Al-Ma'arij

سورة المعارج

Súrà 70 · Mákí · 44 àwọn ẹsẹ

70:1Júzù 29 · ojú. 568

سَأَلَ سَائِلٌ بِعَذَابٍ وَاقِعٍ1

Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà t’ó máa ṣẹlẹ̀
70:2Júzù 29 · ojú. 568

لِلْكَافِرِينَ لَيْسَ لَهُ دَافِعٌ2

sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́
70:3Júzù 29 · ojú. 568

مِنَ اللَّهِ ذِي الْمَعَارِجِ3

lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga.
70:4Júzù 29 · ojú. 568

تَعْرُجُ الْمَلَائِكَةُ وَالرُّوحُ إِلَيْهِ فِي يَوْمٍ كَانَ مِقْدَارُهُ خَمْسِينَ أَلْفَ سَنَةٍ4

Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).
____________________
Ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta ọdún (50,000). Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hajj; 22:47.
70:5Júzù 29 · ojú. 568

فَاصْبِرْ صَبْرًا جَمِيلًا5

Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù t’ó rẹwà.
70:6Júzù 29 · ojú. 568

إِنَّهُمْ يَرَوْنَهُ بَعِيدًا6

Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun t’ó jìnnà.
70:7Júzù 29 · ojú. 568

وَنَرَاهُ قَرِيبًا7

A sì ń wò ó ní ohun t’ó súnmọ́.
70:8Júzù 29 · ojú. 568

يَوْمَ تَكُونُ السَّمَاءُ كَالْمُهْلِ8

(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí idẹ t’ó yọ́,
70:9Júzù 29 · ojú. 568

وَتَكُونُ الْجِبَالُ كَالْعِهْنِ9

àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun,
70:10Júzù 29 · ojú. 568

وَلَا يَسْأَلُ حَمِيمٌ حَمِيمًا10

ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀).
70:11Júzù 29 · ojú. 569

يُبَصَّرُونَهُمْ ۚ يَوَدُّ الْمُجْرِمُ لَوْ يَفْتَدِي مِنْ عَذَابِ يَوْمِئِذٍ بِبَنِيهِ11

Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.
70:12Júzù 29 · ojú. 569

وَصَاحِبَتِهِ وَأَخِيهِ12

Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀,
70:13Júzù 29 · ojú. 569

وَفَصِيلَتِهِ الَّتِي تُؤْوِيهِ13

àti àwọn ẹbí rẹ̀ t’ó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé,
70:14Júzù 29 · ojú. 569

وَمَنْ فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا ثُمَّ يُنْجِيهِ14

àti gbogbo ẹni t’ó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).
70:15Júzù 29 · ojú. 569

كَلَّا ۖ إِنَّهَا لَظَىٰ15

Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná t’ó ń jò fòfò).
70:16Júzù 29 · ojú. 569

نَزَّاعَةً لِلشَّوَىٰ16

Ó máa bó awọ orí tòró.
70:17Júzù 29 · ojú. 569

تَدْعُو مَنْ أَدْبَرَ وَتَوَلَّىٰ17

(Iná) yó máa ké sí ẹni t’ó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i,
70:18Júzù 29 · ojú. 569

وَجَمَعَ فَأَوْعَىٰ18

ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn).
70:19Júzù 29 · ojú. 569

۞ إِنَّ الْإِنْسَانَ خُلِقَ هَلُوعًا19

Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà.
70:20Júzù 29 · ojú. 569

إِذَا مَسَّهُ الشَّرُّ جَزُوعًا20

Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó.
70:21Júzù 29 · ojú. 569

وَإِذَا مَسَّهُ الْخَيْرُ مَنُوعًا21

Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì tẹ oore, ó máa yahun.
70:22Júzù 29 · ojú. 569

إِلَّا الْمُصَلِّينَ22

Àyàfi àwọn olùkírun,
70:23Júzù 29 · ojú. 569

الَّذِينَ هُمْ عَلَىٰ صَلَاتِهِمْ دَائِمُونَ23

àwọn olùdúnnímọ́ ìrun wọn;
70:24Júzù 29 · ojú. 569

وَالَّذِينَ فِي أَمْوَالِهِمْ حَقٌّ مَعْلُومٌ24

àwọn t’ó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn
70:25Júzù 29 · ojú. 569

لِلسَّائِلِ وَالْمَحْرُومِ25

sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún;
70:26Júzù 29 · ojú. 569

وَالَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوْمِ الدِّينِ26

àwọn t’ó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo;
70:27Júzù 29 · ojú. 569

وَالَّذِينَ هُمْ مِنْ عَذَابِ رَبِّهِمْ مُشْفِقُونَ27

àwọn t’ó ń páyà ìyà Olúwa wọn,
70:28Júzù 29 · ojú. 569

إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمْ غَيْرُ مَأْمُونٍ28

dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí;
70:29Júzù 29 · ojú. 569

وَالَّذِينَ هُمْ لِفُرُوجِهِمْ حَافِظُونَ29

àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
70:30Júzù 29 · ojú. 569

إِلَّا عَلَىٰ أَزْوَاجِهِمْ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَإِنَّهُمْ غَيْرُ مَلُومِينَ30

àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú,
70:31Júzù 29 · ojú. 569

فَمَنِ ابْتَغَىٰ وَرَاءَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْعَادُونَ31

nítorí náà, ẹni kẹ́ni t’ó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ-ẹnu àlà;
70:32Júzù 29 · ojú. 569

وَالَّذِينَ هُمْ لِأَمَانَاتِهِمْ وَعَهْدِهِمْ رَاعُونَ32

àwọn t’ó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn;
70:33Júzù 29 · ojú. 569

وَالَّذِينَ هُمْ بِشَهَادَاتِهِمْ قَائِمُونَ33

àwọn t’ó ń dúró ti ìjẹ́rìí wọn;
70:34Júzù 29 · ojú. 569

وَالَّذِينَ هُمْ عَلَىٰ صَلَاتِهِمْ يُحَافِظُونَ34

àti àwọn t’ó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn.
70:35Júzù 29 · ojú. 569

أُولَٰئِكَ فِي جَنَّاتٍ مُكْرَمُونَ35

Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
70:36Júzù 29 · ojú. 569

فَمَالِ الَّذِينَ كَفَرُوا قِبَلَكَ مُهْطِعِينَ36

Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ,
70:37Júzù 29 · ojú. 569

عَنِ الْيَمِينِ وَعَنِ الشِّمَالِ عِزِينَ37

tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)?
70:38Júzù 29 · ojú. 569

أَيَطْمَعُ كُلُّ امْرِئٍ مِنْهُمْ أَنْ يُدْخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٍ38

Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni?
70:39Júzù 29 · ojú. 569

كَلَّا ۖ إِنَّا خَلَقْنَاهُمْ مِمَّا يَعْلَمُونَ39

Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀.
70:40Júzù 29 · ojú. 569

فَلَا أُقْسِمُ بِرَبِّ الْمَشَارِقِ وَالْمَغَارِبِ إِنَّا لَقَادِرُونَ40

Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn , dájúdájú Àwa ni Alágbára
____________________
Ìyẹn ni pé, Èmi, Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn ń fi ara Mi búra. Wòóore: Èròǹgbà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pẹ̀lú “mọṣriƙ” àti “mọgrib” nínú sūrah al-Muzzammil; 73:9 ni agbègbè ibùyọ òòrùn àti agbègbè ibùwọ̀ òòrùn. Èròǹgbà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pẹ̀lú “mọṣriƙọen” nínú sūrah ar-Rahmọ̄n; 55:17 ni ibùyọ òòrùn lásìkò ẹ̀rùn àti ibùyọ òòrùn lásìkò òjò. Bákan náà, “mọgribaen” ibùwọ̀ òòrùn lásìkò ẹ̀rùn àti ibùwọ̀ òòrùn lásìkò òjò. Bákan náà, èròǹgbà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pẹ̀lú “mọṣāriƙ àti mọgārib” ni àwọn ọ̀ọ́dúnrún àti ọgọ́ta ibùyọ òòrùn (360) ni agbègbè ibùyọ òòrùn àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún àti ọgọ́ta ibùwọ̀ òòrùn (360) ni agbègbè ibùwọ̀ òòrùn. (Tafsīr Bagawiy)
70:41Júzù 29 · ojú. 570

عَلَىٰ أَنْ نُبَدِّلَ خَيْرًا مِنْهُمْ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ41

láti lè fi àwọn t’ó dára jù wọ́n lọ pààrọ̀ wọn. Kò sì sí ẹni t’ó lè kó agara bá Wa.
70:42Júzù 29 · ojú. 570

فَذَرْهُمْ يَخُوضُوا وَيَلْعَبُوا حَتَّىٰ يُلَاقُوا يَوْمَهُمُ الَّذِي يُوعَدُونَ42

Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
70:43Júzù 29 · ojú. 570

يَوْمَ يَخْرُجُونَ مِنَ الْأَجْدَاثِ سِرَاعًا كَأَنَّهُمْ إِلَىٰ نُصُبٍ يُوفِضُونَ43

Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.
70:44Júzù 29 · ojú. 570

خَاشِعَةً أَبْصَارُهُمْ تَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ۚ ذَٰلِكَ الْيَوْمُ الَّذِي كَانُوا يُوعَدُونَ44

Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà