Al-Mursalat

سورة المرسلات

Súrà 77 · Mákí · 50 àwọn ẹsẹ

77:1Júzù 29 · ojú. 580

وَالْمُرْسَلَاتِ عُرْفًا1

Allāhu búra pẹ̀lú àwọn atẹ́gùn t’ó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.
77:2Júzù 29 · ojú. 580

فَالْعَاصِفَاتِ عَصْفًا2

Ó búra pẹ̀lú àwọn ìjì atẹ́gùn t’ó ń jà.
77:3Júzù 29 · ojú. 580

وَالنَّاشِرَاتِ نَشْرًا3

Ó búra pẹ̀lú àwọn atẹ́gùn t’ó ń tú èṣújò ká.
77:4Júzù 29 · ojú. 580

فَالْفَارِقَاتِ فَرْقًا4

Ó búra pẹ̀lú àwọn t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́.
77:5Júzù 29 · ojú. 580

فَالْمُلْقِيَاتِ ذِكْرًا5

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́).
77:6Júzù 29 · ojú. 580

عُذْرًا أَوْ نُذْرًا6

(Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀.
77:7Júzù 29 · ojú. 580

إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَاقِعٌ7

Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fun yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.
77:8Júzù 29 · ojú. 580

فَإِذَا النُّجُومُ طُمِسَتْ8

Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́,
77:9Júzù 29 · ojú. 580

وَإِذَا السَّمَاءُ فُرِجَتْ9

àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,
77:10Júzù 29 · ojú. 580

وَإِذَا الْجِبَالُ نُسِفَتْ10

àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù,
77:11Júzù 29 · ojú. 580

وَإِذَا الرُّسُلُ أُقِّتَتْ11

àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ, (Àkókò náà ti dé nìyẹn).
77:12Júzù 29 · ojú. 580

لِأَيِّ يَوْمٍ أُجِّلَتْ12

Ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná?
77:13Júzù 29 · ojú. 580

لِيَوْمِ الْفَصْلِ13

Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni.
77:14Júzù 29 · ojú. 580

وَمَا أَدْرَاكَ مَا يَوْمُ الْفَصْلِ14

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà?
77:15Júzù 29 · ojú. 580

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ15

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:16Júzù 29 · ojú. 580

أَلَمْ نُهْلِكِ الْأَوَّلِينَ16

Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí?
77:17Júzù 29 · ojú. 580

ثُمَّ نُتْبِعُهُمُ الْآخِرِينَ17

Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun).
77:18Júzù 29 · ojú. 580

كَذَٰلِكَ نَفْعَلُ بِالْمُجْرِمِينَ18

Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
77:19Júzù 29 · ojú. 580

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ19

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:20Júzù 29 · ojú. 581

أَلَمْ نَخْلُقْكُمْ مِنْ مَاءٍ مَهِينٍ20

Ṣé A ò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí?
77:21Júzù 29 · ojú. 581

فَجَعَلْنَاهُ فِي قَرَارٍ مَكِينٍ21

Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)
77:22Júzù 29 · ojú. 581

إِلَىٰ قَدَرٍ مَعْلُومٍ22

títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ).
77:23Júzù 29 · ojú. 581

فَقَدَرْنَا فَنِعْمَ الْقَادِرُونَ23

A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀). (Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá t’ó dára.
77:24Júzù 29 · ojú. 581

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ24

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:25Júzù 29 · ojú. 581

أَلَمْ نَجْعَلِ الْأَرْضَ كِفَاتًا25

Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun t’ó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;
77:26Júzù 29 · ojú. 581

أَحْيَاءً وَأَمْوَاتًا26

(ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?
77:27Júzù 29 · ojú. 581

وَجَعَلْنَا فِيهَا رَوَاسِيَ شَامِخَاتٍ وَأَسْقَيْنَاكُمْ مَاءً فُرَاتًا27

A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fun yín ní omi dídùn mu.
77:28Júzù 29 · ojú. 581

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ28

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:29Júzù 29 · ojú. 581

انْطَلِقُوا إِلَىٰ مَا كُنْتُمْ بِهِ تُكَذِّبُونَ29

Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè nírọ́.
77:30Júzù 29 · ojú. 581

انْطَلِقُوا إِلَىٰ ظِلٍّ ذِي ثَلَاثِ شُعَبٍ30

Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta.
77:31Júzù 29 · ojú. 581

لَا ظَلِيلٍ وَلَا يُغْنِي مِنَ اللَّهَبِ31

Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná.
77:32Júzù 29 · ojú. 581

إِنَّهَا تَرْمِي بِشَرَرٍ كَالْقَصْرِ32

Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè t’ó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.
77:33Júzù 29 · ojú. 581

كَأَنَّهُ جِمَالَتٌ صُفْرٌ33

(Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn.
77:34Júzù 29 · ojú. 581

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ34

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:35Júzù 29 · ojú. 581

هَٰذَا يَوْمُ لَا يَنْطِقُونَ35

Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀.
77:36Júzù 29 · ojú. 581

وَلَا يُؤْذَنُ لَهُمْ فَيَعْتَذِرُونَ36

A ò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá.
77:37Júzù 29 · ojú. 581

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ37

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:38Júzù 29 · ojú. 581

هَٰذَا يَوْمُ الْفَصْلِ ۖ جَمَعْنَاكُمْ وَالْأَوَّلِينَ38

Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ.
77:39Júzù 29 · ojú. 581

فَإِنْ كَانَ لَكُمْ كَيْدٌ فَكِيدُونِ39

Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò.
77:40Júzù 29 · ojú. 581

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ40

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:41Júzù 29 · ojú. 581

إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي ظِلَالٍ وَعُيُونٍ41

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú,
77:42Júzù 29 · ojú. 581

وَفَوَاكِهَ مِمَّا يَشْتَهُونَ42

àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́.
77:43Júzù 29 · ojú. 581

كُلُوا وَاشْرَبُوا هَنِيئًا بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ43

Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
77:44Júzù 29 · ojú. 581

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ44

Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
77:45Júzù 29 · ojú. 581

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ45

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:46Júzù 29 · ojú. 581

كُلُوا وَتَمَتَّعُوا قَلِيلًا إِنَّكُمْ مُجْرِمُونَ46

Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.
77:47Júzù 29 · ojú. 581

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ47

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:48Júzù 29 · ojú. 581

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ارْكَعُوا لَا يَرْكَعُونَ48

Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun.
77:49Júzù 29 · ojú. 581

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ49

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:50Júzù 29 · ojú. 581

فَبِأَيِّ حَدِيثٍ بَعْدَهُ يُؤْمِنُونَ50

Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:185.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà