Ad-Duha

سورة الضحى

Súrà 93 · Mákí · 11 àwọn ẹsẹ

93:1Júzù 30 · ojú. 596

وَالضُّحَىٰ1

(Allāhu búra pẹ̀lú) ìyálẹ̀ta.
93:2Júzù 30 · ojú. 596

وَاللَّيْلِ إِذَا سَجَىٰ2

Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú.
93:3Júzù 30 · ojú. 596

مَا وَدَّعَكَ رَبُّكَ وَمَا قَلَىٰ3

Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ.
93:4Júzù 30 · ojú. 596

وَلَلْآخِرَةُ خَيْرٌ لَكَ مِنَ الْأُولَىٰ4

Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé lọ.

وَلَسَوْفَ يُعْطِيكَ رَبُّكَ فَتَرْضَىٰ5

Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i.
93:6Júzù 30 · ojú. 596

أَلَمْ يَجِدْكَ يَتِيمًا فَآوَىٰ6

Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé.
93:7Júzù 30 · ojú. 596

وَوَجَدَكَ ضَالًّا فَهَدَىٰ7

Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:52.
93:8Júzù 30 · ojú. 596

وَوَجَدَكَ عَائِلًا فَأَغْنَىٰ8

Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀.
93:9Júzù 30 · ojú. 596

فَأَمَّا الْيَتِيمَ فَلَا تَقْهَرْ9

Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí).
93:10Júzù 30 · ojú. 596

وَأَمَّا السَّائِلَ فَلَا تَنْهَرْ10

Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn).
93:11Júzù 30 · ojú. 596

وَأَمَّا بِنِعْمَةِ رَبِّكَ فَحَدِّثْ11

Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà