Al-Masad

سورة المسد

Súrà 111 · Mákí · 5 àwọn ẹsẹ

111:1Júzù 30 · ojú. 603

تَبَّتْ يَدَا أَبِي لَهَبٍ وَتَبَّ1

Ọwọ́ Abu-Lahab méjèèjì ti ṣòfò. Òun náà sì ṣòfò.
111:2Júzù 30 · ojú. 603

مَا أَغْنَىٰ عَنْهُ مَالُهُ وَمَا كَسَبَ2

Àwọn dúkìá rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ìyẹn, àwọn ọmọ rẹ̀) kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
111:3Júzù 30 · ojú. 603

سَيَصْلَىٰ نَارًا ذَاتَ لَهَبٍ3

Ó sì máa wọ inú Iná eléjò fòfò.
111:4Júzù 30 · ojú. 603

وَامْرَأَتُهُ حَمَّالَةَ الْحَطَبِ4

Àti ìyàwó rẹ̀, aláàárù-igi-ìṣẹ́pẹ́ ẹlẹ́gùn-ún, (ó máa wọná).
111:5Júzù 30 · ojú. 603

فِي جِيدِهَا حَبْلٌ مِنْ مَسَدٍ5

Igbà-ọ̀pẹ pọ̀npọ̀nràn máa wà ní ọrùn rẹ̀ (nínú Iná).

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà