At-Tariq

سورة الطارق

Súrà 86 · Mákí · 17 àwọn ẹsẹ

86:1Júzù 30 · ojú. 591

وَالسَّمَاءِ وَالطَّارِقِ1

(Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ.
86:2Júzù 30 · ojú. 591

وَمَا أَدْرَاكَ مَا الطَّارِقُ2

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?
86:3Júzù 30 · ojú. 591

النَّجْمُ الثَّاقِبُ3

Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).
86:4Júzù 30 · ojú. 591

إِنْ كُلُّ نَفْسٍ لَمَّا عَلَيْهَا حَافِظٌ4

Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).
86:5Júzù 30 · ojú. 591

فَلْيَنْظُرِ الْإِنْسَانُ مِمَّ خُلِقَ5

Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀.
86:6Júzù 30 · ojú. 591

خُلِقَ مِنْ مَاءٍ دَافِقٍ6

Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi t’ó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́.
86:7Júzù 30 · ojú. 591

يَخْرُجُ مِنْ بَيْنِ الصُّلْبِ وَالتَّرَائِبِ7

Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin.
86:8Júzù 30 · ojú. 591

إِنَّهُ عَلَىٰ رَجْعِهِ لَقَادِرٌ8

Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀
86:9Júzù 30 · ojú. 591

يَوْمَ تُبْلَى السَّرَائِرُ9

ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́.
86:10Júzù 30 · ojú. 591

فَمَا لَهُ مِنْ قُوَّةٍ وَلَا نَاصِرٍ10

Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un.
86:11Júzù 30 · ojú. 591

وَالسَّمَاءِ ذَاتِ الرَّجْعِ11

Allāhu búra pẹ̀lú sánmọ̀ t’ó ń rọ òjò ní ọdọọdún.
86:12Júzù 30 · ojú. 591

وَالْأَرْضِ ذَاتِ الصَّدْعِ12

Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ t’ó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso).
86:13Júzù 30 · ojú. 591

إِنَّهُ لَقَوْلٌ فَصْلٌ13

Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́).
86:14Júzù 30 · ojú. 591

وَمَا هُوَ بِالْهَزْلِ14

Kì í sì ṣe àwàdà.
86:15Júzù 30 · ojú. 591

إِنَّهُمْ يَكِيدُونَ كَيْدًا15

Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an.
86:16Júzù 30 · ojú. 591

وَأَكِيدُ كَيْدًا16

Èmi náà sì ń déte gan-an.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
86:17Júzù 30 · ojú. 591

فَمَهِّلِ الْكَافِرِينَ أَمْهِلْهُمْ رُوَيْدًا17

Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Muhammad Jibreel - At-Tariq · Tlawati