Al-Ghashiyah

سورة الغاشية

Súrà 88 · Mákí · 26 àwọn ẹsẹ

88:1Júzù 30 · ojú. 592

هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ الْغَاشِيَةِ1

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ohun t’ó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
88:2Júzù 30 · ojú. 592

وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ خَاشِعَةٌ2

Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn.
88:3Júzù 30 · ojú. 592

عَامِلَةٌ نَاصِبَةٌ3

Oníṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni wọ́n nílé ayé).
88:4Júzù 30 · ojú. 592

تَصْلَىٰ نَارًا حَامِيَةً4

Wọ́n máa wọ inú Iná t’ó gbóná janjan (ní ọ̀run).
88:5Júzù 30 · ojú. 592

تُسْقَىٰ مِنْ عَيْنٍ آنِيَةٍ5

Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi gbígbóná mu.
88:6Júzù 30 · ojú. 592

لَيْسَ لَهُمْ طَعَامٌ إِلَّا مِنْ ضَرِيعٍ6

Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ.
88:7Júzù 30 · ojú. 592

لَا يُسْمِنُ وَلَا يُغْنِي مِنْ جُوعٍ7

Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi.
88:8Júzù 30 · ojú. 592

وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ نَاعِمَةٌ8

Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn
88:9Júzù 30 · ojú. 592

لِسَعْيِهَا رَاضِيَةٌ9

nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀.
88:10Júzù 30 · ojú. 592

فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٍ10

(Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.
88:11Júzù 30 · ojú. 592

لَا تَسْمَعُ فِيهَا لَاغِيَةً11

Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀.
88:12Júzù 30 · ojú. 592

فِيهَا عَيْنٌ جَارِيَةٌ12

Omi ìṣẹ́lẹ̀rú t’ó ń ṣàn wà nínú rẹ̀.
88:13Júzù 30 · ojú. 592

فِيهَا سُرُرٌ مَرْفُوعَةٌ13

Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀,
88:14Júzù 30 · ojú. 592

وَأَكْوَابٌ مَوْضُوعَةٌ14

àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn),
88:15Júzù 30 · ojú. 592

وَنَمَارِقُ مَصْفُوفَةٌ15

àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn,
88:16Júzù 30 · ojú. 592

وَزَرَابِيُّ مَبْثُوثَةٌ16

àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká.
88:17Júzù 30 · ojú. 592

أَفَلَا يَنْظُرُونَ إِلَى الْإِبِلِ كَيْفَ خُلِقَتْ17

Nítorí náà, ṣé wọn kò wo ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni;
88:18Júzù 30 · ojú. 592

وَإِلَى السَّمَاءِ كَيْفَ رُفِعَتْ18

àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè;
88:19Júzù 30 · ojú. 592

وَإِلَى الْجِبَالِ كَيْفَ نُصِبَتْ19

àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀);
88:20Júzù 30 · ojú. 592

وَإِلَى الْأَرْضِ كَيْفَ سُطِحَتْ20

àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ ní gban̄sasa?
88:21Júzù 30 · ojú. 592

فَذَكِّرْ إِنَّمَا أَنْتَ مُذَكِّرٌ21

Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí.
88:22Júzù 30 · ojú. 592

لَسْتَ عَلَيْهِمْ بِمُصَيْطِرٍ22

Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn
88:23Júzù 30 · ojú. 593

إِلَّا مَنْ تَوَلَّىٰ وَكَفَرَ23

àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́.
88:24Júzù 30 · ojú. 593

فَيُعَذِّبُهُ اللَّهُ الْعَذَابَ الْأَكْبَرَ24

Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà t’ó tóbi jùlọ.
88:25Júzù 30 · ojú. 593

إِنَّ إِلَيْنَا إِيَابَهُمْ25

Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà.
88:26Júzù 30 · ojú. 593

ثُمَّ إِنَّ عَلَيْنَا حِسَابَهُمْ26

Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà