Ar-Rahman

سورة الرحمن

Súrà 55 · Mákí · 78 àwọn ẹsẹ

55:1Júzù 27 · ojú. 531

الرَّحْمَٰنُ1

Àjọkẹ́-ayé,
55:2Júzù 27 · ojú. 531

عَلَّمَ الْقُرْآنَ2

Ó fi ìmọ̀ al-Ƙur’ān mọ (ẹni tí Ó fẹ́).
55:3Júzù 27 · ojú. 531

خَلَقَ الْإِنْسَانَ3

Ó ṣẹ̀dá ènìyàn.
55:4Júzù 27 · ojú. 531

عَلَّمَهُ الْبَيَانَ4

Ó sì fi àlàyé (ọ̀rọ̀ sísọ) mọ̀ ọ́n.
55:5Júzù 27 · ojú. 531

الشَّمْسُ وَالْقَمَرُ بِحُسْبَانٍ5

Òòrùn àti òṣùpá (ń rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé).
55:6Júzù 27 · ojú. 531

وَالنَّجْمُ وَالشَّجَرُ يَسْجُدَانِ6

Àwọn ìtàkùn ilẹ̀ àti igi ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
55:7Júzù 27 · ojú. 531

وَالسَّمَاءَ رَفَعَهَا وَوَضَعَ الْمِيزَانَ7

Àti sánmọ̀, Allāhu gbé e sókè. Ó sì fi òṣùwọ̀n òfin déédé lélẹ̀ (fún ẹ̀dá)
55:8Júzù 27 · ojú. 531

أَلَّا تَطْغَوْا فِي الْمِيزَانِ8

pé kí ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà níbi òṣùwọ̀n.
55:9Júzù 27 · ojú. 531

وَأَقِيمُوا الْوَزْنَ بِالْقِسْطِ وَلَا تُخْسِرُوا الْمِيزَانَ9

Ẹ gbé òṣùwọ̀n náà dúró pẹ̀lú dọ́gbadọ́gba. Kí ẹ sì má ṣe dín òṣùwọ̀n kù.
55:10Júzù 27 · ojú. 531

وَالْأَرْضَ وَضَعَهَا لِلْأَنَامِ10

Ilẹ̀, (Allāhu) tẹ́ ẹ sílẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá.
55:11Júzù 27 · ojú. 531

فِيهَا فَاكِهَةٌ وَالنَّخْلُ ذَاتُ الْأَكْمَامِ11

Èso àti dàbínù alápó wà lórí (ilẹ̀).
55:12Júzù 27 · ojú. 531

وَالْحَبُّ ذُو الْعَصْفِ وَالرَّيْحَانُ12

Àti èso kóró onípòpórò àti eléwé dúdú (wà lórí ilẹ̀).

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ13

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:14Júzù 27 · ojú. 531

خَلَقَ الْإِنْسَانَ مِنْ صَلْصَالٍ كَالْفَخَّارِ14

(Allāhu) ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ gbígbẹ t’ó ń dún kokoko bí ìkòkò amọ̀.
55:15Júzù 27 · ojú. 531

وَخَلَقَ الْجَانَّ مِنْ مَارِجٍ مِنْ نَارٍ15

Ó sì ṣẹ̀dá àlùjànnú láti ara ahọ́n iná tí kò ní èéfín.
55:16Júzù 27 · ojú. 531

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ16

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:17Júzù 27 · ojú. 531

رَبُّ الْمَشْرِقَيْنِ وَرَبُّ الْمَغْرِبَيْنِ17

Olúwa ibùyọ òòrùn méjèèjì àti ibùwọ̀ òòrùn méjèèjì.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mọ‘ārij; 70:40.
55:18Júzù 27 · ojú. 531

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ18

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:19Júzù 27 · ojú. 532

مَرَجَ الْبَحْرَيْنِ يَلْتَقِيَانِ19

(Allāhu) mú odò méjì (odò oníyọ̀ àti odò aládùn) ṣàn pàdé ara wọn.
55:20Júzù 27 · ojú. 532

بَيْنَهُمَا بَرْزَخٌ لَا يَبْغِيَانِ20

Gàgá kan sì wà láààrin àwọn méjèèjì tí wọn kò sì lè tayọ ẹnu-àlà (rẹ̀ láààrin ara wọn).
55:21Júzù 27 · ojú. 532

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ21

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:22Júzù 27 · ojú. 532

يَخْرُجُ مِنْهُمَا اللُّؤْلُؤُ وَالْمَرْجَانُ22

Òkúta oníyebíye àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn ń jáde nínú àwọn (odò) méjèèjì náà.
55:23Júzù 27 · ojú. 532

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ23

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:24Júzù 27 · ojú. 532

وَلَهُ الْجَوَارِ الْمُنْشَآتُ فِي الْبَحْرِ كَالْأَعْلَامِ24

Ti (Allāhu) ni àwọn ọkọ̀ ojú-omi gogoro t’ó ń rìn nínú agbami òdò (tí wọ́n dà) bí àpáta gíga.
55:25Júzù 27 · ojú. 532

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ25

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:26Júzù 27 · ojú. 532

كُلُّ مَنْ عَلَيْهَا فَانٍ26

Gbogbo ẹni t’ó wà lórí ilẹ̀ máa tán.
55:27Júzù 27 · ojú. 532

وَيَبْقَىٰ وَجْهُ رَبِّكَ ذُو الْجَلَالِ وَالْإِكْرَامِ27

Ojú Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé sì máa wà títí láéláé.
55:28Júzù 27 · ojú. 532

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ28

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:29Júzù 27 · ojú. 532

يَسْأَلُهُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ كُلَّ يَوْمٍ هُوَ فِي شَأْنٍ29

Àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń bèèrè (n̄ǹkan) lọ́dọ̀ Rẹ̀; Ó sì wà lórí ìṣe lójoojúmọ́.
55:30Júzù 27 · ojú. 532

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ30

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:31Júzù 27 · ojú. 532

سَنَفْرُغُ لَكُمْ أَيُّهَ الثَّقَلَانِ31

A óò mú tiyín gbọ́ (lọ́jọ́ ẹ̀san), ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú.
55:32Júzù 27 · ojú. 532

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ32

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:33Júzù 27 · ojú. 532

يَا مَعْشَرَ الْجِنِّ وَالْإِنْسِ إِنِ اسْتَطَعْتُمْ أَنْ تَنْفُذُوا مِنْ أَقْطَارِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ فَانْفُذُوا ۚ لَا تَنْفُذُونَ إِلَّا بِسُلْطَانٍ33

Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, tí ẹ bá lágbára láti sá jáde nínú àwọn agbègbè sánmọ̀ àti ilẹ̀, ẹ sá jáde. Ẹ ò lè sá jáde àfi pẹ̀lú agbára.
55:34Júzù 27 · ojú. 532

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ34

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:35Júzù 27 · ojú. 532

يُرْسَلُ عَلَيْكُمَا شُوَاظٌ مِنْ نَارٍ وَنُحَاسٌ فَلَا تَنْتَصِرَانِ35

Wọ́n máa ju ẹ̀ta-pàrà iná àti ẹ̀ta-pàrà idẹ lé ẹ̀yin méjèèjì lórí, ẹ̀yin méjèèjì kò sì lè ran’ra yín lọ́wọ́.
55:36Júzù 27 · ojú. 532

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ36

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:37Júzù 27 · ojú. 532

فَإِذَا انْشَقَّتِ السَّمَاءُ فَكَانَتْ وَرْدَةً كَالدِّهَانِ37

Nítorí náà, nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì máa pọ́n wá wẹ̀ bí epo pupa.
55:38Júzù 27 · ojú. 532

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ38

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:39Júzù 27 · ojú. 532

فَيَوْمَئِذٍ لَا يُسْأَلُ عَنْ ذَنْبِهِ إِنْسٌ وَلَا جَانٌّ39

Nítorí náà, ní ọjọ́ yẹn Wọn ò níí bi ènìyàn àti àlùjànnú kan léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; (ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Wa).
55:40Júzù 27 · ojú. 532

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ40

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:41Júzù 27 · ojú. 532

يُعْرَفُ الْمُجْرِمُونَ بِسِيمَاهُمْ فَيُؤْخَذُ بِالنَّوَاصِي وَالْأَقْدَامِ41

Wọ́n máa mọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú àmì ara wọn. Wọ́n sì máa fi àásó orí àti ẹsẹ̀ gbá wọn mú.
55:42Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ42

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:43Júzù 27 · ojú. 533

هَٰذِهِ جَهَنَّمُ الَّتِي يُكَذِّبُ بِهَا الْمُجْرِمُونَ43

Èyí ni iná Jahanamọ tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń pè nírọ́.
55:44Júzù 27 · ojú. 533

يَطُوفُونَ بَيْنَهَا وَبَيْنَ حَمِيمٍ آنٍ44

Wọn yóò máa rìn lọ rìn bọ̀ láààrin Iná àti omi t’ó gbóná parí.
____________________
Ìyẹn ni pé, nínú Iná, yàtọ̀ sí pé oríṣiríṣi omi burúkú l’ó wà nínú rẹ̀ bíi omi t’ó gbóná parí, omi rẹ́funrẹ́fun, omi ètútú, omi àwọnúwẹ̀jẹ̀, àwọn omi wọ̀nyí máa wà nínú ọ̀gbun kan fún àwọn ọmọ Iná nínú Iná, bí Iná bá ti ń jó wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n á lọ máa mu omi ìmukúmu wọ̀nyí sí i, wọ́n á tún padà síbi Iná, wọ́n á tún padà síbi omi, wọ́n á tún padà síbi Ina. Wọ́n á wà bẹ́ẹ̀ títí láéláé.
55:45Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ45

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:46Júzù 27 · ojú. 533

وَلِمَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِ جَنَّتَانِ46

Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì ń bẹ fún ẹni t’ó bá páyà ìdúró rẹ̀ níwájú Olúwa rẹ̀.
55:47Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ47

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:48Júzù 27 · ojú. 533

ذَوَاتَا أَفْنَانٍ48

(Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra méjèèjì ní) àwọn ẹ̀ka igi gígùn.
55:49Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ49

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:50Júzù 27 · ojú. 533

فِيهِمَا عَيْنَانِ تَجْرِيَانِ50

Odò méjì t’ó ń ṣàn wà nínú ọgbà méjèèjì.
55:51Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ51

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:52Júzù 27 · ojú. 533

فِيهِمَا مِنْ كُلِّ فَاكِهَةٍ زَوْجَانِ52

Oríṣi méjì méjì ni èso kọ̀ọ̀kan t’ó wà nínú ọgbà méjèèjì.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yāsīn; 36:36.
55:53Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ53

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:54Júzù 27 · ojú. 533

مُتَّكِئِينَ عَلَىٰ فُرُشٍ بَطَائِنُهَا مِنْ إِسْتَبْرَقٍ ۚ وَجَنَى الْجَنَّتَيْنِ دَانٍ54

Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí ìtẹ́, tí àwọn ìtẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ àrán t’ó nípọn. Àwọn èso ọgbà méjèèjì sì wà ní àrọ́wọ́tó.
55:55Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ55

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:56Júzù 27 · ojú. 533

فِيهِنَّ قَاصِرَاتُ الطَّرْفِ لَمْ يَطْمِثْهُنَّ إِنْسٌ قَبْلَهُمْ وَلَا جَانٌّ56

Àwọn obìnrin tí kì í wo ọkùnrin mìíràn wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò sì fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.
55:57Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ57

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:58Júzù 27 · ojú. 533

كَأَنَّهُنَّ الْيَاقُوتُ وَالْمَرْجَانُ58

Wọ́n dà bíi ìlẹ̀kẹ̀ ṣẹ̀gi àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn.
55:59Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ59

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:60Júzù 27 · ojú. 533

هَلْ جَزَاءُ الْإِحْسَانِ إِلَّا الْإِحْسَانُ60

Ǹjẹ́ ẹ̀san mìíràn wà fún ṣíṣe rere bí kò ṣe (ẹ̀san) rere.
55:61Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ61

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:62Júzù 27 · ojú. 533

وَمِنْ دُونِهِمَا جَنَّتَانِ62

Ọgbà méjì kan tún ń bẹ yàtọ̀ sí méjì (àkọ́kọ́ yẹn).
55:63Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ63

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:64Júzù 27 · ojú. 533

مُدْهَامَّتَانِ64

Aláwọ̀ ewéko (ni Ọgbà méjèèjì náà).
55:65Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ65

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:66Júzù 27 · ojú. 533

فِيهِمَا عَيْنَانِ نَضَّاخَتَانِ66

Àwọn odò méjì t’ó ń tú omi jáde láì dáwọ́ dúró wà (nínú ọgbà méjèèjì náà).
55:67Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ67

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:68Júzù 27 · ojú. 533

فِيهِمَا فَاكِهَةٌ وَنَخْلٌ وَرُمَّانٌ68

Èso ìpanu, dàbínù àti èso rumọ̄n wà nínú ọgbà méjèèjì.
55:69Júzù 27 · ojú. 533

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ69

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:70Júzù 27 · ojú. 534

فِيهِنَّ خَيْرَاتٌ حِسَانٌ70

Àwọn obìnrin rere, arẹwà wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
55:71Júzù 27 · ojú. 534

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ71

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:72Júzù 27 · ojú. 534

حُورٌ مَقْصُورَاتٌ فِي الْخِيَامِ72

Àwọn ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ kan (ni wọ́n), tí A fi pamọ́ sínú ilé-ọ̀ṣọ́.
55:73Júzù 27 · ojú. 534

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ73

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:74Júzù 27 · ojú. 534

لَمْ يَطْمِثْهُنَّ إِنْسٌ قَبْلَهُمْ وَلَا جَانٌّ74

Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.
55:75Júzù 27 · ojú. 534

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ75

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:76Júzù 27 · ojú. 534

مُتَّكِئِينَ عَلَىٰ رَفْرَفٍ خُضْرٍ وَعَبْقَرِيٍّ حِسَانٍ76

Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí àwọn tìmùtìmù aláwọ̀ ewéko àti ìtẹ́ t’ó dára.
55:77Júzù 27 · ojú. 534

فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ77

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
55:78Júzù 27 · ojú. 534

تَبَارَكَ اسْمُ رَبِّكَ ذِي الْجَلَالِ وَالْإِكْرَامِ78

Ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Sahl Yaseen - Ar-Rahman · Tlawati