Al-Hijr

سورة الحجر

Súrà 15 · Mákí · 99 àwọn ẹsẹ

15:1Júzù 14 · ojú. 262

الر ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ وَقُرْآنٍ مُبِينٍ1

’Alif lām rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà àti (àwọn āyah) al-Ƙur’ān t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
15:2Júzù 14 · ojú. 262

رُبَمَا يَوَدُّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْ كَانُوا مُسْلِمِينَ2

Ó ṣeé ṣe kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí pé àwọn ìbá sì ti jẹ́ mùsùlùmí (nílé ayé).
15:3Júzù 14 · ojú. 262

ذَرْهُمْ يَأْكُلُوا وَيَتَمَتَّعُوا وَيُلْهِهِمُ الْأَمَلُ ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ3

Fi wọ́n sílẹ̀, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n gbádùn, kí ìrètí (ẹ̀mí gígùn) kó àìrójú ráàyè bá wọn (láti ṣẹ̀sìn); láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
15:4Júzù 14 · ojú. 262

وَمَا أَهْلَكْنَا مِنْ قَرْيَةٍ إِلَّا وَلَهَا كِتَابٌ مَعْلُومٌ4

A kò pa ìlú kan run rí àfi kí ó ní àkọsílẹ̀ tí A ti mọ̀.
15:5Júzù 14 · ojú. 262

مَا تَسْبِقُ مِنْ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسْتَأْخِرُونَ5

Kò sí ìjọ kan (tí ó parun) ṣíwájú àkókò rẹ̀ (nínú Laohul-Mahfuuṭḥ); wọn kò sì níí sún un ṣíwájú fún wọn.
15:6Júzù 14 · ojú. 262

وَقَالُوا يَا أَيُّهَا الَّذِي نُزِّلَ عَلَيْهِ الذِّكْرُ إِنَّكَ لَمَجْنُونٌ6

Wọ́n wí pé: “Ìwọ tí Wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún, dájúdájú wèrè ni ẹ́.
15:7Júzù 14 · ojú. 262

لَوْ مَا تَأْتِينَا بِالْمَلَائِكَةِ إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ7

Kí ni kò jẹ́ kí ìwọ mú àwọn mọlāika wá bá wa, tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo?”
15:8Júzù 14 · ojú. 262

مَا نُنَزِّلُ الْمَلَائِكَةَ إِلَّا بِالْحَقِّ وَمَا كَانُوا إِذًا مُنْظَرِينَ8

A ò níí sọ mọlāika kalẹ̀ bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Wọn kò sì níí lọ́ wọn lára mọ́ nígbà náà (tí àwọn mọlāika bá sọ̀kalẹ̀).
15:9Júzù 14 · ojú. 262

إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا الذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ9

Dájúdájú Àwa l’A sọ Tírà Ìrántí kalẹ̀ (ìyẹn al-Ƙur’ān). Dájúdájú Àwa sì ni Olùṣọ́ rẹ̀.
15:10Júzù 14 · ojú. 262

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ فِي شِيَعِ الْأَوَّلِينَ10

Dájúdájú ṣíwájú rẹ A ti rán (àwọn Òjíṣẹ́) níṣẹ́ sí àwọn ìjọ, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
15:11Júzù 14 · ojú. 262

وَمَا يَأْتِيهِمْ مِنْ رَسُولٍ إِلَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ11

Òjíṣẹ́ kan kò sì níí dé bá wọn àfi kí wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́.
15:12Júzù 14 · ojú. 262

كَذَٰلِكَ نَسْلُكُهُ فِي قُلُوبِ الْمُجْرِمِينَ12

Báyẹn ni A ṣe ń fi (àìsàn) sínú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
15:13Júzù 14 · ojú. 262

لَا يُؤْمِنُونَ بِهِ ۖ وَقَدْ خَلَتْ سُنَّةُ الْأَوَّلِينَ13

Wọn kò níí gba Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbọ́; ìṣe (Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá.
____________________
Ìṣe Allāhu lórí ẹ̀dá lásìkò ìparun nílé ayé ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) máa ń gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là, Ó sì máa ń pa àwọn aláìgbàgbọ́ run gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ sí ìjọ Ànábì Nūh, ìjọ Ànábì Lūt àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
15:14Júzù 14 · ojú. 262

