Ash-Shu'ara

سورة الشعراء

Súrà 26 · Mákí · 227 àwọn ẹsẹ

26:1Júzù 19 · ojú. 367

طسم1

Tọ̄ sīn mīm.
26:2Júzù 19 · ojú. 367

تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ الْمُبِينِ2

Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
26:3Júzù 19 · ojú. 367

لَعَلَّكَ بَاخِعٌ نَفْسَكَ أَلَّا يَكُونُوا مُؤْمِنِينَ3

Nítorí kí ni o ṣe máa para rẹ pé wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
26:4Júzù 19 · ojú. 367

إِنْ نَشَأْ نُنَزِّلْ عَلَيْهِمْ مِنَ السَّمَاءِ آيَةً فَظَلَّتْ أَعْنَاقُهُمْ لَهَا خَاضِعِينَ4

Tí A bá fẹ́, A máa sọ àmì kan kalẹ̀ fún wọn láti sánmọ̀. Àwọn ọrùn wọn kò sì níí yé tẹríba fún un.
26:5Júzù 19 · ojú. 367

وَمَا يَأْتِيهِمْ مِنْ ذِكْرٍ مِنَ الرَّحْمَٰنِ مُحْدَثٍ إِلَّا كَانُوا عَنْهُ مُعْرِضِينَ5

Kò sí ìrántí kan tí ó máa dé bá wọn ní titun láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé àfi kí wọ́n jẹ́ olùgbúnrí kúrò níbẹ̀.
26:6Júzù 19 · ojú. 367

فَقَدْ كَذَّبُوا فَسَيَأْتِيهِمْ أَنْبَاءُ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ6

Dájúdájú wọ́n ti pe (āyah Wa) nírọ́. Nítorí náà, àwọn ìró ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn.
26:7Júzù 19 · ojú. 367

أَوَلَمْ يَرَوْا إِلَى الْأَرْضِ كَمْ أَنْبَتْنَا فِيهَا مِنْ كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ7

Ṣé wọn kò rí ilẹ̀ pé mélòó mélòó nínú gbogbo oríṣiríṣi n̄ǹkan alápọ̀n-ọ́nlé tí A mú hù jáde láti inú rẹ̀?
26:8Júzù 19 · ojú. 367

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ8

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
26:9Júzù 19 · ojú. 367

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ9

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
26:10Júzù 19 · ojú. 367

وَإِذْ نَادَىٰ رَبُّكَ مُوسَىٰ أَنِ ائْتِ الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ10

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ pe (Ànábì) Mūsā pé: "Lọ bá ìjọ alábòsí,
26:11Júzù 19 · ojú. 367

قَوْمَ فِرْعَوْنَ ۚ أَلَا يَتَّقُونَ11

ìjọ Fir‘aon (kí o sì sọ̱ fún wọn) pé 'Ṣé wọn kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni.'"
26:12Júzù 19 · ojú. 367

قَالَ رَبِّ إِنِّي أَخَافُ أَنْ يُكَذِّبُونِ12

Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.
26:13Júzù 19 · ojú. 367

وَيَضِيقُ صَدْرِي وَلَا يَنْطَلِقُ لِسَانِي فَأَرْسِلْ إِلَىٰ هَارُونَ13

Ó sì máa jẹ́ ìnira fún mi (tí wọ́n bá pè mí ní òpùrọ́). Ahọ́n mi kò sì já gaaraga. Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Hārūn.
26:14Júzù 19 · ojú. 367

وَلَهُمْ عَلَيَّ ذَنْبٌ فَأَخَافُ أَنْ يَقْتُلُونِ14

Àti pé mo ní ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́rùn lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí."
26:15Júzù 19 · ojú. 367

قَالَ كَلَّا ۖ فَاذْهَبَا بِآيَاتِنَا ۖ إِنَّا مَعَكُمْ مُسْتَمِعُونَ15

(Allāhu) sọ pé: "Rárá (wọn kò lè pa ọ́). Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Wa lọ (bá wọn). Dájúdájú Àwa ń bẹ pẹ̀lú yín; À ń gbọ́ (ọ̀rọ̀ yín).
26:16Júzù 19 · ojú. 367

فَأْتِيَا فِرْعَوْنَ فَقُولَا إِنَّا رَسُولُ رَبِّ الْعَالَمِينَ16

Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ bá Fir‘aon. Kí ẹ sọ fún un pé: 'Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
26:17Júzù 19 · ojú. 367

أَنْ أَرْسِلْ مَعَنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ17

(À ń sọ fún ọ) pé kí o jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ.'"
26:18Júzù 19 · ojú. 367

قَالَ أَلَمْ نُرَبِّكَ فِينَا وَلِيدًا وَلَبِثْتَ فِينَا مِنْ عُمُرِكَ سِنِينَ18

(Fir‘aon) wí pé: “Ṣé kì í ṣe ní ààrin wa ni a ti tọ́ ọ ní kékeré ni, tí o sì gbé ní ọ̀dọ̀ wa fún ọdún púpọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ?
26:19Júzù 19 · ojú. 367

وَفَعَلْتَ فَعْلَتَكَ الَّتِي فَعَلْتَ وَأَنْتَ مِنَ الْكَافِرِينَ19

O sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí o ṣe (sí wa). Ìwọ sì wà nínú àwọn aláìmoore.”
26:20Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ فَعَلْتُهَا إِذًا وَأَنَا مِنَ الضَّالِّينَ20

(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Mo ṣe é nígbà náà nígbà tí mo wà nínú àwọn aláìmọ̀kan ni.
26:21Júzù 19 · ojú. 368

فَفَرَرْتُ مِنْكُمْ لَمَّا خِفْتُكُمْ فَوَهَبَ لِي رَبِّي حُكْمًا وَجَعَلَنِي مِنَ الْمُرْسَلِينَ21

Mo sì sá fun yín nígbà tí mo bẹ̀rù yín. Nítorí náà, Allāhu ti ta mí lọ́rẹ ipò Ànábì. Ó sì ṣe mí ní (ọ̀kan) nínú àwọn Òjíṣẹ́.
26:22Júzù 19 · ojú. 368

وَتِلْكَ نِعْمَةٌ تَمُنُّهَا عَلَيَّ أَنْ عَبَّدْتَ بَنِي إِسْرَائِيلَ22

Àti pé ìyẹn ni ìdẹ̀ra tí ò ń ṣe ìrègún rẹ̀ lé mi lórí. Pé ó sọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl di ẹrú (ńkọ́?).
____________________
Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń fọ èsì fún Fir ‘aon pé, tí o bá sọ pé o ṣoore alágbàtọ́ fún mi, ṣebí o tún sọ àwọn ènìyàn mi di ẹrú rẹ?! Ìyẹn ni pé, tí Fir ‘aon bá mọ ìrègún oore síṣe alágbàtọ́ òun í ṣe, kó rántí aburú ńlá t’ó wà nínú bí ó ṣe sọ àwọn ènìyàn t’òun náà di ẹrú rẹ̀. Nítorí náà, kí Fir ‘aon má ṣe lérò pé gbígba ẹnì kan wò tẹ̀wọ̀n ju sísọ àwọn yòókù rẹ̀ di ẹrú. Fir‘aon sì mẹ́nu kúrò níbẹ̀. Ó bọ́ sórí ọ̀rọ̀ mìíràn.
26:23Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ فِرْعَوْنُ وَمَا رَبُّ الْعَالَمِينَ23

Fir‘aon wí pé: “Kí ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”
26:24Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِنْ كُنْتُمْ مُوقِنِينَ24

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni)
Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.”
26:25Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ لِمَنْ حَوْلَهُ أَلَا تَسْتَمِعُونَ25

(Fir‘aon) wí fún àwọn t’ó wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ (t’ó ń sọ ni)?”
26:26Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ رَبُّكُمْ وَرَبُّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ26

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
26:27Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ إِنَّ رَسُولَكُمُ الَّذِي أُرْسِلَ إِلَيْكُمْ لَمَجْنُونٌ27

(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ yín èyí tí wọ́n rán si yín, wèrè mà ni.”
26:28Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ رَبُّ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِنْ كُنْتُمْ تَعْقِلُونَ28

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa ibùyọ òòrùn, ibùwọ̀ òòrùn àti ohunkóhun t’ó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ bá máa ń ṣe làákàyè.”
26:29Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ لَئِنِ اتَّخَذْتَ إِلَٰهًا غَيْرِي لَأَجْعَلَنَّكَ مِنَ الْمَسْجُونِينَ29

(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú tí o bá fi lè jọ́sìn fún ọlọ́hun kan yàtọ̀ sí mi, dájúdájú mo máa sọ ọ́ di ara àwọn ẹlẹ́wọ̀n.”
26:30Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ أَوَلَوْ جِئْتُكَ بِشَيْءٍ مُبِينٍ30

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé mo mú kiní kan t’ó yanjú wá fún ọ ńkọ́?”
26:31Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ فَأْتِ بِهِ إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ31

(Fir‘aon) wí pé: “Mú un wá nígbà náà tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”
26:32Júzù 19 · ojú. 368

فَأَلْقَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ ثُعْبَانٌ مُبِينٌ32

Nítorí náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé.
26:33Júzù 19 · ojú. 368

وَنَزَعَ يَدَهُ فَإِذَا هِيَ بَيْضَاءُ لِلنَّاظِرِينَ33

Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ síta, ó sì di funfun fún àwọn olùwòran.
26:34Júzù 19 · ojú. 368

قَالَ لِلْمَلَإِ حَوْلَهُ إِنَّ هَٰذَا لَسَاحِرٌ عَلِيمٌ34

(Fir‘aon) wí fún àwọn ìjòyè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa.
26:35Júzù 19 · ojú. 368

يُرِيدُ أَنْ يُخْرِجَكُمْ مِنْ أَرْضِكُمْ بِسِحْرِهِ فَمَاذَا تَأْمُرُونَ35

Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni. Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”
____________________
Nínú sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:109- 110, gbólóhùn "Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa. Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni.", ó jáde láti ẹnu àwọn ìjòyè Fir‘aon. Àmọ́ nínú sūrah yìí, sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26: 34-35, gbólóhùn yẹn jáde láti ẹnu Fir‘aon. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, Fir‘aon sọ gbólóhùn náà, àwọn ìjòyè rẹ̀ náà gbè é lẹ́sẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà sì di àgbàsọ láààrin wọn.
26:36Júzù 19 · ojú. 368

قَالُوا أَرْجِهْ وَأَخَاهُ وَابْعَثْ فِي الْمَدَائِنِ حَاشِرِينَ36

Wọ́n wí pé: "Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ sí àwọn ìlú
26:37Júzù 19 · ojú. 368

يَأْتُوكَ بِكُلِّ سَحَّارٍ عَلِيمٍ37

(pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ."
26:38Júzù 19 · ojú. 368

فَجُمِعَ السَّحَرَةُ لِمِيقَاتِ يَوْمٍ مَعْلُومٍ38

Wọ́n sì kó àwọn òpìdán jọ ní àsìkò tí wọ́n fi àdéhùn sí ní ọjọ́ tí (gbogbo ìlú) ti mọ̀.
26:39Júzù 19 · ojú. 368

وَقِيلَ لِلنَّاسِ هَلْ أَنْتُمْ مُجْتَمِعُونَ39

Wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé: "Ṣé ẹ̀yin máa kó jọ (síbẹ̀) bí?
26:40Júzù 19 · ojú. 369

لَعَلَّنَا نَتَّبِعُ السَّحَرَةَ إِنْ كَانُوا هُمُ الْغَالِبِينَ40

Nítorí kí á lè tẹ̀lé àwọn òpìdán tí ó bá jẹ́ pé àwọn ni olùborí."
26:41Júzù 19 · ojú. 369

فَلَمَّا جَاءَ السَّحَرَةُ قَالُوا لِفِرْعَوْنَ أَئِنَّ لَنَا لَأَجْرًا إِنْ كُنَّا نَحْنُ الْغَالِبِينَ41

Nígbà tí àwọn òpìdán dé, wọ́n wí fún Fir‘aon pé: “Ǹjẹ́ owó-ọ̀yà kan wà fún wa, tí ó bá jẹ́ pé àwa gan-an la jẹ́ olùborí?”
26:42Júzù 19 · ojú. 369

قَالَ نَعَمْ وَإِنَّكُمْ إِذًا لَمِنَ الْمُقَرَّبِينَ42

(Fir‘aon) wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú nígbà náà ẹ máa wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”
26:43Júzù 19 · ojú. 369

قَالَ لَهُمْ مُوسَىٰ أَلْقُوا مَا أَنْتُمْ مُلْقُونَ43

(Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.”
26:44Júzù 19 · ojú. 369

فَأَلْقَوْا حِبَالَهُمْ وَعِصِيَّهُمْ وَقَالُوا بِعِزَّةِ فِرْعَوْنَ إِنَّا لَنَحْنُ الْغَالِبُونَ44

Wọ́n sì ju àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn sílẹ̀. Wọ́n wí pé: “Pẹ̀lú ògo Fir‘aon, dájúdájú àwa, àwa ni olùborí.”
26:45Júzù 19 · ojú. 369

فَأَلْقَىٰ مُوسَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ تَلْقَفُ مَا يَأْفِكُونَ45

Nígbà náà, (Ànábì) Mūsā ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ń gbé ohun tí wọ́n pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.
26:46Júzù 19 · ojú. 369

فَأُلْقِيَ السَّحَرَةُ سَاجِدِينَ46

Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
26:47Júzù 19 · ojú. 369

قَالُوا آمَنَّا بِرَبِّ الْعَالَمِينَ47

Wọ́n sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá,
26:48Júzù 19 · ojú. 369

رَبِّ مُوسَىٰ وَهَارُونَ48

Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn."
26:49Júzù 19 · ojú. 369

قَالَ آمَنْتُمْ لَهُ قَبْلَ أَنْ آذَنَ لَكُمْ ۖ إِنَّهُ لَكَبِيرُكُمُ الَّذِي عَلَّمَكُمُ السِّحْرَ فَلَسَوْفَ تَعْلَمُونَ ۚ لَأُقَطِّعَنَّ أَيْدِيَكُمْ وَأَرْجُلَكُمْ مِنْ خِلَافٍ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمْ أَجْمَعِينَ49

Fir‘aon wí pé: “Ẹ gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fun yín! Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Láìpẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ wá mọ̀. Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”
26:50Júzù 19 · ojú. 369

قَالُوا لَا ضَيْرَ ۖ إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا مُنْقَلِبُونَ50

(Àwọn òpìdán) sọ pé: “Kò sí ìnira fún wa! Dájúdájú àwa yó sì fàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wa.
26:51Júzù 19 · ojú. 369

إِنَّا نَطْمَعُ أَنْ يَغْفِرَ لَنَا رَبُّنَا خَطَايَانَا أَنْ كُنَّا أَوَّلَ الْمُؤْمِنِينَ51

Dájúdájú àwa n retí pé Olúwa wa yóò ṣe àforíjìn àwọn àṣìṣe wa fún wa nítorí pé àwa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo.”
____________________
Ìyẹn ni pé, wọ́n jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ t’ó gba Allāhu gbọ́ nínú ìjọ Fir‘aon. Kì í ṣe pé wọ́n jẹ́ ẹni àkọ́kọ t’ó gba Allāhu gbọ́ nínú àwọn ènìyàn. Ṣebí ìjọ-ìjọ onígbàgbọ́ òdodo ti ré kọjá ṣíwájú wọn.
26:52Júzù 19 · ojú. 369

۞ وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنْ أَسْرِ بِعِبَادِي إِنَّكُمْ مُتَّبَعُونَ52

A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru (nítorí pé) dájúdájú wọn yóò lépa yín.”
26:53Júzù 19 · ojú. 369

فَأَرْسَلَ فِرْعَوْنُ فِي الْمَدَائِنِ حَاشِرِينَ53

Fir‘aon sì rán àwọn akónijọ sínú àwọn ìlú (láti sọ pé):
26:54Júzù 19 · ojú. 369

إِنَّ هَٰؤُلَاءِ لَشِرْذِمَةٌ قَلِيلُونَ54

"Dájúdájú àwọn (ọmọ ’Isrọ̄’īl) wọ̀nyí, ìjọ péréte díẹ̀ ni wọ́n.
26:55Júzù 19 · ojú. 369

وَإِنَّهُمْ لَنَا لَغَائِظُونَ55

Àti pé dájúdájú wọ́n ti ṣe ohun t’ó ń bí wa nínú.
26:56Júzù 19 · ojú. 369

وَإِنَّا لَجَمِيعٌ حَاذِرُونَ56

Dájúdájú gbogbo wa ni kí á sì wà tìfura-tìfura."
26:57Júzù 19 · ojú. 369

فَأَخْرَجْنَاهُمْ مِنْ جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ57

Nítorí náà, A mú (ìjọ Fir‘aon) jáde kúrò nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi,
26:58Júzù 19 · ojú. 369

وَكُنُوزٍ وَمَقَامٍ كَرِيمٍ58

àti àwọn àpótí-ọrọ̀ àti ibùjókòó àpọ́nlé.
26:59Júzù 19 · ojú. 369

كَذَٰلِكَ وَأَوْرَثْنَاهَا بَنِي إِسْرَائِيلَ59

Báyẹn (lọ̀rọ̀ rí). A sì jogún rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.
26:60Júzù 19 · ojú. 369

فَأَتْبَعُوهُمْ مُشْرِقِينَ60

Wọ́n sì lépa wọn ní àsìkò tí òòrùn yọ.
26:61Júzù 19 · ojú. 370

فَلَمَّا تَرَاءَى الْجَمْعَانِ قَالَ أَصْحَابُ مُوسَىٰ إِنَّا لَمُدْرَكُونَ61

Nígbà tí ìjọ méjèèjì ríra wọn, àwọn ìjọ (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú wọn yóò lé wa bá.”
26:62Júzù 19 · ojú. 370

قَالَ كَلَّا ۖ إِنَّ مَعِيَ رَبِّي سَيَهْدِينِ62

(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Rárá, dájúdájú Olúwa mi ń bẹ pẹ̀lú mi. Ó sì máa fi ọ̀nà mọ̀ mí.”
26:63Júzù 19 · ojú. 370

فَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنِ اضْرِبْ بِعَصَاكَ الْبَحْرَ ۖ فَانْفَلَقَ فَكَانَ كُلُّ فِرْقٍ كَالطَّوْدِ الْعَظِيمِ63

A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun.” (Ó fi nà á). Ó sì pín (sí ọ̀nà méjìlá). Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá.
26:64Júzù 19 · ojú. 370

وَأَزْلَفْنَا ثَمَّ الْآخَرِينَ64

A sì mú ìjọ kejì (ìyẹn, ìjọ Fir‘aon) súnmọ́ ibẹ̀ yẹn.
26:65Júzù 19 · ojú. 370

وَأَنْجَيْنَا مُوسَىٰ وَمَنْ مَعَهُ أَجْمَعِينَ65

A gba (Ànábì) Mūsā àti gbogbo àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ là pátápátá.
26:66Júzù 19 · ojú. 370

ثُمَّ أَغْرَقْنَا الْآخَرِينَ66

Lẹ́yìn náà, A tẹ ìjọ kejì rì (sínú agbami).
26:67Júzù 19 · ojú. 370

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ67

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
26:68Júzù 19 · ojú. 370

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ68

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
26:69Júzù 19 · ojú. 370

وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ إِبْرَاهِيمَ69

Ka ìròyìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm fún wọn.
26:70Júzù 19 · ojú. 370

إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَا تَعْبُدُونَ70

Nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?”
26:71Júzù 19 · ojú. 370

قَالُوا نَعْبُدُ أَصْنَامًا فَنَظَلُّ لَهَا عَاكِفِينَ71

Wọ́n wí pé: “À ń jọ́sìn fún àwọn ère kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn.”
26:72Júzù 19 · ojú. 370

قَالَ هَلْ يَسْمَعُونَكُمْ إِذْ تَدْعُونَ72

(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Ǹjẹ́ wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá ń pè wọ́n?
26:73Júzù 19 · ojú. 370

أَوْ يَنْفَعُونَكُمْ أَوْ يَضُرُّونَ73

Tàbí (ṣé) wọ́n lè ṣe yín ní oore tàbí wọ́n lè fi ìnira kàn yín?”
26:74Júzù 19 · ojú. 370

قَالُوا بَلْ وَجَدْنَا آبَاءَنَا كَذَٰلِكَ يَفْعَلُونَ74

Wọ́n wí pé: “Rárá o! A bá àwọn bàbá wa, tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni”
26:75Júzù 19 · ojú. 370

قَالَ أَفَرَأَيْتُمْ مَا كُنْتُمْ تَعْبُدُونَ75

(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún,
26:76Júzù 19 · ojú. 370

أَنْتُمْ وَآبَاؤُكُمُ الْأَقْدَمُونَ76

ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ìṣaájú?
26:77Júzù 19 · ojú. 370

فَإِنَّهُمْ عَدُوٌّ لِي إِلَّا رَبَّ الْعَالَمِينَ77

Dájúdájú àwọn ni ọ̀tá fún mi àyàfi Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
26:78Júzù 19 · ojú. 370

الَّذِي خَلَقَنِي فَهُوَ يَهْدِينِ78

(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí;
26:79Júzù 19 · ojú. 370

وَالَّذِي هُوَ يُطْعِمُنِي وَيَسْقِينِ79

Ẹni t’Ó ń fún mi ní jíjẹ, t’Ó ń fún mi ní mímu;

وَإِذَا مَرِضْتُ فَهُوَ يَشْفِينِ80

Àti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn;
26:81Júzù 19 · ojú. 370

وَالَّذِي يُمِيتُنِي ثُمَّ يُحْيِينِ81

Ẹni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè;
26:82Júzù 19 · ojú. 370

وَالَّذِي أَطْمَعُ أَنْ يَغْفِرَ لِي خَطِيئَتِي يَوْمَ الدِّينِ82

Ẹni tí mo ní ìrètí sí pé Ó máa forí àwọn àṣìṣe mi jìn mí ní Ọjọ́ Ẹ̀san.
26:83Júzù 19 · ojú. 370

رَبِّ هَبْ لِي حُكْمًا وَأَلْحِقْنِي بِالصَّالِحِينَ83

Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ ipò Ànábì. Dà mí pọ̀ mọ́ àwọn ẹni rere.
26:84Júzù 19 · ojú. 371

وَاجْعَلْ لِي لِسَانَ صِدْقٍ فِي الْآخِرِينَ84

Jẹ́ kí àwọn t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn (mi) máa sọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú dáadáa.
26:85Júzù 19 · ojú. 371

وَاجْعَلْنِي مِنْ وَرَثَةِ جَنَّةِ النَّعِيمِ85

Ṣe mí ní ọ̀kan nínú àwọn olùjogún Ọgbà Ìdẹ̀ra.
26:86Júzù 19 · ojú. 371

وَاغْفِرْ لِأَبِي إِنَّهُ كَانَ مِنَ الضَّالِّينَ86

Kí O sì foríjin bàbá mi. Dájúdájú ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣìnà.
26:87Júzù 19 · ojú. 371

وَلَا تُخْزِنِي يَوْمَ يُبْعَثُونَ87

Má ṣe dójú tì mí ní ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.
26:88Júzù 19 · ojú. 371

يَوْمَ لَا يَنْفَعُ مَالٌ وَلَا بَنُونَ88

Ọjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní.
26:89Júzù 19 · ojú. 371

إِلَّا مَنْ أَتَى اللَّهَ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ89

Àyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ọkàn mímọ́."
____________________
Ọkàn mímọ́ ni ọkàn tí ó là kúrò nínú ẹbọ ṣíṣe, àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ẹ̀sìn.
26:90Júzù 19 · ojú. 371

وَأُزْلِفَتِ الْجَنَّةُ لِلْمُتَّقِينَ90

A máa mú Ọgbà Ìdẹ̀ra súnmọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
26:91Júzù 19 · ojú. 371

وَبُرِّزَتِ الْجَحِيمُ لِلْغَاوِينَ91

Wọ́n sì máa fi iná Jẹhīm han àwọn olùṣìnà,
26:92Júzù 19 · ojú. 371

وَقِيلَ لَهُمْ أَيْنَ مَا كُنْتُمْ تَعْبُدُونَ92

wọn yó sì sọ fún wọn pé: “Níbo ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún wà?”
26:93Júzù 19 · ojú. 371

مِنْ دُونِ اللَّهِ هَلْ يَنْصُرُونَكُمْ أَوْ يَنْتَصِرُونَ93

(N̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu, ṣé wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ tàbí ṣé wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́?
26:94Júzù 19 · ojú. 371

فَكُبْكِبُوا فِيهَا هُمْ وَالْغَاوُونَ94

Wọ́n sì máa taari gbogbo wọn sínú Iná; àwọn àti èṣù wọn,
26:95Júzù 19 · ojú. 371

وَجُنُودُ إِبْلِيسَ أَجْمَعُونَ95

àti àwọn ọmọ ogun ’Iblīs pátápátá.
26:96Júzù 19 · ojú. 371

قَالُوا وَهُمْ فِيهَا يَخْتَصِمُونَ96

(Àwọn aláìgbàgbọ́), nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn jiyàn nínú Iná, wọ́n á wí pé:
26:97Júzù 19 · ojú. 371

تَاللَّهِ إِنْ كُنَّا لَفِي ضَلَالٍ مُبِينٍ97

"A fi Allāhu búra, dájúdájú àwa kúkú ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
26:98Júzù 19 · ojú. 371

إِذْ نُسَوِّيكُمْ بِرَبِّ الْعَالَمِينَ98

nígbà tí a fi yín ṣe akẹgbẹ́ fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
26:99Júzù 19 · ojú. 371

وَمَا أَضَلَّنَا إِلَّا الْمُجْرِمُونَ99

Kò sí ohun tí ó ṣì wá lọ́nà bí kò ṣe àwọn (èṣù) ẹlẹ́ṣẹ̀.
26:100Júzù 19 · ojú. 371

فَمَا لَنَا مِنْ شَافِعِينَ100

Kò sì sí àwọn olùṣìpẹ̀ kan fún wa.
26:101Júzù 19 · ojú. 371

وَلَا صَدِيقٍ حَمِيمٍ101

Kò tún sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan (fún wa.)
26:102Júzù 19 · ojú. 371

فَلَوْ أَنَّ لَنَا كَرَّةً فَنَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ102

Tí ó bá jẹ́ pé ìpadà sí ilé ayé wà fún wa ni, nígbà náà àwa ìbá wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo."
26:103Júzù 19 · ojú. 371

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ103

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
26:104Júzù 19 · ojú. 371

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ104

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
26:105Júzù 19 · ojú. 371

كَذَّبَتْ قَوْمُ نُوحٍ الْمُرْسَلِينَ105

Ìjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
26:106Júzù 19 · ojú. 371

إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ نُوحٌ أَلَا تَتَّقُونَ106

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Nūh, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
26:107Júzù 19 · ojú. 371

إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ107

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
26:108Júzù 19 · ojú. 371

فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ108

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
26:109Júzù 19 · ojú. 371

وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ109

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
26:110Júzù 19 · ojú. 371

فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ110

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.”
26:111Júzù 19 · ojú. 371

۞ قَالُوا أَنُؤْمِنُ لَكَ وَاتَّبَعَكَ الْأَرْذَلُونَ111

Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gbà ọ́ gbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ l’ó ń tẹ̀lé ọ!?”
26:112Júzù 19 · ojú. 372

قَالَ وَمَا عِلْمِي بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ112

Ó sọ pé: “Èmi kò nímọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe (lẹ́yìn mi).
26:113Júzù 19 · ojú. 372

إِنْ حِسَابُهُمْ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّي ۖ لَوْ تَشْعُرُونَ113

Kò sí ìṣírò-iṣẹ́ wọn lọ́dọ̀ ẹnì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Olúwa mi, tí ó bá jẹ́ pé ẹ bá fura.
26:114Júzù 19 · ojú. 372

وَمَا أَنَا بِطَارِدِ الْمُؤْمِنِينَ114

Èmi kò sì níí lé àwọn onígbàgbọ́ òdodo dànù.
26:115Júzù 19 · ojú. 372

إِنْ أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ مُبِينٌ115

Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
26:116Júzù 19 · ojú. 372

قَالُوا لَئِنْ لَمْ تَنْتَهِ يَا نُوحُ لَتَكُونَنَّ مِنَ الْمَرْجُومِينَ116

Wọ́n wí pé: “Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò.”
26:117Júzù 19 · ojú. 372

قَالَ رَبِّ إِنَّ قَوْمِي كَذَّبُونِ117

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́.
26:118Júzù 19 · ojú. 372

فَافْتَحْ بَيْنِي وَبَيْنَهُمْ فَتْحًا وَنَجِّنِي وَمَنْ مَعِيَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ118

Nítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
26:119Júzù 19 · ojú. 372

فَأَنْجَيْنَاهُ وَمَنْ مَعَهُ فِي الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ119

A la òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́.
26:120Júzù 19 · ojú. 372

ثُمَّ أَغْرَقْنَا بَعْدُ الْبَاقِينَ120

Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn t’ó ṣẹ́kù rì sínú omi.
26:121Júzù 19 · ojú. 372

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ121

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
26:122Júzù 19 · ojú. 372

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ122

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
26:123Júzù 19 · ojú. 372

كَذَّبَتْ عَادٌ الْمُرْسَلِينَ123

Àwọn ìran ‘Ād pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
26:124Júzù 19 · ojú. 372

إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ هُودٌ أَلَا تَتَّقُونَ124

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
26:125Júzù 19 · ojú. 372

إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ125

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
26:126Júzù 19 · ojú. 372

فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ126

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
26:127Júzù 19 · ojú. 372

وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ127

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
26:128Júzù 19 · ojú. 372

أَتَبْنُونَ بِكُلِّ رِيعٍ آيَةً تَعْبَثُونَ128

Ṣé ẹ óò máa kọ́ ilé ńlá ńlá sí àwọn àyè gíga (kí ẹ lè) máa fi àwọn olùrékọjá ṣẹ̀fẹ̀?
26:129Júzù 19 · ojú. 372

وَتَتَّخِذُونَ مَصَانِعَ لَعَلَّكُمْ تَخْلُدُونَ129

Ẹ sì ń kọ́ àwọn ilé ńlá ńlá bí ẹni pé ẹ máa ṣe gbére (nílé ayé yìí).
26:130Júzù 19 · ojú. 372

وَإِذَا بَطَشْتُمْ بَطَشْتُمْ جَبَّارِينَ130

Nígbà tí ẹ bá sì gbá (ènìyàn mú láti fìyà jẹ wọ́n), ẹ̀ ń gbá wọn mú ní ìgbámú aláìlójú-àánú.
26:131Júzù 19 · ojú. 372

فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ131

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
26:132Júzù 19 · ojú. 372

وَاتَّقُوا الَّذِي أَمَدَّكُمْ بِمَا تَعْلَمُونَ132

Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí ẹ mọ̀;
26:133Júzù 19 · ojú. 372

أَمَدَّكُمْ بِأَنْعَامٍ وَبَنِينَ133

Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn ọmọ,
26:134Júzù 19 · ojú. 372

وَجَنَّاتٍ وَعُيُونٍ134

àti àwọn ọgbà oko pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú omi.
26:135Júzù 19 · ojú. 372

إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ135

Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá fun yín.”
26:136Júzù 19 · ojú. 372

قَالُوا سَوَاءٌ عَلَيْنَا أَوَعَظْتَ أَمْ لَمْ تَكُنْ مِنَ الْوَاعِظِينَ136

Wọ́n wí pé: “Bákan náà ni fún wa; yálà o kìlọ̀ fún wa tàbí o ò sí nínú àwọn olùkìlọ̀.
26:137Júzù 19 · ojú. 373

إِنْ هَٰذَا إِلَّا خُلُقُ الْأَوَّلِينَ137

Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìwà àwọn ẹni àkọ́kọ́.
26:138Júzù 19 · ojú. 373

وَمَا نَحْنُ بِمُعَذَّبِينَ138

Wọn kò sì níí jẹ wá níyà.”
26:139Júzù 19 · ojú. 373

فَكَذَّبُوهُ فَأَهْلَكْنَاهُمْ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ139

Nítorí náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. A sì pa wọ́n run. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
26:140Júzù 19 · ojú. 373

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ140

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
26:141Júzù 19 · ojú. 373

كَذَّبَتْ ثَمُودُ الْمُرْسَلِينَ141

Àwọn ìran Thamūd pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
26:142Júzù 19 · ojú. 373

إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ صَالِحٌ أَلَا تَتَّقُونَ142

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
26:143Júzù 19 · ojú. 373

إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ143

Dájúdájú emi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
26:144Júzù 19 · ojú. 373

فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ144

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
26:145Júzù 19 · ojú. 373

وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ145

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
26:146Júzù 19 · ojú. 373

أَتُتْرَكُونَ فِي مَا هَاهُنَا آمِنِينَ146

Ṣé kí wọ́n fi yín sílẹ̀ síbi n̄ǹkan tí ó wà (nílé ayé) níbí yìí (nínú ìgbádùn ayé, kí ẹ jẹ́) olùfọkànbalẹ̀
26:147Júzù 19 · ojú. 373

فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ147

nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi.
26:148Júzù 19 · ojú. 373

وَزُرُوعٍ وَنَخْلٍ طَلْعُهَا هَضِيمٌ148

àti oko irúgbìn pẹ̀lú igi dàbínù tí ọ̀gọ́mọ̀ rẹ̀ tutù?
26:149Júzù 19 · ojú. 373

وَتَنْحِتُونَ مِنَ الْجِبَالِ بُيُوتًا فَارِهِينَ149

Ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àwọn àpáta (gẹ́gẹ́ bí) akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́!
26:150Júzù 19 · ojú. 373

فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ150

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
26:151Júzù 19 · ojú. 373

وَلَا تُطِيعُوا أَمْرَ الْمُسْرِفِينَ151

Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àṣẹ àwọn aláṣejù,
26:152Júzù 19 · ojú. 373

الَّذِينَ يُفْسِدُونَ فِي الْأَرْضِ وَلَا يُصْلِحُونَ152

àwọn t’ó ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere.”
26:153Júzù 19 · ojú. 373

قَالُوا إِنَّمَا أَنْتَ مِنَ الْمُسَحَّرِينَ153

Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.
26:154Júzù 19 · ojú. 373

مَا أَنْتَ إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُنَا فَأْتِ بِآيَةٍ إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ154

Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Nítorí náà, mú àmì kan wá tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
26:155Júzù 19 · ojú. 373

قَالَ هَٰذِهِ نَاقَةٌ لَهَا شِرْبٌ وَلَكُمْ شِرْبُ يَوْمٍ مَعْلُومٍ155

Ó sọ pé: “Èyí ni abo ràkúnmí kan. Omi wà fún òhun, omi sì wà fún ẹ̀yin náà ní ọjọ́ tí a ti mọ̀.
26:156Júzù 19 · ojú. 373

وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابُ يَوْمٍ عَظِيمٍ156

Ẹ má ṣe fi aburú kan kàn án nítorí kí ìyà ọjọ́ ńlá má baà jẹ yín.”
26:157Júzù 19 · ojú. 373

فَعَقَرُوهَا فَأَصْبَحُوا نَادِمِينَ157

Wọ́n sì gún un pa. Nítorí náà, wọ́n sì di alábàámọ̀.
26:158Júzù 19 · ojú. 373

فَأَخَذَهُمُ الْعَذَابُ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ158

Ìyà náà jẹ wọ́n. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
26:159Júzù 19 · ojú. 373

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ159

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
26:160Júzù 19 · ojú. 374

كَذَّبَتْ قَوْمُ لُوطٍ الْمُرْسَلِينَ160

Ìjọ Lūt pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
26:161Júzù 19 · ojú. 374

إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ لُوطٌ أَلَا تَتَّقُونَ161

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Lūt, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
26:162Júzù 19 · ojú. 374

إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ162

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
26:163Júzù 19 · ojú. 374

فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ163

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
26:164Júzù 19 · ojú. 374

وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ164

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
26:165Júzù 19 · ojú. 374

أَتَأْتُونَ الذُّكْرَانَ مِنَ الْعَالَمِينَ165

Ṣé àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀dá ni ẹ̀yin ọkùnrin yóò lọ máa bá (fún adùn ìbálòpọ̀)?
26:166Júzù 19 · ojú. 374

وَتَذَرُونَ مَا خَلَقَ لَكُمْ رَبُّكُمْ مِنْ أَزْوَاجِكُمْ ۚ بَلْ أَنْتُمْ قَوْمٌ عَادُونَ166

Ẹ sì ń pa ohun tí Olúwa yín dá fun yín tì nínú àwọn ìyàwó yín! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni ẹ̀yin.”
26:167Júzù 19 · ojú. 374

قَالُوا لَئِنْ لَمْ تَنْتَهِ يَا لُوطُ لَتَكُونَنَّ مِنَ الْمُخْرَجِينَ167

Wọ́n wí pé: “Tí ìwọ Lūt kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa lé jáde kúrò nínú ìlú.”
26:168Júzù 19 · ojú. 374

قَالَ إِنِّي لِعَمَلِكُمْ مِنَ الْقَالِينَ168

Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùbínú sí iṣẹ́ (aburú) ọwọ́ yín.
26:169Júzù 19 · ojú. 374

رَبِّ نَجِّنِي وَأَهْلِي مِمَّا يَعْمَلُونَ169

Olúwa mi, la èmi àti àwọn ènìyàn mi níbí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (aburú)."
26:170Júzù 19 · ojú. 374

فَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ أَجْمَعِينَ170

Nítorí náà, A la òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pátápátá.
26:171Júzù 19 · ojú. 374

إِلَّا عَجُوزًا فِي الْغَابِرِينَ171

Àfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).
____________________
Arúgbóbìnrin yẹn ni ìyàwó Ànábì Lūt ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé, nínú sūrah Hūd; 11:81, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lo “àyàfi ìyàwó rẹ”.
26:172Júzù 19 · ojú. 374

ثُمَّ دَمَّرْنَا الْآخَرِينَ172

Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.
26:173Júzù 19 · ojú. 374

وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِمْ مَطَرًا ۖ فَسَاءَ مَطَرُ الْمُنْذَرِينَ173

A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú.
26:174Júzù 19 · ojú. 374

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ174

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
26:175Júzù 19 · ojú. 374

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ175

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
26:176Júzù 19 · ojú. 374

كَذَّبَ أَصْحَابُ الْأَيْكَةِ الْمُرْسَلِينَ176

Àwọn ará ’Aekah pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
26:177Júzù 19 · ojú. 374

إِذْ قَالَ لَهُمْ شُعَيْبٌ أَلَا تَتَّقُونَ177

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb, sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
26:178Júzù 19 · ojú. 374

إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ178

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
26:179Júzù 19 · ojú. 374

فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ179

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
26:180Júzù 19 · ojú. 374

وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ180

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
26:181Júzù 19 · ojú. 374

۞ أَوْفُوا الْكَيْلَ وَلَا تَكُونُوا مِنَ الْمُخْسِرِينَ181

Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún. Kí ẹ sì má ṣe wà nínú àwọn olùdóṣùwọ̀nkù.
26:182Júzù 19 · ojú. 374

وَزِنُوا بِالْقِسْطَاسِ الْمُسْتَقِيمِ182

Ẹ fi ìwọ̀n t’ó tọ́ wọn n̄ǹkan.
26:183Júzù 19 · ojú. 374

وَلَا تَبْخَسُوا النَّاسَ أَشْيَاءَهُمْ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ183

Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣe hùwà aburú lórí ilẹ̀ ní ti òbìlẹ̀jẹ́.
26:184Júzù 19 · ojú. 375

وَاتَّقُوا الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالْجِبِلَّةَ الْأَوَّلِينَ184

Kí ẹ sì bẹ̀rù Ẹni tí Ó dá yín àti àwọn ìran àkọ́kọ́.”
26:185Júzù 19 · ojú. 375

قَالُوا إِنَّمَا أَنْتَ مِنَ الْمُسَحَّرِينَ185

Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.
26:186Júzù 19 · ojú. 375

وَمَا أَنْتَ إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُنَا وَإِنْ نَظُنُّكَ لَمِنَ الْكَاذِبِينَ186

Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àti pé a ò rò ọ́ sí kiní kan bí kò ṣe pé ó wà nínú àwọn òpùrọ́.
26:187Júzù 19 · ojú. 375

فَأَسْقِطْ عَلَيْنَا كِسَفًا مِنَ السَّمَاءِ إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ187

Nítorí náà, jẹ́ kí apá kan nínú sánmọ̀ ya lù wá mọ́lẹ̀, tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
26:188Júzù 19 · ojú. 375

قَالَ رَبِّي أَعْلَمُ بِمَا تَعْمَلُونَ188

Ó sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
26:189Júzù 19 · ojú. 375

فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمْ عَذَابُ يَوْمِ الظُّلَّةِ ۚ إِنَّهُ كَانَ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ189

Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà ọjọ́ ẹ̀ṣújò sì jẹ wọ́n. Dájúdájú ó jẹ́ ìyà ọjọ́ ńlá.
26:190Júzù 19 · ojú. 375

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ190

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
26:191Júzù 19 · ojú. 375

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ191

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
26:192Júzù 19 · ojú. 375

وَإِنَّهُ لَتَنْزِيلُ رَبِّ الْعَالَمِينَ192

Dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
26:193Júzù 19 · ojú. 375

نَزَلَ بِهِ الرُّوحُ الْأَمِينُ193

Mọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀
26:194Júzù 19 · ojú. 375

عَلَىٰ قَلْبِكَ لِتَكُونَ مِنَ الْمُنْذِرِينَ194

sínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀
26:195Júzù 19 · ojú. 375

بِلِسَانٍ عَرَبِيٍّ مُبِينٍ195

pẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé.
26:196Júzù 19 · ojú. 375

وَإِنَّهُ لَفِي زُبُرِ الْأَوَّلِينَ196

Dájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) ti wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́.
26:197Júzù 19 · ojú. 375

أَوَلَمْ يَكُنْ لَهُمْ آيَةً أَنْ يَعْلَمَهُ عُلَمَاءُ بَنِي إِسْرَائِيلَ197

Ṣé kò jẹ́ àmì kan fún wọn pé àwọn onímọ̀ (nínú) àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nímọ̀ (sí àsọọ́lẹ̀ nípa) rẹ̀ (nínú tírà ọwọ́ wọn)?
26:198Júzù 19 · ojú. 375

وَلَوْ نَزَّلْنَاهُ عَلَىٰ بَعْضِ الْأَعْجَمِينَ198

Tí ó bá jẹ́ pé A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún apá kan àwọn elédè mìíràn ni,
26:199Júzù 19 · ojú. 375

فَقَرَأَهُ عَلَيْهِمْ مَا كَانُوا بِهِ مُؤْمِنِينَ199

199. tí ó sì ké e fún wọn, wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo.
26:200Júzù 19 · ojú. 375

كَذَٰلِكَ سَلَكْنَاهُ فِي قُلُوبِ الْمُجْرِمِينَ200

Báyẹn ni A ṣe mú (àtakò) wọ inú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
26:201Júzù 19 · ojú. 375

لَا يُؤْمِنُونَ بِهِ حَتَّىٰ يَرَوُا الْعَذَابَ الْأَلِيمَ201

Wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
26:202Júzù 19 · ojú. 375

فَيَأْتِيَهُمْ بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ202

(Ìyà náà) yóò dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura.
26:203Júzù 19 · ojú. 375

فَيَقُولُوا هَلْ نَحْنُ مُنْظَرُونَ203

Nígbà náà ni wọn yóò wí pé: "Ǹjẹ́ wọ́n lè lọ́ wa lára bí?"
26:204Júzù 19 · ojú. 375

أَفَبِعَذَابِنَا يَسْتَعْجِلُونَ204

Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?
26:205Júzù 19 · ojú. 375

أَفَرَأَيْتَ إِنْ مَتَّعْنَاهُمْ سِنِينَ205

Sọ fún Mi tí A bá fún wọn ní ìgbádùn ayé fún ọdún gbọọrọ!
26:206Júzù 19 · ojú. 375

ثُمَّ جَاءَهُمْ مَا كَانُوا يُوعَدُونَ206

Lẹ́yìn náà, kí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn dé bá wọn.
26:207Júzù 19 · ojú. 376

مَا أَغْنَىٰ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يُمَتَّعُونَ207

Ohun tí A ṣe ní ìgbádùn fún wọn kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
26:208Júzù 19 · ojú. 376

وَمَا أَهْلَكْنَا مِنْ قَرْيَةٍ إِلَّا لَهَا مُنْذِرُونَ208

A ò sì pa ìlú kan run àfi kí wọ́n ti ní àwọn olùkìlọ̀.
26:209Júzù 19 · ojú. 376

ذِكْرَىٰ وَمَا كُنَّا ظَالِمِينَ209

Ìrántí (dé fún wọn sẹ́). Àti pé Àwa kì í ṣe alábòsí.
26:210Júzù 19 · ojú. 376

وَمَا تَنَزَّلَتْ بِهِ الشَّيَاطِينُ210

Kì í ṣe àwọn èṣù ni wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀.
26:211Júzù 19 · ojú. 376

وَمَا يَنْبَغِي لَهُمْ وَمَا يَسْتَطِيعُونَ211

Kò yẹ fún wọn. Wọn kò sì lágbára rẹ̀.
26:212Júzù 19 · ojú. 376

إِنَّهُمْ عَنِ السَّمْعِ لَمَعْزُولُونَ212

Dájúdájú A ti mú wọn takété sí gbígbọ́ rẹ̀ (láti ojú sánmọ̀).
26:213Júzù 19 · ojú. 376

فَلَا تَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ فَتَكُونَ مِنَ الْمُعَذَّبِينَ213

Nítorí náà, má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, nítorí kí ìwọ má baà wà nínú àwọn tí A máa jẹ níyà.
26:214Júzù 19 · ojú. 376

وَأَنْذِرْ عَشِيرَتَكَ الْأَقْرَبِينَ214

Kí o sì kìlọ̀ fún àwọn ẹbí rẹ, t’ó súnmọ́ jùlọ.
26:215Júzù 19 · ojú. 376

وَاخْفِضْ جَنَاحَكَ لِمَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ215

Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn t’ó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
26:216Júzù 19 · ojú. 376

فَإِنْ عَصَوْكَ فَقُلْ إِنِّي بَرِيءٌ مِمَّا تَعْمَلُونَ216

Tí wọ́n bá sì yapa (àṣẹ) rẹ, sọ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe (níṣẹ́ aburú).”
26:217Júzù 19 · ojú. 376

وَتَوَكَّلْ عَلَى الْعَزِيزِ الرَّحِيمِ217

Kí o sì gbáralé Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run;
26:218Júzù 19 · ojú. 376

الَّذِي يَرَاكَ حِينَ تَقُومُ218

Ẹni t’Ó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)
26:219Júzù 19 · ojú. 376

وَتَقَلُّبَكَ فِي السَّاجِدِينَ219

àti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀.
26:220Júzù 19 · ojú. 376

إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ220

Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
26:221Júzù 19 · ojú. 376

هَلْ أُنَبِّئُكُمْ عَلَىٰ مَنْ تَنَزَّلُ الشَّيَاطِينُ221

Ṣé kí n̄g sọ ẹni tí àwọn èṣù ń sọ̀kalẹ̀ wá bá?
26:222Júzù 19 · ojú. 376

تَنَزَّلُ عَلَىٰ كُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٍ222

Wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá gbogbo àwọn òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
26:223Júzù 19 · ojú. 376

يُلْقُونَ السَّمْعَ وَأَكْثَرُهُمْ كَاذِبُونَ223

(Àwọn èṣù) ń dẹtí (sí ìró sánmọ̀). Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òpùrọ́.
26:224Júzù 19 · ojú. 376

وَالشُّعَرَاءُ يَتَّبِعُهُمُ الْغَاوُونَ224

Àwọn eléwì, àwọn olùṣìnà l’ó ń tẹ̀lé wọn.
26:225Júzù 19 · ojú. 376

أَلَمْ تَرَ أَنَّهُمْ فِي كُلِّ وَادٍ يَهِيمُونَ225

Ṣé o ò rí i pé gbogbo ọ̀gbun ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń tẹnu bọ̀ ni?
26:226Júzù 19 · ojú. 376

وَأَنَّهُمْ يَقُولُونَ مَا لَا يَفْعَلُونَ226

Àti pé dájúdájú wọ́n ń sọ ohun tí wọn kò níí ṣe.
26:227Júzù 19 · ojú. 376

إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَذَكَرُوا اللَّهَ كَثِيرًا وَانْتَصَرُوا مِنْ بَعْدِ مَا ظُلِمُوا ۗ وَسَيَعْلَمُ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَيَّ مُنْقَلَبٍ يَنْقَلِبُونَ227

Àfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, tí wọ́n rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀, tí wọ́n sì jàjà gbara lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàbòsí sí wọn. Àwọn t’ó ṣàbòsí sì máa mọ irú ìkángun tí wọ́n máa gúnlẹ̀ sí.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà