Al-Adiyat

سورة العاديات

Súrà 100 · Mákí · 11 àwọn ẹsẹ

100:1Júzù 30 · ojú. 599

وَالْعَادِيَاتِ ضَبْحًا1

Allāhu búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin t’ó ń sáré t’ó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun.
100:2Júzù 30 · ojú. 599

فَالْمُورِيَاتِ قَدْحًا2

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá).
100:3Júzù 30 · ojú. 599

فَالْمُغِيرَاتِ صُبْحًا3

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin t’ó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
100:4Júzù 30 · ojú. 599

فَأَثَرْنَ بِهِ نَقْعًا4

Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè.
100:5Júzù 30 · ojú. 599

فَوَسَطْنَ بِهِ جَمْعًا5

Wọ́n tún bẹ́ gìjà papọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ sáààrin àkójọ ọ̀tá.
100:6Júzù 30 · ojú. 600

إِنَّ الْإِنْسَانَ لِرَبِّهِ لَكَنُودٌ6

Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀.
100:7Júzù 30 · ojú. 600

وَإِنَّهُ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٌ7

Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.
100:8Júzù 30 · ojú. 600

وَإِنَّهُ لِحُبِّ الْخَيْرِ لَشَدِيدٌ8

Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé.
100:9Júzù 30 · ojú. 600

۞ أَفَلَا يَعْلَمُ إِذَا بُعْثِرَ مَا فِي الْقُبُورِ9

Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun t’ó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),
100:10Júzù 30 · ojú. 600

وَحُصِّلَ مَا فِي الصُّدُورِ10

tí wọ́n sì tú ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,
100:11Júzù 30 · ojú. 600

إِنَّ رَبَّهُمْ بِهِمْ يَوْمَئِذٍ لَخَبِيرٌ11

dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà