Al-Fajr

سورة الفجر

Súrà 89 · Mákí · 30 àwọn ẹsẹ

89:1Júzù 30 · ojú. 593

وَالْفَجْرِ1

Allāhu búra pẹ̀lú àfẹ̀mọ́júmọ́.
89:2Júzù 30 · ojú. 593

وَلَيَالٍ عَشْرٍ2

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn òru mẹ́wàá kan.
89:3Júzù 30 · ojú. 593

وَالشَّفْعِ وَالْوَتْرِ3

Ó tún búra pẹ̀lú méjì àti ẹyọ.
89:4Júzù 30 · ojú. 593

وَاللَّيْلِ إِذَا يَسْرِ4

Ó tún búra pẹ̀lú òru nígbà tí ó bá lọ (tí ó bá dé).
89:5Júzù 30 · ojú. 593

هَلْ فِي ذَٰلِكَ قَسَمٌ لِذِي حِجْرٍ5

Ǹjẹ́ ìbúra wà nínú ìyẹn fún onílàákàyè?
89:6Júzù 30 · ojú. 593

أَلَمْ تَرَ كَيْفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِعَادٍ6

Ṣé o ò rí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ará ‘Ād,
89:7Júzù 30 · ojú. 593

إِرَمَ ذَاتِ الْعِمَادِ7

(ìyẹn àwọn ìran) ’Irọm, àwọn òmìrán,
89:8Júzù 30 · ojú. 593

الَّتِي لَمْ يُخْلَقْ مِثْلُهَا فِي الْبِلَادِ8

àwọn tí A ò dá irú wọn mọ́ sínú ìlú?
89:9Júzù 30 · ojú. 593

وَثَمُودَ الَّذِينَ جَابُوا الصَّخْرَ بِالْوَادِ9

Àti àwọn Thamūd tí wọ́n gbẹ́ (ilé ìgbé) sínú àpáta nínú àfonífojì,
89:10Júzù 30 · ojú. 593

وَفِرْعَوْنَ ذِي الْأَوْتَادِ10

àti Fir‘aon eléèkàn (ìyà)?
89:11Júzù 30 · ojú. 593

الَّذِينَ طَغَوْا فِي الْبِلَادِ11

(Àwọn wọ̀nyí ni) àwọn t’ó tayọ ẹnu-àlà nínú ìlú.
89:12Júzù 30 · ojú. 593

فَأَكْثَرُوا فِيهَا الْفَسَادَ12

Wọ́n sì ṣe ìbàjẹ́ púpọ̀ sínú rẹ̀.
89:13Júzù 30 · ojú. 593

فَصَبَّ عَلَيْهِمْ رَبُّكَ سَوْطَ عَذَابٍ13

Olúwa rẹ sì rọ̀jò ìyà lé wọn lórí.
89:14Júzù 30 · ojú. 593

إِنَّ رَبَّكَ لَبِالْمِرْصَادِ14

Dájúdájú Olúwa rẹ wà ní ibùṣọ́ (iṣẹ́ ẹ̀dá).
89:15Júzù 30 · ojú. 593

فَأَمَّا الْإِنْسَانُ إِذَا مَا ابْتَلَاهُ رَبُّهُ فَأَكْرَمَهُ وَنَعَّمَهُ فَيَقُولُ رَبِّي أَكْرَمَنِ15

Nítorí náà, ní ti ènìyàn, nígbà tí Olúwa rẹ̀ bá dán an wò, tí Ó pọ́n ọn lé, tí Ó sì ṣe ìdẹ̀ra fún un, nígbà náà ó máa wí pé: "Olúwa mi ti pọ́n mi lé."
89:16Júzù 30 · ojú. 593

وَأَمَّا إِذَا مَا ابْتَلَاهُ فَقَدَرَ عَلَيْهِ رِزْقَهُ فَيَقُولُ رَبِّي أَهَانَنِ16

Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó bá dán an wò, tí Ó gán arísìkí rẹ̀ lé e lọ́wọ́, nígbà náà ó máa wí pé: "Olúwa mi ti yẹpẹrẹ mi."
89:17Júzù 30 · ojú. 593

كَلَّا ۖ بَلْ لَا تُكْرِمُونَ الْيَتِيمَ17

Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ẹ̀yin kò ṣàpọ́nlé ọmọ-òrukàn.
89:18Júzù 30 · ojú. 593

وَلَا تَحَاضُّونَ عَلَىٰ طَعَامِ الْمِسْكِينِ18

Àti pé ẹ̀yin kò gbẹra yín lóǹgbẹ láti fún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ.
89:19Júzù 30 · ojú. 593

وَتَأْكُلُونَ التُّرَاثَ أَكْلًا لَمًّا19

Ẹ tún ń jẹ ogún ní ìjẹkújẹ.
89:20Júzù 30 · ojú. 593

وَتُحِبُّونَ الْمَالَ حُبًّا جَمًّا20

Àti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí dúkìá ní ìfẹ́ púpọ̀.
89:21Júzù 30 · ojú. 593

كَلَّا إِذَا دُكَّتِ الْأَرْضُ دَكًّا دَكًّا21

Rárá, (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀). Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímì tìtì (t’ó rún wómúwómú, tí kò sí kòtò, tí kò sí gelemọ),
89:22Júzù 30 · ojú. 593

وَجَاءَ رَبُّكَ وَالْمَلَكُ صَفًّا صَفًّا22

(tí) Olúwa rẹ dé pẹ̀lú àwọn mọlāika ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́,
89:23Júzù 30 · ojú. 594

وَجِيءَ يَوْمَئِذٍ بِجَهَنَّمَ ۚ يَوْمَئِذٍ يَتَذَكَّرُ الْإِنْسَانُ وَأَنَّىٰ لَهُ الذِّكْرَىٰ23

ní ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mú iná Jahanamọ wá. Ní ọjọ́ yẹn, ènìyàn yóò rántí (ọ̀rọ̀ ara rẹ̀). Báwo sì ni ìrántí náà ṣe lè wúlò fún un!
89:24Júzù 30 · ojú. 594

يَقُولُ يَا لَيْتَنِي قَدَّمْتُ لِحَيَاتِي24

Ó máa wí pé: "Yéè, èmi ìbá ti ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ìṣẹ̀mí mi."
89:25Júzù 30 · ojú. 594

فَيَوْمَئِذٍ لَا يُعَذِّبُ عَذَابَهُ أَحَدٌ25

Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan kò lè fi ìyà jẹ (ẹ̀dá) bí irú ìyà (tí) Allāhu (yóò fi jẹ ẹ́).
89:26Júzù 30 · ojú. 594

وَلَا يُوثِقُ وَثَاقَهُ أَحَدٌ26

Ẹnì kan kò sì lè de (ẹ̀dá) ní ìgbèkùn bí irú ìgbèkùn (tí) Allāhu (yóò fi dè é).
89:27Júzù 30 · ojú. 594

يَا أَيَّتُهَا النَّفْسُ الْمُطْمَئِنَّةُ27

Ìwọ ẹ̀mí olùfọ̀kànbalẹ̀,
89:28Júzù 30 · ojú. 594

ارْجِعِي إِلَىٰ رَبِّكِ رَاضِيَةً مَرْضِيَّةً28

padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní olùyọ́nú, ẹni ìyọ́nú.
89:29Júzù 30 · ojú. 594

فَادْخُلِي فِي عِبَادِي29

Nítorí náà, wọlé sáààrin àwọn ẹrúsìn Mi.
89:30Júzù 30 · ojú. 594

وَادْخُلِي جَنَّتِي30

Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra Mi.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Sahl Yaseen - Al-Fajr · Tlawati