Nuh

سورة نوح

Súrà 71 · Mákí · 28 àwọn ẹsẹ

71:1Júzù 29 · ojú. 570

إِنَّا أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ أَنْ أَنْذِرْ قَوْمَكَ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ1

Dájúdájú Àwa rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣèkìlọ̀ fún ìjọ rẹ ṣíwájú kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro tó dé bá wọn."
71:2Júzù 29 · ojú. 570

قَالَ يَا قَوْمِ إِنِّي لَكُمْ نَذِيرٌ مُبِينٌ2

Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín
71:3Júzù 29 · ojú. 570

أَنِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَاتَّقُوهُ وَأَطِيعُونِ3

pé kí ẹ jọ́sìn fún Allāhu, kí ẹ bẹ̀rù Rẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
71:4Júzù 29 · ojú. 570

يَغْفِرْ لَكُمْ مِنْ ذُنُوبِكُمْ وَيُؤَخِّرْكُمْ إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى ۚ إِنَّ أَجَلَ اللَّهِ إِذَا جَاءَ لَا يُؤَخَّرُ ۖ لَوْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ4

(Allāhu) máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fun yín. Ó sì máa lọ yín lára títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àkókò (ikú tí) Allāhu (kọ mọ́ ẹ̀dá), nígbà tí ó bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀."
71:5Júzù 29 · ojú. 570

قَالَ رَبِّ إِنِّي دَعَوْتُ قَوْمِي لَيْلًا وَنَهَارًا5

Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi pe ìjọ mi ní òru àti ní ọ̀sán.
71:6Júzù 29 · ojú. 570

فَلَمْ يَزِدْهُمْ دُعَائِي إِلَّا فِرَارًا6

Ìpè mi kò sì ṣe àlékún kan fún wọn àyàfi sísá sẹ́yìn (fún òdodo).
71:7Júzù 29 · ojú. 570

وَإِنِّي كُلَّمَا دَعَوْتُهُمْ لِتَغْفِرَ لَهُمْ جَعَلُوا أَصَابِعَهُمْ فِي آذَانِهِمْ وَاسْتَغْشَوْا ثِيَابَهُمْ وَأَصَرُّوا وَاسْتَكْبَرُوا اسْتِكْبَارًا7

Àti pé ìgbàkígbà tí mo bá pè wọ́n pé kí O lè foríjìn wọ́n, wọ́n ń fi ọmọníka wọn dí etí wọn, wọ́n ń yíṣọ wọn borí, wọ́n ń takú (sórí ẹ̀ṣẹ̀), wọ́n sì ń ṣègbéraga gan-an.
71:8Júzù 29 · ojú. 570

ثُمَّ إِنِّي دَعَوْتُهُمْ جِهَارًا8

Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi pè wọ́n pẹ̀lú ohùn òkè.
71:9Júzù 29 · ojú. 570

ثُمَّ إِنِّي أَعْلَنْتُ لَهُمْ وَأَسْرَرْتُ لَهُمْ إِسْرَارًا9

Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi kéde fún wọn, mo sì tún pè wọ́n ní ìdá kọ́ńkọ́.
71:10Júzù 29 · ojú. 570

فَقُلْتُ اسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ إِنَّهُ كَانَ غَفَّارًا10

Mo sì sọ pé, ẹ tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín, dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn.
71:11Júzù 29 · ojú. 571

يُرْسِلِ السَّمَاءَ عَلَيْكُمْ مِدْرَارًا11

Ó máa rọ̀jò fun yín ní òjò púpọ̀,
71:12Júzù 29 · ojú. 571

وَيُمْدِدْكُمْ بِأَمْوَالٍ وَبَنِينَ وَيَجْعَلْ لَكُمْ جَنَّاتٍ وَيَجْعَلْ لَكُمْ أَنْهَارًا12

Ó máa fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin ràn yín lọ́wọ́. Ó máa ṣe àwọn ọgbà oko fun yín. Ó sì máa ṣe àwọn odò fun yín.
71:13Júzù 29 · ojú. 571

مَا لَكُمْ لَا تَرْجُونَ لِلَّهِ وَقَارًا13

Kí ló mu yín tí ẹ kò páyà títóbi Allāhu?
71:14Júzù 29 · ojú. 571

وَقَدْ خَلَقَكُمْ أَطْوَارًا14

Ó sì kúkú ṣẹ̀dá yín láti ìrísí kan sí òmíràn (nínú oyún).
____________________
Ìyẹn ni pé, láti ìrísí àtọ̀ sí ìrísí ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà sí bááṣí ẹran.
71:15Júzù 29 · ojú. 571

أَلَمْ تَرَوْا كَيْفَ خَلَقَ اللَّهُ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ طِبَاقًا15

Ṣé ẹ ò rí bí Allāhu ṣe dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele ni?
71:16Júzù 29 · ojú. 571

وَجَعَلَ الْقَمَرَ فِيهِنَّ نُورًا وَجَعَلَ الشَّمْسَ سِرَاجًا16

Ó sì ṣe òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú wọn. Ó tún ṣe òòrùn ní àtùpà.
71:17Júzù 29 · ojú. 571

وَاللَّهُ أَنْبَتَكُمْ مِنَ الْأَرْضِ نَبَاتًا17

Allāhu mu yín jáde láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀.
71:18Júzù 29 · ojú. 571

ثُمَّ يُعِيدُكُمْ فِيهَا وَيُخْرِجُكُمْ إِخْرَاجًا18

Lẹ́yìn náà, Ó máa da yín padà sínú rẹ̀. Ó sì máa mu yín jáde tààrà.
71:19Júzù 29 · ojú. 571

وَاللَّهُ جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ بِسَاطًا19

Allāhu ṣe ilẹ̀ fun yín ní ìtẹ́
71:20Júzù 29 · ojú. 571

لِتَسْلُكُوا مِنْهَا سُبُلًا فِجَاجًا20

nítorí kí ẹ lè tọ àwọn ojú ọ̀nà fífẹ̀ gbẹ̀gẹ̀dẹ̀ lórí rẹ̀."
71:21Júzù 29 · ojú. 571

قَالَ نُوحٌ رَبِّ إِنَّهُمْ عَصَوْنِي وَاتَّبَعُوا مَنْ لَمْ يَزِدْهُ مَالُهُ وَوَلَدُهُ إِلَّا خَسَارًا21

(Ànábì) Nūh sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú wọ́n yapa mi. Wọ́n sì tẹ̀lé ẹni tí dúkìá rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún bí kò ṣe òfò.
71:22Júzù 29 · ojú. 571

وَمَكَرُوا مَكْرًا كُبَّارًا22

Wọ́n sì déte ní ète t’ó tóbi."
71:23Júzù 29 · ojú. 571

وَقَالُوا لَا تَذَرُنَّ آلِهَتَكُمْ وَلَا تَذَرُنَّ وَدًّا وَلَا سُوَاعًا وَلَا يَغُوثَ وَيَعُوقَ وَنَسْرًا23

Wọ́n sì wí pé: "Ẹ má ṣe fi àwọn òrìṣà yín sílẹ̀. Ẹ má ṣe fi òrìṣà Wadd, Suwā‘u, Yẹgūth, Yẹ‘ūƙ àti Nasr sílẹ̀."
71:24Júzù 29 · ojú. 571

وَقَدْ أَضَلُّوا كَثِيرًا ۖ وَلَا تَزِدِ الظَّالِمِينَ إِلَّا ضَلَالًا24

Dájúdájú wọ́n ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ṣìnà. (Olúwa mi) má ṣe jẹ́ kí àwọn alábòsí lékún ní kiní kan bí kò ṣe ìṣìnà.
71:25Júzù 29 · ojú. 571

مِمَّا خَطِيئَاتِهِمْ أُغْرِقُوا فَأُدْخِلُوا نَارًا فَلَمْ يَجِدُوا لَهُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ أَنْصَارًا25

Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Wọ́n sì máa fi wọ́n sínú Iná. Wọn kò sì níí rí àwọn alárànṣe fún wọn lẹ́yìn Allāhu.
71:26Júzù 29 · ojú. 571

وَقَالَ نُوحٌ رَبِّ لَا تَذَرْ عَلَى الْأَرْضِ مِنَ الْكَافِرِينَ دَيَّارًا26

(Ànábì) Nūh tún sọ pé: "Olúwa mi, má ṣe fi ẹnì kan kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́ sílẹ̀ lórí ilẹ̀.
71:27Júzù 29 · ojú. 571

إِنَّكَ إِنْ تَذَرْهُمْ يُضِلُّوا عِبَادَكَ وَلَا يَلِدُوا إِلَّا فَاجِرًا كَفَّارًا27

Dájúdájú tí Ìwọ bá fi wọ́n sílẹ̀, wọn yóò kó ìṣìnà bá àwọn ẹrú Rẹ. Wọn kò sì níí bí ọmọ kan àfi ẹni burúkú, aláìgbàgbọ́.
71:28Júzù 29 · ojú. 571

رَبِّ اغْفِرْ لِي وَلِوَالِدَيَّ وَلِمَنْ دَخَلَ بَيْتِيَ مُؤْمِنًا وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ وَلَا تَزِدِ الظَّالِمِينَ إِلَّا تَبَارًا28

Olúwa mi foríjìn èmi, àwọn òbí mi méjèèjì àti ẹni t’ó bá wọ inú ilé mi (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Má sì ṣàlékún kan fún àwọn alábòsí àfi ìparun."

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Ibrahim Al-Akhdar - Nuh · Tlawati