun ni) Iná gbígbóná gan-an.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Salah Bukhatir - Al-Qari'ah · Tlawati