Al-Haqqah

سورة الحاقة

Súrà 69 · Mákí · 52 àwọn ẹsẹ

69:1Júzù 29 · ojú. 566

الْحَاقَّةُ1

Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo
69:2Júzù 29 · ojú. 566

مَا الْحَاقَّةُ2

Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo.
69:3Júzù 29 · ojú. 566

وَمَا أَدْرَاكَ مَا الْحَاقَّةُ3

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo?
69:4Júzù 29 · ojú. 566

كَذَّبَتْ ثَمُودُ وَعَادٌ بِالْقَارِعَةِ4

Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Ìpáyà nírọ́.
____________________
Nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ Àjíǹde ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo àti Ìpáyà.
69:5Júzù 29 · ojú. 566

فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهْلِكُوا بِالطَّاغِيَةِ5

Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe t’ó tayọ ẹnu-àlà pa wọ́n rẹ́.
69:6Júzù 29 · ojú. 566

وَأَمَّا عَادٌ فَأُهْلِكُوا بِرِيحٍ صَرْصَرٍ عَاتِيَةٍ6

Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle t’ó tayọ ẹnu-àlà pa wọ́n rẹ́.
69:7Júzù 29 · ojú. 566

سَخَّرَهَا عَلَيْهِمْ سَبْعَ لَيَالٍ وَثَمَانِيَةَ أَيَّامٍ حُسُومًا فَتَرَى الْقَوْمَ فِيهَا صَرْعَىٰ كَأَنَّهُمْ أَعْجَازُ نَخْلٍ خَاوِيَةٍ7

Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù t’ó ti luhò nínú ni wọ́n.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Fussilat; 41:16.
69:8Júzù 29 · ojú. 566

فَهَلْ تَرَىٰ لَهُمْ مِنْ بَاقِيَةٍ8

Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn t’ó ṣẹ́ kù bí?
69:9Júzù 29 · ojú. 567

وَجَاءَ فِرْعَوْنُ وَمَنْ قَبْلَهُ وَالْمُؤْتَفِكَاتُ بِالْخَاطِئَةِ9

Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe.
69:10Júzù 29 · ojú. 567

فَعَصَوْا رَسُولَ رَبِّهِمْ فَأَخَذَهُمْ أَخْذَةً رَابِيَةً10

Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú àlékún.
69:11Júzù 29 · ojú. 567

إِنَّا لَمَّا طَغَى الْمَاءُ حَمَلْنَاكُمْ فِي الْجَارِيَةِ11

Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-àlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi.
69:12Júzù 29 · ojú. 567

لِنَجْعَلَهَا لَكُمْ تَذْكِرَةً وَتَعِيَهَا أُذُنٌ وَاعِيَةٌ12

Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fun yín àti nítorí kí etí t’ó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ.
69:13Júzù 29 · ojú. 567

فَإِذَا نُفِخَ فِي الصُّورِ نَفْخَةٌ وَاحِدَةٌ13

Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan,
69:14Júzù 29 · ojú. 567

وَحُمِلَتِ الْأَرْضُ وَالْجِبَالُ فَدُكَّتَا دَكَّةً وَاحِدَةً14

tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan,
69:15Júzù 29 · ojú. 567

فَيَوْمَئِذٍ وَقَعَتِ الْوَاقِعَةُ15

ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.
69:16Júzù 29 · ojú. 567

وَانْشَقَّتِ السَّمَاءُ فَهِيَ يَوْمَئِذٍ وَاهِيَةٌ16

Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn.
69:17Júzù 29 · ojú. 567

وَالْمَلَكُ عَلَىٰ أَرْجَائِهَا ۚ وَيَحْمِلُ عَرْشَ رَبِّكَ فَوْقَهُمْ يَوْمَئِذٍ ثَمَانِيَةٌ17

Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ.
69:18Júzù 29 · ojú. 567

يَوْمَئِذٍ تُعْرَضُونَ لَا تَخْفَىٰ مِنْكُمْ خَافِيَةٌ18

Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan t’ó máa pamọ́ (fún Wa).
69:19Júzù 29 · ojú. 567

فَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِيَمِينِهِ فَيَقُولُ هَاؤُمُ اقْرَءُوا كِتَابِيَهْ19

Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: "Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi.
69:20Júzù 29 · ojú. 567

إِنِّي ظَنَنْتُ أَنِّي مُلَاقٍ حِسَابِيَهْ20

Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé."
69:21Júzù 29 · ojú. 567

فَهُوَ فِي عِيشَةٍ رَاضِيَةٍ21

Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó máa yọ́nú sí
69:22Júzù 29 · ojú. 567

فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٍ22

nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.
69:23Júzù 29 · ojú. 567

قُطُوفُهَا دَانِيَةٌ23

Àwọn èso rẹ̀ (sì) wà ní àrọ́wọ́tó.
69:24Júzù 29 · ojú. 567

كُلُوا وَاشْرَبُوا هَنِيئًا بِمَا أَسْلَفْتُمْ فِي الْأَيَّامِ الْخَالِيَةِ24

Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá.
69:25Júzù 29 · ojú. 567

وَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِشِمَالِهِ فَيَقُولُ يَا لَيْتَنِي لَمْ أُوتَ كِتَابِيَهْ25

Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: "Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi!
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Āyah yìí ń sọ pé ọwọ́ òsì ni àwọn aláìgbàgbọ́ máa fi gba ìwé iṣẹ́ wọn, àmọ́ sūrah al-’Inṣiƙọ̄ƙ; 84:10 ń sọ pé láti ẹ̀yìn ni wọ́n máa ti gbà á.” Wọ́n ní, “Ìtakora nìyẹn!”
Èsì: Ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe ìtakora tóríbẹ́ẹ̀. Àlàyé rẹ̀ nìyí, méjéèjì ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé, ọwọ́ òsì ni aláìgbàgbọ́ máa tì bọ inú igbá-àyà rẹ̀ bọ́ sí ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi gba ìwé iṣẹ́ rẹ̀.
69:26Júzù 29 · ojú. 567

وَلَمْ أَدْرِ مَا حِسَابِيَهْ26

Àti pé èmi kò mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́.
69:27Júzù 29 · ojú. 567

يَا لَيْتَهَا كَانَتِ الْقَاضِيَةَ27

Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá).
69:28Júzù 29 · ojú. 567

مَا أَغْنَىٰ عَنِّي مَالِيَهْ ۜ28

Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀.
69:29Júzù 29 · ojú. 567

هَلَكَ عَنِّي سُلْطَانِيَهْ29

Agbára mi sì ti parun."
69:30Júzù 29 · ojú. 567

خُذُوهُ فَغُلُّوهُ30

Ẹ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn.
69:31Júzù 29 · ojú. 567

ثُمَّ الْجَحِيمَ صَلُّوهُ31

Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀.
69:32Júzù 29 · ojú. 567

ثُمَّ فِي سِلْسِلَةٍ ذَرْعُهَا سَبْعُونَ ذِرَاعًا فَاسْلُكُوهُ32

Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u ni kí ẹ kì í sí.
____________________
Gígùn “Thar‘u” kan ni gígùn láti ìlú Mọkkah sí ibi tí ó jìnnà jùlọ sí ìlú Mọkkah.
69:33Júzù 29 · ojú. 567

إِنَّهُ كَانَ لَا يُؤْمِنُ بِاللَّهِ الْعَظِيمِ33

Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi.
69:34Júzù 29 · ojú. 567

وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ الْمِسْكِينِ34

Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
69:35Júzù 29 · ojú. 567

فَلَيْسَ لَهُ الْيَوْمَ هَاهُنَا حَمِيمٌ35

Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní.
69:36Júzù 29 · ojú. 568

وَلَا طَعَامٌ إِلَّا مِنْ غِسْلِينٍ36

Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọyúnwẹ̀jẹ̀.
69:37Júzù 29 · ojú. 568

لَا يَأْكُلُهُ إِلَّا الْخَاطِئُونَ37

Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
69:38Júzù 29 · ojú. 568

فَلَا أُقْسِمُ بِمَا تُبْصِرُونَ38

Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú ohun tí ẹ̀ ń fojú rí
69:39Júzù 29 · ojú. 568

وَمَا لَا تُبْصِرُونَ39

àti ohun tí ẹ ò fojú rí.
69:40Júzù 29 · ojú. 568

إِنَّهُ لَقَوْلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ40

Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.
____________________
“Ọ̀rọ̀ òjíṣẹ́” ni ìtúmọ̀ “ƙọolu rọsūl, àmọ́ al-Ƙur’ān kì í ṣe ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ bí kò ṣe “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun”. Àgbékalẹ̀ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ yìí ni ṣíṣe àfitì ọ̀rọ̀ sí ọ̀dọ̀ alágbàsọ. Bákan náà, āyah yìí jọ āyah 19 nínú sūrah at-Tẹkwīr ní ìsọ, àmọ “Òjíṣẹ́” tí wọ́n gbàlérò nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh ni Òjíṣẹ́ abara, ìyẹn Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), Òjíṣẹ́ mọlāika ni wọ́n sì gbàlérò nínú āyah ti sūrah at-Tẹkwīr. Sàkánì ti ìkọ̀ọ̀kan ti jẹyọ l’ó ṣàfi hàn èyí bẹ́ẹ̀.
69:41Júzù 29 · ojú. 568

وَمَا هُوَ بِقَوْلِ شَاعِرٍ ۚ قَلِيلًا مَا تُؤْمِنُونَ41

Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀.
69:42Júzù 29 · ojú. 568

وَلَا بِقَوْلِ كَاهِنٍ ۚ قَلِيلًا مَا تَذَكَّرُونَ42

Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
69:43Júzù 29 · ojú. 568

تَنْزِيلٌ مِنْ رَبِّ الْعَالَمِينَ43

Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
69:44Júzù 29 · ojú. 568

وَلَوْ تَقَوَّلَ عَلَيْنَا بَعْضَ الْأَقَاوِيلِ44

Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni,
69:45Júzù 29 · ojú. 568

لَأَخَذْنَا مِنْهُ بِالْيَمِينِ45

Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún.
69:46Júzù 29 · ojú. 568

ثُمَّ لَقَطَعْنَا مِنْهُ الْوَتِينَ46

Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀.
69:47Júzù 29 · ojú. 568

فَمَا مِنْكُمْ مِنْ أَحَدٍ عَنْهُ حَاجِزِينَ47

Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa).
69:48Júzù 29 · ojú. 568

وَإِنَّهُ لَتَذْكِرَةٌ لِلْمُتَّقِينَ48

Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
69:49Júzù 29 · ojú. 568

وَإِنَّا لَنَعْلَمُ أَنَّ مِنْكُمْ مُكَذِّبِينَ49

Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn t’ó ń pe al-Ƙur’ān nírọ́ wà nínú yín.
69:50Júzù 29 · ojú. 568

وَإِنَّهُ لَحَسْرَةٌ عَلَى الْكَافِرِينَ50

Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́.
69:51Júzù 29 · ojú. 568

وَإِنَّهُ لَحَقُّ الْيَقِينِ51

Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo t’ó dájú.
69:52Júzù 29 · ojú. 568

فَسَبِّحْ بِاسْمِ رَبِّكَ الْعَظِيمِ52

Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Fares Abbad - Al-Haqqah · Tlawati