وَلَوْ فَتَحْنَا عَلَيْهِمْ بَابًا مِنَ السَّمَاءِ فَظَلُّوا فِيهِ يَعْرُجُونَ14

Tí ó bá jẹ́ pé A ṣí ìlẹ̀kùn kan sílẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀, tí wọn kò sì yé gbabẹ̀ gùnkè lọ (sínú sánmọ̀),
15:15Júzù 14 · ojú. 262

لَقَالُوا إِنَّمَا سُكِّرَتْ أَبْصَارُنَا بَلْ نَحْنُ قَوْمٌ مَسْحُورُونَ15

dájúdájú wọ́n á wí pé: “Wọ́n kúkú lo ìṣíjú fún wa ni. Ńṣe ni wọ́n ń dan wá.”
15:16Júzù 14 · ojú. 263

وَلَقَدْ جَعَلْنَا فِي السَّمَاءِ بُرُوجًا وَزَيَّنَّاهَا لِلنَّاظِرِينَ16

A kúkú fi àwọn ibùsọ̀ (ìràwọ̀) sínú sánmọ̀ (ayé). A sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùwòran.
15:17Júzù 14 · ojú. 263

وَحَفِظْنَاهَا مِنْ كُلِّ شَيْطَانٍ رَجِيمٍ17

A sì fi ààbò bo ìmísí sánmọ̀ lọ́dọ̀ gbogbo èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.
15:18Júzù 14 · ojú. 263

إِلَّا مَنِ اسْتَرَقَ السَّمْعَ فَأَتْبَعَهُ شِهَابٌ مُبِينٌ18

Àfi (èṣù) tí ó bá jí ọ̀rọ̀ gbọ́. Nígbà náà sì ni ògúnná pọ́nńbélé yó tẹ̀lé e láti ẹ̀yìn.
15:19Júzù 14 · ojú. 263

وَالْأَرْضَ مَدَدْنَاهَا وَأَلْقَيْنَا فِيهَا رَوَاسِيَ وَأَنْبَتْنَا فِيهَا مِنْ كُلِّ شَيْءٍ مَوْزُونٍ19

Ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú gbogbo n̄ǹkan tí ó ní òdíwọ̀n hù jáde láti inú rẹ̀.
15:20Júzù 14 · ojú. 263

وَجَعَلْنَا لَكُمْ فِيهَا مَعَايِشَ وَمَنْ لَسْتُمْ لَهُ بِرَازِقِينَ20

A ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu sínú (ilé ayé) fun ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ̀yin kò lè pèsè fún.
15:21Júzù 14 · ojú. 263

وَإِنْ مِنْ شَيْءٍ إِلَّا عِنْدَنَا خَزَائِنُهُ وَمَا نُنَزِّلُهُ إِلَّا بِقَدَرٍ مَعْلُومٍ21

Kò sì sí kiní kan àfi kí ilé-ọrọ̀ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Wa. Àwa kò sì níí sọ̀ ọ́ kalẹ̀ àfi pẹ̀lú òdíwọ̀n tí A ti mọ̀.
15:22Júzù 14 · ojú. 263

وَأَرْسَلْنَا الرِّيَاحَ لَوَاقِحَ فَأَنْزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَسْقَيْنَاكُمُوهُ وَمَا أَنْتُمْ لَهُ بِخَازِنِينَ22

Àti pé A rán atẹ́gùn láti kó ẹ̀ṣújò jọ. A sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Nítorí náà, A fun yín mu. Ẹ̀yin sì kọ́ ni ẹ kó omi òjò jọ (sójú sánmọ̀).
15:23Júzù 14 · ojú. 263

وَإِنَّا لَنَحْنُ نُحْيِي وَنُمِيتُ وَنَحْنُ الْوَارِثُونَ23

Dájúdájú Àwa, Àwa mà l’À ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Àwa sì ni A óò jogún (ẹ̀dá).
15:24Júzù 14 · ojú. 263

وَلَقَدْ عَلِمْنَا الْمُسْتَقْدِمِينَ مِنْكُمْ وَلَقَدْ عَلِمْنَا الْمُسْتَأْخِرِينَ24

Àti pé dájúdájú A mọ àwọn olùgbawájú nínú yín. Dájúdájú A sì mọ àwọn olùgbẹ̀yìn.
15:25Júzù 14 · ojú. 263

وَإِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَحْشُرُهُمْ ۚ إِنَّهُ حَكِيمٌ عَلِيمٌ25

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó máa kó wọn jọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
15:26Júzù 14 · ojú. 263

وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنْ صَلْصَالٍ مِنْ حَمَإٍ مَسْنُونٍ26

Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà.
15:27Júzù 14 · ojú. 263

وَالْجَانَّ خَلَقْنَاهُ مِنْ قَبْلُ مِنْ نَارِ السَّمُومِ27

Àti pé àlùjànnú, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ṣíwájú (ènìyàn) láti ara iná alátẹ́gùn gbígbóná tí kò ní èéfín.
15:28Júzù 14 · ojú. 263

وَإِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي خَالِقٌ بَشَرًا مِنْ صَلْصَالٍ مِنْ حَمَإٍ مَسْنُونٍ28

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò ṣe ẹ̀dá abara kan láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà.
15:29Júzù 14 · ojú. 263

فَإِذَا سَوَّيْتُهُ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِنْ رُوحِي فَقَعُوا لَهُ سَاجِدِينَ29

Nígbà tí Mo bá ṣe é t’ó gún régé tán, tí Mo fẹ́ ẹ̀mí sí i (lára) nínú ẹ̀mí Mi (tí Mo dá), nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni."
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:34.
15:30Júzù 14 · ojú. 263

فَسَجَدَ الْمَلَائِكَةُ كُلُّهُمْ أَجْمَعُونَ30

Nítorí náà, àwọn mọlāika, gbogbo wọn pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i.
15:31Júzù 14 · ojú. 263

إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَىٰ أَنْ يَكُونَ مَعَ السَّاجِدِينَ31

Àyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ náà.
15:32Júzù 14 · ojú. 264

قَالَ يَا إِبْلِيسُ مَا لَكَ أَلَّا تَكُونَ مَعَ السَّاجِدِينَ32

(Allāhu) sọ pé: "’Iblīs, kí l’ó dí ọ lọ́wọ́ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀?"
15:33Júzù 14 · ojú. 264

قَالَ لَمْ أَكُنْ لِأَسْجُدَ لِبَشَرٍ خَلَقْتَهُ مِنْ صَلْصَالٍ مِنْ حَمَإٍ مَسْنُونٍ33

Ó wí pé: "Èmi kò níí forí kanlẹ̀ kí abara kan tí O ṣẹ̀dá rẹ̀ láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà."
15:34Júzù 14 · ojú. 264

قَالَ فَاخْرُجْ مِنْهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٌ34

(Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, jáde kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú, ìwọ ni ẹni-ẹ̀kọ̀.
15:35Júzù 14 · ojú. 264

وَإِنَّ عَلَيْكَ اللَّعْنَةَ إِلَىٰ يَوْمِ الدِّينِ35

Àti pé, dájúdájú ègún ń bẹ lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san."
15:36Júzù 14 · ojú. 264

قَالَ رَبِّ فَأَنْظِرْنِي إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ36

Ó wí pé: “Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di Ọjọ́ Àjíǹde.”
15:37Júzù 14 · ojú. 264

قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ الْمُنْظَرِينَ37

(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn tí A óò lọ́ lára
15:38Júzù 14 · ojú. 264

إِلَىٰ يَوْمِ الْوَقْتِ الْمَعْلُومِ38

títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ."
15:39Júzù 14 · ojú. 264

قَالَ رَبِّ بِمَا أَغْوَيْتَنِي لَأُزَيِّنَنَّ لَهُمْ فِي الْأَرْضِ وَلَأُغْوِيَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ39

Ó wí pé: "Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe mí ní ẹni anù, dájúdájú emí yóò ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún wọn lórí ilẹ̀. Dájúdájú èmi yó sì kó gbogbo wọn sínú anù
15:40Júzù 14 · ojú. 264

إِلَّا عِبَادَكَ مِنْهُمُ الْمُخْلَصِينَ40

àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn ẹni ẹ̀ṣà nínú wọn."
15:41Júzù 14 · ojú. 264

قَالَ هَٰذَا صِرَاطٌ عَلَيَّ مُسْتَقِيمٌ41

(Allāhu) sọ pé: "(Ìdúróṣinṣin lójú) ọ̀nà tààrà, Ọwọ́ Mi ni èyí wà."
15:42Júzù 14 · ojú. 264

إِنَّ عِبَادِي لَيْسَ لَكَ عَلَيْهِمْ سُلْطَانٌ إِلَّا مَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْغَاوِينَ42

Dájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn, àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú àwọn ẹni anù.
15:43Júzù 14 · ojú. 264

وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمَوْعِدُهُمْ أَجْمَعِينَ43

Àti pé dájúdájú iná Jahanamọ ni àdéhùn fún gbogbo wọn.
15:44Júzù 14 · ojú. 264

لَهَا سَبْعَةُ أَبْوَابٍ لِكُلِّ بَابٍ مِنْهُمْ جُزْءٌ مَقْسُومٌ44

Àwọn ojú ọ̀nà méje ń bẹ fún (iná). Àtúnpín tún wà fún ojú-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.
15:45Júzù 14 · ojú. 264

إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ45

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn odò (t’ó ń ṣàn nísàlẹ̀ rẹ̀).
15:46Júzù 14 · ojú. 264

ادْخُلُوهَا بِسَلَامٍ آمِنِينَ46

(A máa sọ pé): “Ẹ wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ní olùfàyàbalẹ̀.”
15:47Júzù 14 · ojú. 264

وَنَزَعْنَا مَا فِي صُدُورِهِمْ مِنْ غِلٍّ إِخْوَانًا عَلَىٰ سُرُرٍ مُتَقَابِلِينَ47

A sì máa yọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn t’ó jẹ́ inúnibíni kúrò; (wọn yóò di) ọmọ-ìyá (ara wọn. Wọn yóò wà) lórí ibùsùn, tí wọn yóò kọjú síra wọn.
15:48Júzù 14 · ojú. 264

لَا يَمَسُّهُمْ فِيهَا نَصَبٌ وَمَا هُمْ مِنْهَا بِمُخْرَجِينَ48

Wàhálà kan kò níí bá wọn nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀.
15:49Júzù 14 · ojú. 264

۞ نَبِّئْ عِبَادِي أَنِّي أَنَا الْغَفُورُ الرَّحِيمُ49

Fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
15:50Júzù 14 · ojú. 264

وَأَنَّ عَذَابِي هُوَ الْعَذَابُ الْأَلِيمُ50

Àti pé dájúdájú ìyà Mi ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
15:51Júzù 14 · ojú. 264

وَنَبِّئْهُمْ عَنْ ضَيْفِ إِبْرَاهِيمَ51

Fún wọn ní ìró nípa àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.
15:52Júzù 14 · ojú. 265

إِذْ دَخَلُوا عَلَيْهِ فَقَالُوا سَلَامًا قَالَ إِنَّا مِنْكُمْ وَجِلُونَ52

(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà”. Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀rù yín ń ba àwa.”
15:53Júzù 14 · ojú. 265

قَالُوا لَا تَوْجَلْ إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَامٍ عَلِيمٍ53

Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwa yóò fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin onímímọ̀ kan."
15:54Júzù 14 · ojú. 265

قَالَ أَبَشَّرْتُمُونِي عَلَىٰ أَنْ مَسَّنِيَ الْكِبَرُ فَبِمَ تُبَشِّرُونَ54

Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀ ń fún mi ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí ọmọ) nígbà tí ogbó ti dé sí mi? Ìró ìdùnnú wo ni ẹ̀ ń fún mi ná?"
15:55Júzù 14 · ojú. 265

قَالُوا بَشَّرْنَاكَ بِالْحَقِّ فَلَا تَكُنْ مِنَ الْقَانِطِينَ55

Wọ́n sọ pé: “À ń fún ọ ní ìró ìdùnnú pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, má ṣe wà lára àwọn olùjákànmùná.”
15:56Júzù 14 · ojú. 265

قَالَ وَمَنْ يَقْنَطُ مِنْ رَحْمَةِ رَبِّهِ إِلَّا الضَّالُّونَ56

Ó sọ pé: “Kò mà sí ẹni tí ó máa jákànmùná nínú ìkẹ́ Olúwa Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn olùṣìnà.”
15:57Júzù 14 · ojú. 265

قَالَ فَمَا خَطْبُكُمْ أَيُّهَا الْمُرْسَلُونَ57

Ó sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”
15:58Júzù 14 · ojú. 265

قَالُوا إِنَّا أُرْسِلْنَا إِلَىٰ قَوْمٍ مُجْرِمِينَ58

Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.
15:59Júzù 14 · ojú. 265

إِلَّا آلَ لُوطٍ إِنَّا لَمُنَجُّوهُمْ أَجْمَعِينَ59

Àfi ará ilé (Ànábì) Lūt. Dájúdájú àwa yóò gba wọn là pátápátá.
15:60Júzù 14 · ojú. 265

إِلَّا امْرَأَتَهُ قَدَّرْنَا ۙ إِنَّهَا لَمِنَ الْغَابِرِينَ60

Àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ kádàrá rẹ̀ (pé) dájúdájú ó máa wà nínú àwọn t’ó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun."
15:61Júzù 14 · ojú. 265

فَلَمَّا جَاءَ آلَ لُوطٍ الْمُرْسَلُونَ61

Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ ará ilé (Ànábì) Lūt,
15:62Júzù 14 · ojú. 265

قَالَ إِنَّكُمْ قَوْمٌ مُنْكَرُونَ62

(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ àjòjì ènìyàn.”
15:63Júzù 14 · ojú. 265

قَالُوا بَلْ جِئْنَاكَ بِمَا كَانُوا فِيهِ يَمْتَرُونَ63

Wọ́n sọ pé: “Rárá, a wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ohun tí wọ́n ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.
15:64Júzù 14 · ojú. 265

وَأَتَيْنَاكَ بِالْحَقِّ وَإِنَّا لَصَادِقُونَ64

A mú òdodo wá bá ọ ni. Àti pé dájúdájú olódodo ni àwa.
15:65Júzù 14 · ojú. 265

فَأَسْرِ بِأَهْلِكَ بِقِطْعٍ مِنَ اللَّيْلِ وَاتَّبِعْ أَدْبَارَهُمْ وَلَا يَلْتَفِتْ مِنْكُمْ أَحَدٌ وَامْضُوا حَيْثُ تُؤْمَرُونَ65

Nítorí náà, mú ará ilé rẹ jáde ní apá kan òru. Kí o sì tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Ẹnì kan nínú yín kò sì gbọdọ̀ ṣíjú wo ẹ̀yìn wò. Kí ẹ sì lọ sí àyè tí wọ́n ń pa láṣẹ fun yín."
15:66Júzù 14 · ojú. 265

وَقَضَيْنَا إِلَيْهِ ذَٰلِكَ الْأَمْرَ أَنَّ دَابِرَ هَٰؤُلَاءِ مَقْطُوعٌ مُصْبِحِينَ66

A sì jẹ́ kí ìdájọ́ ọ̀rọ̀ yìí hàn sí i pé dájúdájú A máa pa àwọn (ẹlẹ́ṣẹ̀) wọ̀nyí run pátápátá nígbà tí wọ́n bá mọ́júmọ́.
15:67Júzù 14 · ojú. 265

وَجَاءَ أَهْلُ الْمَدِينَةِ يَسْتَبْشِرُونَ67

Àwọn ará ìlú náà dé, wọ́n sì ń yọ̀ sẹ̀sẹ̀.
15:68Júzù 14 · ojú. 265

قَالَ إِنَّ هَٰؤُلَاءِ ضَيْفِي فَلَا تَفْضَحُونِ68

(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni àlejò mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe dójú tì mí.
15:69Júzù 14 · ojú. 265

وَاتَّقُوا اللَّهَ وَلَا تُخْزُونِ69

Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe yẹpẹrẹ mi."
15:70Júzù 14 · ojú. 265

قَالُوا أَوَلَمْ نَنْهَكَ عَنِ الْعَالَمِينَ70

Wọ́n wí pé: “Ǹjẹ́ àwa kò ti kọ̀ fún ọ (nípa gbígba àlejò) àwọn ẹ̀dá?”
15:71Júzù 14 · ojú. 266

قَالَ هَٰؤُلَاءِ بَنَاتِي إِنْ كُنْتُمْ فَاعِلِينَ71

Ó sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin mi nìwọ̀nyí, tí ẹ bá ní n̄ǹkan tí ẹ fẹ́ (fi wọ́n) ṣe.”
15:72Júzù 14 · ojú. 266

لَعَمْرُكَ إِنَّهُمْ لَفِي سَكْرَتِهِمْ يَعْمَهُونَ72

(Allāhu sọ pé): “Mo fi ìṣẹ̀mí ìwọ (Ànábì Muhammad) búra; dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú ìdààmú ọpọlọ, tí wọ́n ń pa rìdàrìdà.”
15:73Júzù 14 · ojú. 266

فَأَخَذَتْهُمُ الصَّيْحَةُ مُشْرِقِينَ73

Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn nígbà tí òòrùn òwúrọ̀ yọ sí wọn.
15:74Júzù 14 · ojú. 266

فَجَعَلْنَا عَالِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِمْ حِجَارَةً مِنْ سِجِّيلٍ74

A sì sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí.
15:75Júzù 14 · ojú. 266

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِلْمُتَوَسِّمِينَ75

Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn alárìíwòye.
15:76Júzù 14 · ojú. 266

وَإِنَّهَا لَبِسَبِيلٍ مُقِيمٍ76

Dájúdájú (ìlú náà) kúkú wà lójú ọ̀nà (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).
15:77Júzù 14 · ojú. 266

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِلْمُؤْمِنِينَ77

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
15:78Júzù 14 · ojú. 266

وَإِنْ كَانَ أَصْحَابُ الْأَيْكَةِ لَظَالِمِينَ78

Àwọn ará ’Aekah náà jẹ́ alábòsí.
____________________
’Aekah tún túmọ̀ sí igbó. Ìyẹn ni pé, ìlú tí ó wà nínú igbó. Ará ’Aekah ni ìjọ Ànábì Ṣu‘aeb ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām).
15:79Júzù 14 · ojú. 266

فَانْتَقَمْنَا مِنْهُمْ وَإِنَّهُمَا لَبِإِمَامٍ مُبِينٍ79

A sì gbẹ́san lára wọn. Dájújájú àwọn ìlú méjèèjì l’ó kúkú wà lójú ọ̀nà gban̄gba (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).
15:80Júzù 14 · ojú. 266

وَلَقَدْ كَذَّبَ أَصْحَابُ الْحِجْرِ الْمُرْسَلِينَ80

Dájúdájú àwọn ará Ihò àpáta pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
15:81Júzù 14 · ojú. 266

وَآتَيْنَاهُمْ آيَاتِنَا فَكَانُوا عَنْهَا مُعْرِضِينَ81

A sì fún wọn ní àwọn àmì Wa. Àmọ́ wọ́n gbúnrí kúrò níbẹ̀.
15:82Júzù 14 · ojú. 266

وَكَانُوا يَنْحِتُونَ مِنَ الْجِبَالِ بُيُوتًا آمِنِينَ82

Wọ́n máa ń gbẹ́ àwọn ilé ìgbé ìfàyàbalẹ̀ sínú àwọn àpáta.
15:83Júzù 14 · ojú. 266

فَأَخَذَتْهُمُ الصَّيْحَةُ مُصْبِحِينَ83

Ohùn igbe sì mú wọn nígbà tí wọ́n mọ́júmọ́.
15:84Júzù 14 · ojú. 266

فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَكْسِبُونَ84

Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
15:85Júzù 14 · ojú. 266

وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ ۗ وَإِنَّ السَّاعَةَ لَآتِيَةٌ ۖ فَاصْفَحِ الصَّفْحَ الْجَمِيلَ85

A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú Àkókò náà máa dé. Nítorí náà, ṣàmójúkúrò ní àmójúkúrò t’ó rẹwà.
15:86Júzù 14 · ojú. 266

إِنَّ رَبَّكَ هُوَ الْخَلَّاقُ الْعَلِيمُ86

Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.
15:87Júzù 14 · ojú. 266

وَلَقَدْ آتَيْنَاكَ سَبْعًا مِنَ الْمَثَانِي وَالْقُرْآنَ الْعَظِيمَ87

Dájúdájú A fún ọ ní Sab‘u Mọthānī (ìyẹn, sūrah al-Fātihah) àti al-Ƙur’ān t’ó tóbi.
15:88Júzù 14 · ojú. 266

لَا تَمُدَّنَّ عَيْنَيْكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعْنَا بِهِ أَزْوَاجًا مِنْهُمْ وَلَا تَحْزَنْ عَلَيْهِمْ وَاخْفِضْ جَنَاحَكَ لِلْمُؤْمِنِينَ88

Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣíjú rẹ wo ohun tí A fi ṣe ìgbádún ayé lóríṣiríṣi fún àwọn kan nínú wọn. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
15:89Júzù 14 · ojú. 266

وَقُلْ إِنِّي أَنَا النَّذِيرُ الْمُبِينُ89

Kí o sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
15:90Júzù 14 · ojú. 266

كَمَا أَنْزَلْنَا عَلَى الْمُقْتَسِمِينَ90

Gẹ́gẹ́ bí A ṣe sọ (ìyà) kalẹ̀ fún àwọn t’ó ń pín òdodo mọ́ irọ́;
____________________
Pípín òdodo mọ́ irọ́ ni pípín al-Ƙur’ān mọ́ orin, idán, ìdábigba, àlá lílá àti ààlọ́.
15:91Júzù 14 · ojú. 267

الَّذِينَ جَعَلُوا الْقُرْآنَ عِضِينَ91

àwọn tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān di ìpínkúpìn-ín,
15:92Júzù 14 · ojú. 267

فَوَرَبِّكَ لَنَسْأَلَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ92

Olúwa rẹ fi Ara Rẹ̀ búra fún ọ pé, A máa bi gbogbo wọn ní ìbéèrè
15:93Júzù 14 · ojú. 267

عَمَّا كَانُوا يَعْمَلُونَ93

nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
15:94Júzù 14 · ojú. 267

فَاصْدَعْ بِمَا تُؤْمَرُ وَأَعْرِضْ عَنِ الْمُشْرِكِينَ94

Nítorí náà, kéde n̄ǹkan tí A pa láṣẹ fún ọ. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ.
15:95Júzù 14 · ojú. 267

إِنَّا كَفَيْنَاكَ الْمُسْتَهْزِئِينَ95

Dájúdájú Àwa yóò tó ọ (níbi aburú) àwọn oníyẹ̀yẹ́,
15:96Júzù 14 · ojú. 267

الَّذِينَ يَجْعَلُونَ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ ۚ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ96

àwọn t’ó ń mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
15:97Júzù 14 · ojú. 267

وَلَقَدْ نَعْلَمُ أَنَّكَ يَضِيقُ صَدْرُكَ بِمَا يَقُولُونَ97

Àwa kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń wí ń kó ìnira bá ọ.
15:98Júzù 14 · ojú. 267

فَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ وَكُنْ مِنَ السَّاجِدِينَ98

Nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ. Kí o sì wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Un).
15:99Júzù 14 · ojú. 267

وَاعْبُدْ رَبَّكَ حَتَّىٰ يَأْتِيَكَ الْيَقِينُ99

Jọ́sìn fún Olúwa rẹ títí àmọ̀dájú (ìyẹn, ikú) yóò fi dé bá ọ.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà