Adh-Dhariyat

سورة الذاريات

Súrà 51 · Mákí · 60 àwọn ẹsẹ

51:1Júzù 26 · ojú. 520

وَالذَّارِيَاتِ ذَرْوًا1

(Allāhu búra pẹ̀lú) atẹ́gùn t’ó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ tààrà.
51:2Júzù 26 · ojú. 520

فَالْحَامِلَاتِ وِقْرًا2

(Ó búra pẹ̀lú) àwọn ẹ̀ṣújò t’ó wúwo rinrin.
51:3Júzù 26 · ojú. 520

فَالْجَارِيَاتِ يُسْرًا3

(Ó búra pẹ̀lú) àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn.
51:4Júzù 26 · ojú. 520

فَالْمُقَسِّمَاتِ أَمْرًا4

(Ó búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika t’ó ń pín n̄ǹkan (tí Ó ti pín fún ẹ̀dá).
51:5Júzù 26 · ojú. 520

إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَصَادِقٌ5

Òdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín.
51:6Júzù 26 · ojú. 520

وَإِنَّ الدِّينَ لَوَاقِعٌ6

Àti pé dájúdájú Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀.
51:7Júzù 26 · ojú. 521

وَالسَّمَاءِ ذَاتِ الْحُبُكِ7

(Allāhu tún búra pẹ̀lú) sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́.
51:8Júzù 26 · ojú. 521

إِنَّكُمْ لَفِي قَوْلٍ مُخْتَلِفٍ8

Dájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ t’ó ń takora wọn (nípa al-Ƙur’ān).
51:9Júzù 26 · ojú. 521

يُؤْفَكُ عَنْهُ مَنْ أُفِكَ9

Ẹni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur’ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ).
51:10Júzù 26 · ojú. 521

قُتِلَ الْخَرَّاصُونَ10

Ègbé ni fún àwọn òpùrọ́;
51:11Júzù 26 · ojú. 521

الَّذِينَ هُمْ فِي غَمْرَةٍ سَاهُونَ11

àwọn ni wọ́n wà nínú àìmọ̀kan, àwọn onígbàgbé,
51:12Júzù 26 · ojú. 521

يَسْأَلُونَ أَيَّانَ يَوْمُ الدِّينِ12

tí wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀.
51:13Júzù 26 · ojú. 521

يَوْمَ هُمْ عَلَى النَّارِ يُفْتَنُونَ13

Ní ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà.
51:14Júzù 26 · ojú. 521

ذُوقُوا فِتْنَتَكُمْ هَٰذَا الَّذِي كُنْتُمْ بِهِ تَسْتَعْجِلُونَ14

Ẹ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú.
51:15Júzù 26 · ojú. 521

إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ15

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
51:16Júzù 26 · ojú. 521

آخِذِينَ مَا آتَاهُمْ رَبُّهُمْ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَبْلَ ذَٰلِكَ مُحْسِنِينَ16

Wọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn.
51:17Júzù 26 · ojú. 521

كَانُوا قَلِيلًا مِنَ اللَّيْلِ مَا يَهْجَعُونَ17

Wọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru.
51:18Júzù 26 · ojú. 521

وَبِالْأَسْحَارِ هُمْ يَسْتَغْفِرُونَ18

Wọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.
51:19Júzù 26 · ojú. 521

وَفِي أَمْوَالِهِمْ حَقٌّ لِلسَّائِلِ وَالْمَحْرُومِ19

Nínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún.
51:20Júzù 26 · ojú. 521

وَفِي الْأَرْضِ آيَاتٌ لِلْمُوقِنِينَ20

Àwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú.
51:21Júzù 26 · ojú. 521

وَفِي أَنْفُسِكُمْ ۚ أَفَلَا تُبْصِرُونَ21

Nínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ ò ríran ni?
51:22Júzù 26 · ojú. 521

وَفِي السَّمَاءِ رِزْقُكُمْ وَمَا تُوعَدُونَ22

Arísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín wà nínú sánmọ̀.
51:23Júzù 26 · ojú. 521

فَوَرَبِّ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ إِنَّهُ لَحَقٌّ مِثْلَ مَا أَنَّكُمْ تَنْطِقُونَ23

Nítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀.
51:24Júzù 26 · ojú. 521

هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ ضَيْفِ إِبْرَاهِيمَ الْمُكْرَمِينَ24

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
51:25Júzù 26 · ojú. 521

إِذْ دَخَلُوا عَلَيْهِ فَقَالُوا سَلَامًا ۖ قَالَ سَلَامٌ قَوْمٌ مُنْكَرُونَ25

(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: "Àlàáfíà (fún ọ)." Òun náà sọ pé: "Àlàáfíà (fun yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn."
51:26Júzù 26 · ojú. 521

فَرَاغَ إِلَىٰ أَهْلِهِ فَجَاءَ بِعِجْلٍ سَمِينٍ26

Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù ọlọ́ràá (àyangbẹ).
51:27Júzù 26 · ojú. 521

فَقَرَّبَهُ إِلَيْهِمْ قَالَ أَلَا تَأْكُلُونَ27

Ó gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni?"
51:28Júzù 26 · ojú. 521

فَأَوْجَسَ مِنْهُمْ خِيفَةً ۖ قَالُوا لَا تَخَفْ ۖ وَبَشَّرُوهُ بِغُلَامٍ عَلِيمٍ28

Nígbà náà, ó ní ìpáyà wọn nínú ọkàn. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe páyà." Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin onímọ̀ kan.
51:29Júzù 26 · ojú. 521

فَأَقْبَلَتِ امْرَأَتُهُ فِي صَرَّةٍ فَصَكَّتْ وَجْهَهَا وَقَالَتْ عَجُوزٌ عَقِيمٌ29

Nígbà náà, ìyàwó rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: "Arúgbó, àgàn (mà ni mí)!"
51:30Júzù 26 · ojú. 521

قَالُوا كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِ ۖ إِنَّهُ هُوَ الْحَكِيمُ الْعَلِيمُ30

Wọ́n sọ pé: "Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀."
51:31Júzù 27 · ojú. 522

۞ قَالَ فَمَا خَطْبُكُمْ أَيُّهَا الْمُرْسَلُونَ31

(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?"
51:32Júzù 27 · ojú. 522

قَالُوا إِنَّا أُرْسِلْنَا إِلَىٰ قَوْمٍ مُجْرِمِينَ32

Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni
51:33Júzù 27 · ojú. 522

لِنُرْسِلَ عَلَيْهِمْ حِجَارَةً مِنْ طِينٍ33

nítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn.
51:34Júzù 27 · ojú. 522

مُسَوَّمَةً عِنْدَ رَبِّكَ لِلْمُسْرِفِينَ34

Wọ́n ti fàmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ."
51:35Júzù 27 · ojú. 522

فَأَخْرَجْنَا مَنْ كَانَ فِيهَا مِنَ الْمُؤْمِنِينَ35

Nítorí náà, A mú àwọn t’ó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà).
51:36Júzù 27 · ojú. 522

فَمَا وَجَدْنَا فِيهَا غَيْرَ بَيْتٍ مِنَ الْمُسْلِمِينَ36

A ò sì rí nínú (ìlú náà) tayọ ilé kan t’ó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí.
51:37Júzù 27 · ojú. 522

وَتَرَكْنَا فِيهَا آيَةً لِلَّذِينَ يَخَافُونَ الْعَذَابَ الْأَلِيمَ37

A sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn t’ó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
51:38Júzù 27 · ojú. 522

وَفِي مُوسَىٰ إِذْ أَرْسَلْنَاهُ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ بِسُلْطَانٍ مُبِينٍ38

(Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon.
51:39Júzù 27 · ojú. 522

فَتَوَلَّىٰ بِرُكْنِهِ وَقَالَ سَاحِرٌ أَوْ مَجْنُونٌ39

Ṣùgbọ́n (Fir‘aon) gbúnrí pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó sì wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí)."
51:40Júzù 27 · ojú. 522

فَأَخَذْنَاهُ وَجُنُودَهُ فَنَبَذْنَاهُمْ فِي الْيَمِّ وَهُوَ مُلِيمٌ40

Nítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù.
51:41Júzù 27 · ojú. 522

وَفِي عَادٍ إِذْ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمُ الرِّيحَ الْعَقِيمَ41

(Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn,
51:42Júzù 27 · ojú. 522

مَا تَذَرُ مِنْ شَيْءٍ أَتَتْ عَلَيْهِ إِلَّا جَعَلَتْهُ كَالرَّمِيمِ42

kò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kó sọ ọ́ di bí èso rírún túútú.
51:43Júzù 27 · ojú. 522

وَفِي ثَمُودَ إِذْ قِيلَ لَهُمْ تَمَتَّعُوا حَتَّىٰ حِينٍ43

(Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: "Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná."
51:44Júzù 27 · ojú. 522

فَعَتَوْا عَنْ أَمْرِ رَبِّهِمْ فَأَخَذَتْهُمُ الصَّاعِقَةُ وَهُمْ يَنْظُرُونَ44

Wọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, igbe ìparun mú wọ́n; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀.
51:45Júzù 27 · ojú. 522

فَمَا اسْتَطَاعُوا مِنْ قِيَامٍ وَمَا كَانُوا مُنْتَصِرِينَ45

Wọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́.
51:46Júzù 27 · ojú. 522

وَقَوْمَ نُوحٍ مِنْ قَبْلُ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا فَاسِقِينَ46

Àti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú Àwa sì ni olùgbòòrò.
51:47Júzù 27 · ojú. 522

وَالسَّمَاءَ بَنَيْنَاهَا بِأَيْدٍ وَإِنَّا لَمُوسِعُونَ47

Àti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni olùgbòòrò.
51:48Júzù 27 · ojú. 522

وَالْأَرْضَ فَرَشْنَاهَا فَنِعْمَ الْمَاهِدُونَ48

Àti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. Àwọn olùtẹ́lẹ̀-sílẹ̀ sì dára.
51:49Júzù 27 · ojú. 522

وَمِنْ كُلِّ شَيْءٍ خَلَقْنَا زَوْجَيْنِ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ49

Àti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yāsīn; 36:36.
51:50Júzù 27 · ojú. 522

فَفِرُّوا إِلَى اللَّهِ ۖ إِنِّي لَكُمْ مِنْهُ نَذِيرٌ مُبِينٌ50

Nítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
51:51Júzù 27 · ojú. 522

وَلَا تَجْعَلُوا مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ ۖ إِنِّي لَكُمْ مِنْهُ نَذِيرٌ مُبِينٌ51

Ẹ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
51:52Júzù 27 · ojú. 523

كَذَٰلِكَ مَا أَتَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ مِنْ رَسُولٍ إِلَّا قَالُوا سَاحِرٌ أَوْ مَجْنُونٌ52

Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn t’ó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè ni."
51:53Júzù 27 · ojú. 523

أَتَوَاصَوْا بِهِ ۚ بَلْ هُمْ قَوْمٌ طَاغُونَ53

Ṣé wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-àlà ni wọ́n ni.
51:54Júzù 27 · ojú. 523

فَتَوَلَّ عَنْهُمْ فَمَا أَنْتَ بِمَلُومٍ54

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe alábùkù.
51:55Júzù 27 · ojú. 523

وَذَكِّرْ فَإِنَّ الذِّكْرَىٰ تَنْفَعُ الْمُؤْمِنِينَ55

Ṣèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
51:56Júzù 27 · ojú. 523

وَمَا خَلَقْتُ الْجِنَّ وَالْإِنْسَ إِلَّا لِيَعْبُدُونِ56

Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi.
51:57Júzù 27 · ojú. 523

مَا أُرِيدُ مِنْهُمْ مِنْ رِزْقٍ وَمَا أُرِيدُ أَنْ يُطْعِمُونِ57

Èmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi.
51:58Júzù 27 · ojú. 523

إِنَّ اللَّهَ هُوَ الرَّزَّاقُ ذُو الْقُوَّةِ الْمَتِينُ58

Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle.
51:59Júzù 27 · ojú. 523

فَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا ذَنُوبًا مِثْلَ ذَنُوبِ أَصْحَابِهِمْ فَلَا يَسْتَعْجِلُونِ59

Dájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn t’ó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn).
51:60Júzù 27 · ojú. 523

فَوَيْلٌ لِلَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ يَوْمِهِمُ الَّذِي يُوعَدُونَ60

Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà