Al-Qalam

سورة القلم

Súrà 68 · Mákí · 52 àwọn ẹsẹ

68:1Júzù 29 · ojú. 564

ن ۚ وَالْقَلَمِ وَمَا يَسْطُرُونَ1

Nūn. (Allāhu búra pẹ̀lú) gègé ìkọ̀wé àti ohun tí àwọn mọlāika ń kọ sílẹ̀.
68:2Júzù 29 · ojú. 564

مَا أَنْتَ بِنِعْمَةِ رَبِّكَ بِمَجْنُونٍ2

Ìwọ kì í ṣe wèrè nípa ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
68:3Júzù 29 · ojú. 564

وَإِنَّ لَكَ لَأَجْرًا غَيْرَ مَمْنُونٍ3

Àti pé dájúdájú ẹ̀san tí kò níí dáwọ́ dúró ti wà fún ọ.
68:4Júzù 29 · ojú. 564

وَإِنَّكَ لَعَلَىٰ خُلُقٍ عَظِيمٍ4

Dájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà àpọ́nlé.
68:5Júzù 29 · ojú. 564

فَسَتُبْصِرُ وَيُبْصِرُونَ5

Láìpẹ́ ìwọ yóò rí i, àwọn náà yó sì rí i;
68:6Júzù 29 · ojú. 564

بِأَيْيِكُمُ الْمَفْتُونُ6

èwo nínú yín ni wèrè?
68:7Júzù 29 · ojú. 564

إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنْ ضَلَّ عَنْ سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ7

Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
68:8Júzù 29 · ojú. 564

فَلَا تُطِعِ الْمُكَذِّبِينَ8

Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
68:9Júzù 29 · ojú. 564

وَدُّوا لَوْ تُدْهِنُ فَيُدْهِنُونَ9

Àti pé wọ́n fẹ́ kí o dẹwọ́, kí àwọn náà sì dẹwọ́.
68:10Júzù 29 · ojú. 564

وَلَا تُطِعْ كُلَّ حَلَّافٍ مَهِينٍ10

Má ṣe tẹ̀lé gbogbo ẹni tí ìbúra rẹ̀ pọ̀, ẹni yẹpẹrẹ,
68:11Júzù 29 · ojú. 564

هَمَّازٍ مَشَّاءٍ بِنَمِيمٍ11

abúni, alárìnká t’ó ń sòfófó kiri,
68:12Júzù 29 · ojú. 564

مَنَّاعٍ لِلْخَيْرِ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ12

olùdènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀,
68:13Júzù 29 · ojú. 564

عُتُلٍّ بَعْدَ ذَٰلِكَ زَنِيمٍ13

ọ̀dájú. Lẹ́yìn ìyẹn, àsáwọ̀ ni.
____________________
Ìyẹn ni pé, kì í ṣe ojúlówó ọmọ ìran Ƙuraeṣ; àsọdọmọ ni. Ẹni náà ni Walīd ọmọ Mugīrah, ẹni tí ó wà ní ọmọ ọdún méjìdínlógún nígbà tí Mugīrah sọ ọ́ di ọmọ rẹ̀.
68:14Júzù 29 · ojú. 564

أَنْ كَانَ ذَا مَالٍ وَبَنِينَ14

Nítorí pé ó ní dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin,
68:15Júzù 29 · ojú. 564

إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ آيَاتُنَا قَالَ أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ15

nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)”.
68:16Júzù 29 · ojú. 564

سَنَسِمُهُ عَلَى الْخُرْطُومِ16

A máa fi àmì sí i ní góńgórí imú.
68:17Júzù 29 · ojú. 565

إِنَّا بَلَوْنَاهُمْ كَمَا بَلَوْنَا أَصْحَابَ الْجَنَّةِ إِذْ أَقْسَمُوا لَيَصْرِمُنَّهَا مُصْبِحِينَ17

Dájúdájú Àwa dán wọn wò gẹ́gẹ́ bí A ṣe dán àwọn ọlọ́gbà wò nígbà tí wọ́n búra pé dájúdájú àwọn yóò ká gbogbo èso ọgbà náà ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
68:18Júzù 29 · ojú. 565

وَلَا يَسْتَثْنُونَ18

Wọn kò sì ṣe àyàfi pé "tí Allāhu bá fẹ́".
68:19Júzù 29 · ojú. 565

فَطَافَ عَلَيْهَا طَائِفٌ مِنْ رَبِّكَ وَهُمْ نَائِمُونَ19

Àdánwò t’ó ń yí n̄ǹkan po láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì yí ọgbà náà po, nígbà tí wọ́n sùn lọ.
68:20Júzù 29 · ojú. 565

فَأَصْبَحَتْ كَالصَّرِيمِ20

Ó sì dà bí oko àgédànù (tí wọ́n ti résun).
68:21Júzù 29 · ojú. 565

فَتَنَادَوْا مُصْبِحِينَ21

Wọ́n ń pera wọn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù
68:22Júzù 29 · ojú. 565

أَنِ اغْدُوا عَلَىٰ حَرْثِكُمْ إِنْ كُنْتُمْ صَارِمِينَ22

pé ẹ jí lọ sí oko yín tí ẹ bá fẹ́ ká èso.
68:23Júzù 29 · ojú. 565

فَانْطَلَقُوا وَهُمْ يَتَخَافَتُونَ23

Wọ́n lọ, wọ́n sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀
68:24Júzù 29 · ojú. 565

أَنْ لَا يَدْخُلَنَّهَا الْيَوْمَ عَلَيْكُمْ مِسْكِينٌ24

pé ní òní mẹ̀kúnnù kan kò gbọdọ̀ wọnú rẹ̀ wá ba yín.
68:25Júzù 29 · ojú. 565

وَغَدَوْا عَلَىٰ حَرْدٍ قَادِرِينَ25

Wọ́n jí lọ lórí èrò-ọkàn kan (pé) àwọn lágbára.
68:26Júzù 29 · ojú. 565

فَلَمَّا رَأَوْهَا قَالُوا إِنَّا لَضَالُّونَ26

Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa ti ṣìnà.
68:27Júzù 29 · ojú. 565

بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ27

Rárá o, wọ́n ṣe ìkórè oko léèwọ̀ fún wa ni."
68:28Júzù 29 · ojú. 565

قَالَ أَوْسَطُهُمْ أَلَمْ أَقُلْ لَكُمْ لَوْلَا تُسَبِّحُونَ28

Ẹni t’ó dúró déédé jùlọ nínú wọn sọ pé: "Ṣé èmi kò sọ fun yín pé ẹ̀yin kò ṣe ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu (pé "a máa kórè oko wa, ’in ṣā ’Allāhu.)"?
68:29Júzù 29 · ojú. 565

قَالُوا سُبْحَانَ رَبِّنَا إِنَّا كُنَّا ظَالِمِينَ29

Wọ́n wí pé: "Mímọ́ ni fún Olúwa wa, dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí."
68:30Júzù 29 · ojú. 565

فَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَلَاوَمُونَ30

Apá kan wọn kọjú sí apá kan; wọ́n sì ń dára wọn lẹ́bi.
68:31Júzù 29 · ojú. 565

قَالُوا يَا وَيْلَنَا إِنَّا كُنَّا طَاغِينَ31

Wọ́n wí pé: "Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ olùtayọ-ẹnu àlà.
68:32Júzù 29 · ojú. 565

عَسَىٰ رَبُّنَا أَنْ يُبْدِلَنَا خَيْرًا مِنْهَا إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا رَاغِبُونَ32

Ó ṣeé ṣe kí Olúwa wa fi èyí t’ó dára ju èyí lọ pààrọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa ń rokàn oore sí."
68:33Júzù 29 · ojú. 565

كَذَٰلِكَ الْعَذَابُ ۖ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَكْبَرُ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ33

Báyẹn ni ìyà náà ṣe rí (fún wọn). Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
68:34Júzù 29 · ojú. 565

إِنَّ لِلْمُتَّقِينَ عِنْدَ رَبِّهِمْ جَنَّاتِ النَّعِيمِ34

Dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún àwọn olùbẹ̀rù lọ́dọ̀ Olúwa wọn.
68:35Júzù 29 · ojú. 565

أَفَنَجْعَلُ الْمُسْلِمِينَ كَالْمُجْرِمِينَ35

Ṣé A máa ṣe àwọn mùsùlùmí bí (A ṣe máa ṣe) àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?
68:36Júzù 29 · ojú. 565

مَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ36

Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí ná?
____________________
Ìyẹn ni pé, ẹni tí ó bá lérò pé ìkẹ́ máa wà fún òun ní ọ̀run láì jẹ́ pé ó kú sínú ẹ̀sìn ’Islām, ó ti gbé ìdájọ́ gbági.
68:37Júzù 29 · ojú. 565

أَمْ لَكُمْ كِتَابٌ فِيهِ تَدْرُسُونَ37

Tàbí tírà kan wà fun yín tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀
68:38Júzù 29 · ojú. 565

إِنَّ لَكُمْ فِيهِ لَمَا تَخَيَّرُونَ38

pé dájúdájú ẹ̀yin lẹ ni ohun tí ẹ bá ń ṣà lẹ́ṣà nínú ìdájọ́?
68:39Júzù 29 · ojú. 565

أَمْ لَكُمْ أَيْمَانٌ عَلَيْنَا بَالِغَةٌ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ ۙ إِنَّ لَكُمْ لَمَا تَحْكُمُونَ39

Ǹjẹ́ ẹ ni àwọn àdéhùn kan lọ́dọ̀ wa tí ó máa wà títí di Ọjọ́ Àjíǹde pé: "Dájúdájú tiyín ni ìdájọ́ tí ẹ bá ti mú wá."?
68:40Júzù 29 · ojú. 565

سَلْهُمْ أَيُّهُمْ بِذَٰلِكَ زَعِيمٌ40

Bi wọ́n léèrè wò pé èwo nínú wọn l’ó lè fọwọ́ ìyẹn sọ̀yà!
68:41Júzù 29 · ojú. 565

أَمْ لَهُمْ شُرَكَاءُ فَلْيَأْتُوا بِشُرَكَائِهِمْ إِنْ كَانُوا صَادِقِينَ41

Tàbí wọ́n ní àwọn òrìṣà kan? Kí wọ́n mú àwọn òrìṣà wọn wá nígbà náà tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
68:42Júzù 29 · ojú. 565

يَوْمَ يُكْشَفُ عَنْ سَاقٍ وَيُدْعَوْنَ إِلَى السُّجُودِ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ42

Ní ọjọ́ tí A máa ṣí ojúgun sílẹ̀, A sì máa pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀, wọn kò sì níí lè ṣe é.
68:43Júzù 29 · ojú. 566

خَاشِعَةً أَبْصَارُهُمْ تَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ۖ وَقَدْ كَانُوا يُدْعَوْنَ إِلَى السُّجُودِ وَهُمْ سَالِمُونَ43

Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n kúkú ti pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀ nígbà tí wọ́n ní àlàáfíà (wọn kò sì kírun).
68:44Júzù 29 · ojú. 566

فَذَرْنِي وَمَنْ يُكَذِّبُ بِهَٰذَا الْحَدِيثِ ۖ سَنَسْتَدْرِجُهُمْ مِنْ حَيْثُ لَا يَعْلَمُونَ44

Nítorí náà, fi Èmi àti ẹni t’ó ń pe ọ̀rọ̀ yìí nírọ́ sílẹ̀. A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò mọ̀.
68:45Júzù 29 · ojú. 566

وَأُمْلِي لَهُمْ ۚ إِنَّ كَيْدِي مَتِينٌ45

Mò ń lọ́ra fún wọn ni. Dájúdájú ète Mi lágbára.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
68:46Júzù 29 · ojú. 566

أَمْ تَسْأَلُهُمْ أَجْرًا فَهُمْ مِنْ مَغْرَمٍ مُثْقَلُونَ46

Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́dọ̀ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
68:47Júzù 29 · ojú. 566

أَمْ عِنْدَهُمُ الْغَيْبُ فَهُمْ يَكْتُبُونَ47

Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni (wàláà) ìkọ̀kọ̀ wà ni wọ́n bá ń kọ ọ́ (síta)?
68:48Júzù 29 · ojú. 566

فَاصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ وَلَا تَكُنْ كَصَاحِبِ الْحُوتِ إِذْ نَادَىٰ وَهُوَ مَكْظُومٌ48

Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Kí ìwọ má sì ṣe dà bí ẹlẹ́ja (ìyẹn, Ànábì Yūnus) nígbà tí ó pe (Allāhu) pẹ̀lú ìbànújẹ́.
68:49Júzù 29 · ojú. 566

لَوْلَا أَنْ تَدَارَكَهُ نِعْمَةٌ مِنْ رَبِّهِ لَنُبِذَ بِالْعَرَاءِ وَهُوَ مَذْمُومٌ49

Tí kò bá jẹ́ pé ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ lé e bá, wọn ìbá jù ú sórí ilẹ̀ gban̄sasa (láti inú ẹja) ní ẹni-èébú.
68:50Júzù 29 · ojú. 566

فَاجْتَبَاهُ رَبُّهُ فَجَعَلَهُ مِنَ الصَّالِحِينَ50

Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì ṣe é ní ara àwọn ẹni rere.
68:51Júzù 29 · ojú. 566

وَإِنْ يَكَادُ الَّذِينَ كَفَرُوا لَيُزْلِقُونَكَ بِأَبْصَارِهِمْ لَمَّا سَمِعُوا الذِّكْرَ وَيَقُولُونَ إِنَّهُ لَمَجْنُونٌ51

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ẹ̀ fi ojú wọn gbé ọ ṣubú nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrántí náà. Wọ́n sì ń wí pé: "Dájúdájú wèrè mà ni."
68:52Júzù 29 · ojú. 566

وَمَا هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِلْعَالَمِينَ52

Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Muhammad Ayyub - Al-Qalam · Tlawati