Al-Humazah

سورة الهمزة

Súrà 104 · Mákí · 9 àwọn ẹsẹ

104:1Júzù 30 · ojú. 601

وَيْلٌ لِكُلِّ هُمَزَةٍ لُمَزَةٍ1

Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni,
104:2Júzù 30 · ojú. 601

الَّذِي جَمَعَ مَالًا وَعَدَّدَهُ2

ẹni tí ó kó owó jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fẹ́sìn).
104:3Júzù 30 · ojú. 601

يَحْسَبُ أَنَّ مَالَهُ أَخْلَدَهُ3

Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé).
104:4Júzù 30 · ojú. 601

كَلَّا ۖ لَيُنْبَذَنَّ فِي الْحُطَمَةِ4

Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni.
104:5Júzù 30 · ojú. 601

وَمَا أَدْرَاكَ مَا الْحُطَمَةُ5

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Hutọmọh?
104:6Júzù 30 · ojú. 601

نَارُ اللَّهِ الْمُوقَدَةُ6

(Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (t’ó ń jò geregere),
104:7Júzù 30 · ojú. 601

الَّتِي تَطَّلِعُ عَلَى الْأَفْئِدَةِ7

èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ.
104:8Júzù 30 · ojú. 601

إِنَّهَا عَلَيْهِمْ مُؤْصَدَةٌ8

Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
104:9Júzù 30 · ojú. 601

فِي عَمَدٍ مُمَدَّدَةٍ9

(Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná).

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Sahl Yaseen - Al-Humazah · Tlawati