An-Nazi'at

سورة النازعات

Súrà 79 · Mákí · 46 àwọn ẹsẹ

79:1Júzù 30 · ojú. 583

وَالنَّازِعَاتِ غَرْقًا1

Allāhu búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́.
79:2Júzù 30 · ojú. 583

وَالنَّاشِطَاتِ نَشْطًا2

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
79:3Júzù 30 · ojú. 583

وَالسَّابِحَاتِ سَبْحًا3

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀.
79:4Júzù 30 · ojú. 583

فَالسَّابِقَاتِ سَبْقًا4

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà.
79:5Júzù 30 · ojú. 583

فَالْمُدَبِّرَاتِ أَمْرًا5

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń ṣètò ilé ayé.
79:6Júzù 30 · ojú. 583

يَوْمَ تَرْجُفُ الرَّاجِفَةُ6

Ní ọjọ́ tí ìfọn àkọ́kọ́ fún òpin ayé máa mi gbogbo ayé tìtì pẹ̀lú ohùn igbe.
79:7Júzù 30 · ojú. 583

تَتْبَعُهَا الرَّادِفَةُ7

Ìfọn kejì fún Àjíǹde sì máa tèlé e.
79:8Júzù 30 · ojú. 583

قُلُوبٌ يَوْمَئِذٍ وَاجِفَةٌ8

Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.
79:9Júzù 30 · ojú. 583

أَبْصَارُهَا خَاشِعَةٌ9

Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ.
79:10Júzù 30 · ojú. 583

يَقُولُونَ أَإِنَّا لَمَرْدُودُونَ فِي الْحَافِرَةِ10

Wọn yóò wí pé: "Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)?
79:11Júzù 30 · ojú. 583

أَإِذَا كُنَّا عِظَامًا نَخِرَةً11

Ṣé nígbà tí a ti di eegun t’ó kẹfun tán?"
79:12Júzù 30 · ojú. 583

قَالُوا تِلْكَ إِذًا كَرَّةٌ خَاسِرَةٌ12

Wọ́n wí pé: "Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni t’ó pè é nírọ́.)"
79:13Júzù 30 · ojú. 583

فَإِنَّمَا هِيَ زَجْرَةٌ وَاحِدَةٌ13

Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni.
79:14Júzù 30 · ojú. 583

فَإِذَا هُمْ بِالسَّاهِرَةِ14

Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa.
79:15Júzù 30 · ojú. 583

هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ مُوسَىٰ15

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
79:16Júzù 30 · ojú. 583

إِذْ نَادَاهُ رَبُّهُ بِالْوَادِ الْمُقَدَّسِ طُوًى16

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonífojì mímọ́, Tuwā.
79:17Júzù 30 · ojú. 584

اذْهَبْ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُ طَغَىٰ17

Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-àlà.
79:18Júzù 30 · ojú. 584

فَقُلْ هَلْ لَكَ إِلَىٰ أَنْ تَزَكَّىٰ18

Kí o sì sọ pé: "Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí?
79:19Júzù 30 · ojú. 584

وَأَهْدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخْشَىٰ19

Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, kí o páyà (Rẹ̀)."
79:20Júzù 30 · ojú. 584

فَأَرَاهُ الْآيَةَ الْكُبْرَىٰ20

Ó sì fi àmì t’ó tóbi hàn án.
79:21Júzù 30 · ojú. 584

فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ21

(Àmọ́) ó pè é lópùrọ́. Ó sì yapa rẹ̀.
79:22Júzù 30 · ojú. 584

ثُمَّ أَدْبَرَ يَسْعَىٰ22

Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó).
79:23Júzù 30 · ojú. 584

فَحَشَرَ فَنَادَىٰ23

Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì.
79:24Júzù 30 · ojú. 584

فَقَالَ أَنَا رَبُّكُمُ الْأَعْلَىٰ24

Ó sì wí pé: "Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ."
79:25Júzù 30 · ojú. 584

فَأَخَذَهُ اللَّهُ نَكَالَ الْآخِرَةِ وَالْأُولَىٰ25

Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́).
____________________
Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ náà nìyí, Fir‘aon wí pé: "Ẹ̀yin ìjòyè, èmi kò mọ̀ pé ọlọ́hun kan tún wà lẹ́yìn mi!" Sūrah al-Ƙọsọs; 28:38
79:26Júzù 30 · ojú. 584

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبْرَةً لِمَنْ يَخْشَىٰ26

Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni t’ó ń páyà (Allāhu).
79:27Júzù 30 · ojú. 584

أَأَنْتُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَمِ السَّمَاءُ ۚ بَنَاهَا27

Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ?
79:28Júzù 30 · ojú. 584

رَفَعَ سَمْكَهَا فَسَوَّاهَا28

Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé t’ó gún régé.
79:29Júzù 30 · ojú. 584

وَأَغْطَشَ لَيْلَهَا وَأَخْرَجَ ضُحَاهَا29

Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde.
79:30Júzù 30 · ojú. 584

وَالْأَرْضَ بَعْدَ ذَٰلِكَ دَحَاهَا30

Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:29.
79:31Júzù 30 · ojú. 584

أَخْرَجَ مِنْهَا مَاءَهَا وَمَرْعَاهَا31

Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀.
79:32Júzù 30 · ojú. 584

وَالْجِبَالَ أَرْسَاهَا32

Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin.
79:33Júzù 30 · ojú. 584

مَتَاعًا لَكُمْ وَلِأَنْعَامِكُمْ33

Ìgbádùn ni fun yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
79:34Júzù 30 · ojú. 584

فَإِذَا جَاءَتِ الطَّامَّةُ الْكُبْرَىٰ34

Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé,
79:35Júzù 30 · ojú. 584

يَوْمَ يَتَذَكَّرُ الْإِنْسَانُ مَا سَعَىٰ35

ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun t’ó ṣe níṣẹ́.
79:36Júzù 30 · ojú. 584

وَبُرِّزَتِ الْجَحِيمُ لِمَنْ يَرَىٰ36

Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni t’ó ríran.
79:37Júzù 30 · ojú. 584

فَأَمَّا مَنْ طَغَىٰ37

Nítorí náà, ní ti ẹni t’ó bá tayọ ẹnu-àlà,
79:38Júzù 30 · ojú. 584

وَآثَرَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا38

tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé,
79:39Júzù 30 · ojú. 584

فَإِنَّ الْجَحِيمَ هِيَ الْمَأْوَىٰ39

dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
79:40Júzù 30 · ojú. 584

وَأَمَّا مَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِ وَنَهَى النَّفْسَ عَنِ الْهَوَىٰ40

Ní ti ẹni tí ó bá páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀),
79:41Júzù 30 · ojú. 584

فَإِنَّ الْجَنَّةَ هِيَ الْمَأْوَىٰ41

dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
79:42Júzù 30 · ojú. 584

يَسْأَلُونَكَ عَنِ السَّاعَةِ أَيَّانَ مُرْسَاهَا42

Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: "Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀?"
79:43Júzù 30 · ojú. 584

فِيمَ أَنْتَ مِنْ ذِكْرَاهَا43

Ọ̀nà wo ni ìwọ lè fi ní (ìmọ̀) ìrántí rẹ̀ ná?
79:44Júzù 30 · ojú. 584

إِلَىٰ رَبِّكَ مُنْتَهَاهَا44

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà.
79:45Júzù 30 · ojú. 584

إِنَّمَا أَنْتَ مُنْذِرُ مَنْ يَخْشَاهَا45

Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni t’ó ń páyà rẹ̀.
79:46Júzù 30 · ojú. 584

كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَهَا لَمْ يَلْبَثُوا إِلَّا عَشِيَّةً أَوْ ضُحَاهَا46

Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò lò tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan lọ (nílé ayé).

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà