Abasa

سورة عبس

Súrà 80 · Mákí · 42 àwọn ẹsẹ

80:1Júzù 30 · ojú. 585

عَبَسَ وَتَوَلَّىٰ1

(Ànábì s.a.w.) fajú ro, ó sì pẹ̀yìn dà
80:2Júzù 30 · ojú. 585

أَنْ جَاءَهُ الْأَعْمَىٰ2

nítorí pé afọ́jú wá bá a.
80:3Júzù 30 · ojú. 585

وَمَا يُدْرِيكَ لَعَلَّهُ يَزَّكَّىٰ3

Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)
80:4Júzù 30 · ojú. 585

أَوْ يَذَّكَّرُ فَتَنْفَعَهُ الذِّكْرَىٰ4

tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní?
80:5Júzù 30 · ojú. 585

أَمَّا مَنِ اسْتَغْنَىٰ5

Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀,
80:6Júzù 30 · ojú. 585

فَأَنْتَ لَهُ تَصَدَّىٰ6

òun ni ìwọ tẹ́tí sí.
80:7Júzù 30 · ojú. 585

وَمَا عَلَيْكَ أَلَّا يَزَّكَّىٰ7

Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́).
80:8Júzù 30 · ojú. 585

وَأَمَّا مَنْ جَاءَكَ يَسْعَىٰ8

Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, t’ó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú),
80:9Júzù 30 · ojú. 585

وَهُوَ يَخْشَىٰ9

tí ó sì ń páyà (Allāhu),
80:10Júzù 30 · ojú. 585

فَأَنْتَ عَنْهُ تَلَهَّىٰ10

ìwọ kò sì kọbi ara sí i.
80:11Júzù 30 · ojú. 585

كَلَّا إِنَّهَا تَذْكِرَةٌ11

Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
80:12Júzù 30 · ojú. 585

فَمَنْ شَاءَ ذَكَرَهُ12

Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀.
80:13Júzù 30 · ojú. 585

فِي صُحُفٍ مُكَرَّمَةٍ13

(Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé,
80:14Júzù 30 · ojú. 585

مَرْفُوعَةٍ مُطَهَّرَةٍ14

A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́
80:15Júzù 30 · ojú. 585

بِأَيْدِي سَفَرَةٍ15

ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika),
80:16Júzù 30 · ojú. 585

كِرَامٍ بَرَرَةٍ16

àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere.
80:17Júzù 30 · ojú. 585

قُتِلَ الْإِنْسَانُ مَا أَكْفَرَهُ17

Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ!
80:18Júzù 30 · ojú. 585

مِنْ أَيِّ شَيْءٍ خَلَقَهُ18

Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀?
80:19Júzù 30 · ojú. 585

مِنْ نُطْفَةٍ خَلَقَهُ فَقَدَّرَهُ19

Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀.
80:20Júzù 30 · ojú. 585

ثُمَّ السَّبِيلَ يَسَّرَهُ20

Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un.
80:21Júzù 30 · ojú. 585

ثُمَّ أَمَاتَهُ فَأَقْبَرَهُ21

Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè.
80:22Júzù 30 · ojú. 585

ثُمَّ إِذَا شَاءَ أَنْشَرَهُ22

Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde.
80:23Júzù 30 · ojú. 585

كَلَّا لَمَّا يَقْضِ مَا أَمَرَهُ23

Ẹ gbọ́, ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un.
80:24Júzù 30 · ojú. 585

فَلْيَنْظُرِ الْإِنْسَانُ إِلَىٰ طَعَامِهِ24

Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀.
80:25Júzù 30 · ojú. 585

أَنَّا صَبَبْنَا الْمَاءَ صَبًّا25

Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀.
80:26Júzù 30 · ojú. 585

ثُمَّ شَقَقْنَا الْأَرْضَ شَقًّا26

Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn.
80:27Júzù 30 · ojú. 585

فَأَنْبَتْنَا فِيهَا حَبًّا27

A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀;
80:28Júzù 30 · ojú. 585

وَعِنَبًا وَقَضْبًا28

àti èso àjàrà àti kànnáfùrù,
80:29Júzù 30 · ojú. 585

وَزَيْتُونًا وَنَخْلًا29

àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù,
80:30Júzù 30 · ojú. 585

وَحَدَائِقَ غُلْبًا30

àti àwọn ọgbà t’ó kún fún igi,
80:31Júzù 30 · ojú. 585

وَفَاكِهَةً وَأَبًّا31

àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde).
80:32Júzù 30 · ojú. 585

مَتَاعًا لَكُمْ وَلِأَنْعَامِكُمْ32

(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
80:33Júzù 30 · ojú. 585

فَإِذَا جَاءَتِ الصَّاخَّةُ33

Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀,
80:34Júzù 30 · ojú. 585

يَوْمَ يَفِرُّ الْمَرْءُ مِنْ أَخِيهِ34

ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀,
80:35Júzù 30 · ojú. 585

وَأُمِّهِ وَأَبِيهِ35

àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú bàbá rẹ̀,
80:36Júzù 30 · ojú. 585

وَصَاحِبَتِهِ وَبَنِيهِ36

àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.
80:37Júzù 30 · ojú. 585

لِكُلِّ امْرِئٍ مِنْهُمْ يَوْمَئِذٍ شَأْنٌ يُغْنِيهِ37

Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn t’ó máa tó o ó rán.
80:38Júzù 30 · ojú. 585

وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ مُسْفِرَةٌ38

Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀.
80:39Júzù 30 · ojú. 585

ضَاحِكَةٌ مُسْتَبْشِرَةٌ39

Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú.
80:40Júzù 30 · ojú. 585

وَوُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ عَلَيْهَا غَبَرَةٌ40

Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀.
80:41Júzù 30 · ojú. 586

تَرْهَقُهَا قَتَرَةٌ41

Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀.
80:42Júzù 30 · ojú. 586

أُولَٰئِكَ هُمُ الْكَفَرَةُ الْفَجَرَةُ42

Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Muhammad Abdulkarim - Abasa · Tlawati