Al-Balad

سورة البلد

Súrà 90 · Mákí · 20 àwọn ẹsẹ

90:1Júzù 30 · ojú. 594

لَا أُقْسِمُ بِهَٰذَا الْبَلَدِ1

Èmi (Allāhu) búra pẹ̀lú ìlú yìí.
____________________
Ìbúra Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) àti ìbúra ẹ̀dá: Nígbà tí ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe kan bá jẹ́ kìkìdá òdodo àti àmọ̀dájú, ìbura lórí rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí a lè gba ṣe àfihàn ìdánilójú rẹ̀ fún ẹlòmíìràn nítorí kí ó lè bi iyèméjì àti rújúrújú wó lulẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ àti ìṣe Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ti dájú pé iṣẹ́ Ọwọ́ Rẹ̀ ni níti òdodo àti àmọ̀dàjù, ẹ̀tọ́ ni fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) láti fi èyíkéyìí nínú wọn búra. Ṣebí iṣẹ́ ọwọ́ Allāhu ni gbogbo bíbẹ. Àmọ́, ẹ̀dá kan kò gbọdọ̀ fi ẹ̀dá mìíràn búra nítorí pé, ẹ̀dá kan kì í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá mìíràn. Allāhu nìkan ni òdodo àti àmọ̀dájú fún ẹ̀dá láti fi búra nítorí pé, fífi Allāhu nìkan ṣoṣo búra ni ẹ̀sìn gbà wá láyè mọ láti fi búra. Bíbá Allāhu wá akẹgbẹ́ (ẹbọ ṣíṣe) sì ni fífi n̄ǹkan mìíràn búra lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).
90:2Júzù 30 · ojú. 594

وَأَنْتَ حِلٌّ بِهَٰذَا الْبَلَدِ2

Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).
____________________
Ẹ̀tọ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni kíkógun ja ìlú Mọkkah lásìkò ogun Ìṣí Mọkkah “Fat-hu Mọkkah”. Ṣíwájú àsìkò yìí àti lẹ́yìn rẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti jagun nínú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé.
90:3Júzù 30 · ojú. 594

وَوَالِدٍ وَمَا وَلَدَ3

(Mo tún) búra pẹ̀lú òbí àti ohun t’ó bí.
90:4Júzù 30 · ojú. 594

لَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ فِي كَبَدٍ4

Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.
90:5Júzù 30 · ojú. 594

أَيَحْسَبُ أَنْ لَنْ يَقْدِرَ عَلَيْهِ أَحَدٌ5

Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?
90:6Júzù 30 · ojú. 594

يَقُولُ أَهْلَكْتُ مَالًا لُبَدًا6

Ó (sì) ń wí pé: "Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì s.a.w.)"
90:7Júzù 30 · ojú. 594

أَيَحْسَبُ أَنْ لَمْ يَرَهُ أَحَدٌ7

Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?
90:8Júzù 30 · ojú. 594

أَلَمْ نَجْعَلْ لَهُ عَيْنَيْنِ8

Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?
90:9Júzù 30 · ojú. 594

وَلِسَانًا وَشَفَتَيْنِ9

Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?
90:10Júzù 30 · ojú. 594

وَهَدَيْنَاهُ النَّجْدَيْنِ10

A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.
90:11Júzù 30 · ojú. 594

فَلَا اقْتَحَمَ الْعَقَبَةَ11

Kò sì mú àkàbà ìgbàlà gùn!
90:12Júzù 30 · ojú. 594

وَمَا أَدْرَاكَ مَا الْعَقَبَةُ12

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ àkàbà ìgbàlà?
90:13Júzù 30 · ojú. 594

فَكُّ رَقَبَةٍ13

(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.
90:14Júzù 30 · ojú. 594

أَوْ إِطْعَامٌ فِي يَوْمٍ ذِي مَسْغَبَةٍ14

Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.
90:15Júzù 30 · ojú. 594

يَتِيمًا ذَا مَقْرَبَةٍ15

(Ó lè jẹ́) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,
90:16Júzù 30 · ojú. 594

أَوْ مِسْكِينًا ذَا مَتْرَبَةٍ16

tàbí mẹ́kùnnú, ẹni ilẹ̀ẹ́lẹ̀.
90:17Júzù 30 · ojú. 594

ثُمَّ كَانَ مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا وَتَوَاصَوْا بِالصَّبْرِ وَتَوَاصَوْا بِالْمَرْحَمَةِ17

Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.
90:18Júzù 30 · ojú. 594

أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ18

Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.
90:19Júzù 30 · ojú. 595

وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِنَا هُمْ أَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ19

Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:7.
90:20Júzù 30 · ojú. 595

عَلَيْهِمْ نَارٌ مُؤْصَدَةٌ20

A máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Muhammad Abdulkarim - Al-Balad · Tlawati