Al-Qiyamah

سورة القيامة

Súrà 75 · Mákí · 40 àwọn ẹsẹ

75:1Júzù 29 · ojú. 577

لَا أُقْسِمُ بِيَوْمِ الْقِيَامَةِ1

Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú Ọjọ́ Àjíǹde.
75:2Júzù 29 · ojú. 577

وَلَا أُقْسِمُ بِالنَّفْسِ اللَّوَّامَةِ2

Mo tún ń búra pẹ̀lú ẹ̀mí t’ó máa dára rẹ̀ lẹ́bi.
75:3Júzù 29 · ojú. 577

أَيَحْسَبُ الْإِنْسَانُ أَلَّنْ نَجْمَعَ عِظَامَهُ3

Ṣé ènìyàn lérò pé A ò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni?
75:4Júzù 29 · ojú. 577

بَلَىٰ قَادِرِينَ عَلَىٰ أَنْ نُسَوِّيَ بَنَانَهُ4

Rárá o. A lágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba.
75:5Júzù 29 · ojú. 577

بَلْ يُرِيدُ الْإِنْسَانُ لِيَفْجُرَ أَمَامَهُ5

Ṣùgbọ́n ènìyàn gbèrò láti pe (Ọjọ́ Àjíǹde) t’ó ń bẹ níwájú rẹ̀ nírọ́.
75:6Júzù 29 · ojú. 577

يَسْأَلُ أَيَّانَ يَوْمُ الْقِيَامَةِ6

Ó ń bèèrè pé: "Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde?"
75:7Júzù 29 · ojú. 577

فَإِذَا بَرِقَ الْبَصَرُ7

Nígbà tí ojú bá kọ mọ̀nà,
75:8Júzù 29 · ojú. 577

وَخَسَفَ الْقَمَرُ8

àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn,
75:9Júzù 29 · ojú. 577

وَجُمِعَ الشَّمْسُ وَالْقَمَرُ9

àti (nígbà) tí A bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn,
75:10Júzù 29 · ojú. 577

يَقُولُ الْإِنْسَانُ يَوْمَئِذٍ أَيْنَ الْمَفَرُّ10

ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: "Níbo ni ibùsásí wà?"
75:11Júzù 29 · ojú. 577

كَلَّا لَا وَزَرَ11

Rárá, kò sí ibùsásí.
75:12Júzù 29 · ojú. 577

إِلَىٰ رَبِّكَ يَوْمَئِذٍ الْمُسْتَقَرُّ12

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn.
75:13Júzù 29 · ojú. 577

يُنَبَّأُ الْإِنْسَانُ يَوْمَئِذٍ بِمَا قَدَّمَ وَأَخَّرَ13

Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun t’ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun t’ó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
75:14Júzù 29 · ojú. 577

بَلِ الْإِنْسَانُ عَلَىٰ نَفْسِهِ بَصِيرَةٌ14

Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀,
75:15Júzù 29 · ojú. 577

وَلَوْ أَلْقَىٰ مَعَاذِيرَهُ15

ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá.
75:16Júzù 29 · ojú. 577

لَا تُحَرِّكْ بِهِ لِسَانَكَ لِتَعْجَلَ بِهِ16

Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e.
75:17Júzù 29 · ojú. 577

إِنَّ عَلَيْنَا جَمْعَهُ وَقُرْآنَهُ17

Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀.
75:18Júzù 29 · ojú. 577

فَإِذَا قَرَأْنَاهُ فَاتَّبِعْ قُرْآنَهُ18

Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀.
75:19Júzù 29 · ojú. 577

ثُمَّ إِنَّ عَلَيْنَا بَيَانَهُ19

Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ.
75:20Júzù 29 · ojú. 578

كَلَّا بَلْ تُحِبُّونَ الْعَاجِلَةَ20

Ẹ gbọ́! Ńṣe l’ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé.
75:21Júzù 29 · ojú. 578

وَتَذَرُونَ الْآخِرَةَ21

Ẹ sì ń pa ọ̀run tì.
75:22Júzù 29 · ojú. 578

وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ نَاضِرَةٌ22

Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú).
75:23Júzù 29 · ojú. 578

إِلَىٰ رَبِّهَا نَاظِرَةٌ23

Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò.
75:24Júzù 29 · ojú. 578

وَوُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ بَاسِرَةٌ24

Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́.
75:25Júzù 29 · ojú. 578

تَظُنُّ أَنْ يُفْعَلَ بِهَا فَاقِرَةٌ25

(Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé Wọ́n máa fi aburú kan òhun.
75:26Júzù 29 · ojú. 578

كَلَّا إِذَا بَلَغَتِ التَّرَاقِيَ26

Ẹ gbọ́! Nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò.
75:27Júzù 29 · ojú. 578

وَقِيلَ مَنْ ۜ رَاقٍ27

A sì máa sọ pé: "Ǹjẹ́ ọlọ́fọ̀ pípè kan wà bí (tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)?
75:28Júzù 29 · ojú. 578

وَظَنَّ أَنَّهُ الْفِرَاقُ28

Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé.
75:29Júzù 29 · ojú. 578

وَالْتَفَّتِ السَّاقُ بِالسَّاقِ29

Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun.
75:30Júzù 29 · ojú. 578

إِلَىٰ رَبِّكَ يَوْمَئِذٍ الْمَسَاقُ30

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn.
75:31Júzù 29 · ojú. 578

فَلَا صَدَّقَ وَلَا صَلَّىٰ31

Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun.
75:32Júzù 29 · ojú. 578

وَلَٰكِنْ كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ32

Ṣùgbọ́n ó pe òdodo nírọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i.
75:33Júzù 29 · ojú. 578

ثُمَّ ذَهَبَ إِلَىٰ أَهْلِهِ يَتَمَطَّىٰ33

Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí.
75:34Júzù 29 · ojú. 578

أَوْلَىٰ لَكَ فَأَوْلَىٰ34

Ègbé ni fún ọ, ègbé ni sẹ́.
75:35Júzù 29 · ojú. 578

ثُمَّ أَوْلَىٰ لَكَ فَأَوْلَىٰ35

Lẹ́yìn náà, ègbé ni fún ọ, ègbé sì sẹ́.
75:36Júzù 29 · ojú. 578

أَيَحْسَبُ الْإِنْسَانُ أَنْ يُتْرَكَ سُدًى36

Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni?
75:37Júzù 29 · ojú. 578

أَلَمْ يَكُ نُطْفَةً مِنْ مَنِيٍّ يُمْنَىٰ37

Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni?
75:38Júzù 29 · ojú. 578

ثُمَّ كَانَ عَلَقَةً فَخَلَقَ فَسَوَّىٰ38

Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é t’ó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn.
75:39Júzù 29 · ojú. 578

فَجَعَلَ مِنْهُ الزَّوْجَيْنِ الذَّكَرَ وَالْأُنْثَىٰ39

(Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti inú rẹ̀, akọ àti abo.
75:40Júzù 29 · ojú. 578

أَلَيْسَ ذَٰلِكَ بِقَادِرٍ عَلَىٰ أَنْ يُحْيِيَ الْمَوْتَىٰ40

Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí?

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Muhammad Jibreel - Al-Qiyamah · Tlawati