Al-Qamar

سورة القمر

Súrà 54 · Mákí · 55 àwọn ẹsẹ

54:1Júzù 27 · ojú. 528

اقْتَرَبَتِ السَّاعَةُ وَانْشَقَّ الْقَمَرُ1

Àkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì).
54:2Júzù 27 · ojú. 528

وَإِنْ يَرَوْا آيَةً يُعْرِضُوا وَيَقُولُوا سِحْرٌ مُسْتَمِرٌّ2

Tí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: "Idán kan (t’ó lágbára) t’ó máa lọ ni."
54:3Júzù 27 · ojú. 528

وَكَذَّبُوا وَاتَّبَعُوا أَهْوَاءَهُمْ ۚ وَكُلُّ أَمْرٍ مُسْتَقِرٌّ3

Wọ́n pè é nírọ́. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Gbogbo iṣẹ́ ẹ̀dá sì máa jókòó tì í lọ́rùn.
54:4Júzù 27 · ojú. 528

وَلَقَدْ جَاءَهُمْ مِنَ الْأَنْبَاءِ مَا فِيهِ مُزْدَجَرٌ4

Dájúdájú èyí tí wọ́n fi ohùn líle kọ̀ wà nínú àwọn ìró t’ó dé bá wọn.
54:5Júzù 27 · ojú. 528

حِكْمَةٌ بَالِغَةٌ ۖ فَمَا تُغْنِ النُّذُرُ5

Ìjìnlẹ̀ òye t’ó péye ni; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
54:6Júzù 27 · ojú. 528

فَتَوَلَّ عَنْهُمْ ۘ يَوْمَ يَدْعُ الدَّاعِ إِلَىٰ شَيْءٍ نُكُرٍ6

Ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè fún kiní kan tí ẹ̀mí kórira (ìyẹn, Àjíǹde),
54:7Júzù 27 · ojú. 529

خُشَّعًا أَبْصَارُهُمْ يَخْرُجُونَ مِنَ الْأَجْدَاثِ كَأَنَّهُمْ جَرَادٌ مُنْتَشِرٌ7

Ojú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n.
54:8Júzù 27 · ojú. 529

مُهْطِعِينَ إِلَى الدَّاعِ ۖ يَقُولُ الْكَافِرُونَ هَٰذَا يَوْمٌ عَسِرٌ8

Wọn yó sì máa yára lọ sí ọ̀dọ̀ olùpèpè náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: "Èyí ni ọjọ́ ìṣòro."
54:9Júzù 27 · ojú. 529

۞ كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ فَكَذَّبُوا عَبْدَنَا وَقَالُوا مَجْنُونٌ وَازْدُجِرَ9

Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: "Wèrè ni." Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Gbólóhùn ìparí āyah yìí ń sọ pé, ‘ìjọ Nūh lé Nūh jáde kúrò nínú ìlú’. Àmọ́ sūrah Hūd; 11:38 ń sọ pé, ‘Nígbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.” Wọ́n ní, “Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ Nūh tí wọ́n ti lé jáde kúrò nínú ìlú ni ẹni tí wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́!”
Èsì: Kò sí ìtakora kan nínú rẹ̀. Al-Ƙur’ān kò fi rinlẹ̀ níbì kan kan pé, ìjọ Nūh lé Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jáde kúrò nínú ìlú. Ìpìlẹ̀ “wa-zdujir” ni “zajara” láti ara “zajr” – kíkọ n̄ǹkan àti híhánnà n̄ǹkan pẹ̀lú ohùn líle. Ìyẹn ni pé, wọ́n fi ohùn líle kọ òdodo sílẹ̀ fún Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní kíkọ̀ àlésá-sẹ́yìn fún wọn nípasẹ̀ sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i, híhalẹ̀ mọ̀ ọn, dídúnkokò mọ́ ọn nítorí kí ó lè máa wò wọ́n níran. Ìtúmọ̀ “wa-zdujir” yìí ni Allāhu ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú sūrah aṣ-Ṣu‘arā’; 26:116 pé wọ́n ń fi lílẹ̀ lókò halẹ̀ mọ́ ọn. Ìtúmọ̀ kíkọ̀ náà ni ìtúmọ̀ t’ó jẹyọ nínú “muzdajar” t’ó parí āyah 4 ṣíwájú. Ìtúmọ̀ àkànlò fún “zajr” sì jẹyọ nínú sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:2. Kókó ọ̀rọ̀ ni pé, ìjọ Nūh fi ohùn líle kọ ọ̀rọ̀ sí Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lẹ́nu ni, kì í ṣe pé wọ́n lé e jáde kúrò nínú ìlú. Wọ́n kọ ìtẹ̀lé Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sílẹ̀ pẹ̀lú sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i. Àmọ́ Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wà nínú ìlú pẹ̀lú wọn títí ó fi kan ọkọ̀ ojú omi. W-Allāhu ’a‘lam.
54:10Júzù 27 · ojú. 529

فَدَعَا رَبَّهُ أَنِّي مَغْلُوبٌ فَانْتَصِرْ10

Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: "Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Ràn mí lọ́wọ́."
54:11Júzù 27 · ojú. 529

فَفَتَحْنَا أَبْوَابَ السَّمَاءِ بِمَاءٍ مُنْهَمِرٍ11

Nítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi t’ó lágbára.
54:12Júzù 27 · ojú. 529

وَفَجَّرْنَا الْأَرْضَ عُيُونًا فَالْتَقَى الْمَاءُ عَلَىٰ أَمْرٍ قَدْ قُدِرَ12

A tún mú àwọn odò ṣẹyọ lórí ilẹ̀. Omi (sánmọ̀) pàdé (omi ilẹ̀) pẹ̀lú àṣẹ tí A ti kọ (lé wọn lórí).
54:13Júzù 27 · ojú. 529

وَحَمَلْنَاهُ عَلَىٰ ذَاتِ أَلْوَاحٍ وَدُسُرٍ13

A sì gbé (Ànábì) Nūh gun ọkọ̀ onípákó, ọkọ̀ eléṣòó,
54:14Júzù 27 · ojú. 529

تَجْرِي بِأَعْيُنِنَا جَزَاءً لِمَنْ كَانَ كُفِرَ14

t’ó ń rìn (lórí omi) lójú Wa. (Ó jẹ́) ẹ̀san fún ẹni tí wọ́n takò.
54:15Júzù 27 · ojú. 529

وَلَقَدْ تَرَكْنَاهَا آيَةً فَهَلْ مِنْ مُدَّكِرٍ15

Dájúdájú A fi sílẹ̀ ní àmì. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:16Júzù 27 · ojú. 529

فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ16

Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
54:17Júzù 27 · ojú. 529

وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِنْ مُدَّكِرٍ17

Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:18Júzù 27 · ojú. 529

كَذَّبَتْ عَادٌ فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ18

Ìran ‘Ād pé òdodo nírọ́. Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
54:19Júzù 27 · ojú. 529

إِنَّا أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِيحًا صَرْصَرًا فِي يَوْمِ نَحْسٍ مُسْتَمِرٍّ19

Dájúdájú Àwa rán atẹ́gùn líle sí wọn ní ọjọ́ burúkú kan t’ó ń tẹ̀ síwájú.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Fussilat; 41:16.
54:20Júzù 27 · ojú. 529

تَنْزِعُ النَّاسَ كَأَنَّهُمْ أَعْجَازُ نَخْلٍ مُنْقَعِرٍ20

Ó ń fa àwọn ènìyàn jáde bí ẹni pé kùkùté igi ọ̀pẹ tí wọ́n fà tu tegbòtegbò ni wọ́n.
54:21Júzù 27 · ojú. 529

فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ21

Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
54:22Júzù 27 · ojú. 529

وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِنْ مُدَّكِرٍ22

Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:23Júzù 27 · ojú. 529

كَذَّبَتْ ثَمُودُ بِالنُّذُرِ23

Ìjọ Thamūd pe àwọn ìkìlọ̀ nírọ́.
54:24Júzù 27 · ojú. 529

فَقَالُوا أَبَشَرًا مِنَّا وَاحِدًا نَتَّبِعُهُ إِنَّا إِذًا لَفِي ضَلَالٍ وَسُعُرٍ24

Wọ́n wí pé: "Ṣé abara kan, ẹnì kan ṣoṣo nínú wa ni a óò máa tẹ̀lé. (Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà dájúdájú àwa ti wà nínú ìṣìnà àti ìyà.
54:25Júzù 27 · ojú. 529

أَأُلْقِيَ الذِّكْرُ عَلَيْهِ مِنْ بَيْنِنَا بَلْ هُوَ كَذَّابٌ أَشِرٌ25

Ṣé òun ni wọ́n sọ ìrántí kalẹ̀ fún láààrin wa? Rárá o, òpùrọ́ onígbèéraga ni."
54:26Júzù 27 · ojú. 529

سَيَعْلَمُونَ غَدًا مَنِ الْكَذَّابُ الْأَشِرُ26

Ní ọ̀la ni wọn yóò mọ ta ni òpùrọ́ onígbèéraga.
54:27Júzù 27 · ojú. 529

إِنَّا مُرْسِلُو النَّاقَةِ فِتْنَةً لَهُمْ فَارْتَقِبْهُمْ وَاصْطَبِرْ27

Dájúdájú Àwa máa rán abo ràkúnmí sí wọn; (ó máa jẹ́) àdánwò fún wọn. Nítorí náà, máa wò wọ́n níran ná, kí o sì ṣe sùúrù.
54:28Júzù 27 · ojú. 530

وَنَبِّئْهُمْ أَنَّ الْمَاءَ قِسْمَةٌ بَيْنَهُمْ ۖ كُلُّ شِرْبٍ مُحْتَضَرٌ28

Kí o sì fún wọn ní ìró pé dájúdájú pípín ni omi láààrin wọn. Gbogbo ìpín omi sì wà fún ẹni tí ó bá kàn láti wá sí odò.
54:29Júzù 27 · ojú. 530

فَنَادَوْا صَاحِبَهُمْ فَتَعَاطَىٰ فَعَقَرَ29

Nígbà náà ni wọ́n pe ẹni wọn. Ó wá ọ̀nà láti mú (ràkúnmí náà mọ́lẹ̀). Ó sì pa á.
54:30Júzù 27 · ojú. 530

فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ30

Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
54:31Júzù 27 · ojú. 530

إِنَّا أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ صَيْحَةً وَاحِدَةً فَكَانُوا كَهَشِيمِ الْمُحْتَظِرِ31

Dájúdájú Àwa rán igbe kan ṣoṣo sí wọn. Wọ́n sì dà bí igi koríko gbígbẹ.
54:32Júzù 27 · ojú. 530

وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِنْ مُدَّكِرٍ32

Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:33Júzù 27 · ojú. 530

كَذَّبَتْ قَوْمُ لُوطٍ بِالنُّذُرِ33

Ìjọ Lūt pe àwọn ìkìlọ̀ nírọ́.
54:34Júzù 27 · ojú. 530

إِنَّا أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ حَاصِبًا إِلَّا آلَ لُوطٍ ۖ نَجَّيْنَاهُمْ بِسَحَرٍ34

Dájúdájú Àwa fi òkúta iná ránṣẹ́ sí wọn àfi ará ilé Lūt, tí A gbàlà ní àsìkò sààrì.
54:35Júzù 27 · ojú. 530

نِعْمَةً مِنْ عِنْدِنَا ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي مَنْ شَكَرَ35

(Ó jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹni t’ó bá dúpẹ́ (fún Wa).
54:36Júzù 27 · ojú. 530

وَلَقَدْ أَنْذَرَهُمْ بَطْشَتَنَا فَتَمَارَوْا بِالنُّذُرِ36

Ó kúkú fi ìgbámú Wa ṣe ìkìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ja àwọn ìkìlọ̀ níyàn.
54:37Júzù 27 · ojú. 530

وَلَقَدْ رَاوَدُوهُ عَنْ ضَيْفِهِ فَطَمَسْنَا أَعْيُنَهُمْ فَذُوقُوا عَذَابِي وَنُذُرِ37

Wọ́n kúkú làkàkà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá àwọn aléjò rẹ̀ ṣèbàjẹ́. Nítorí náà, A fọ́ ojú wọn. Ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
54:38Júzù 27 · ojú. 530

وَلَقَدْ صَبَّحَهُمْ بُكْرَةً عَذَابٌ مُسْتَقِرٌّ38

Àti pé dájúdájú ìyà gbére ni wọ́n mọ́júmọ́ sínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
54:39Júzù 27 · ojú. 530

فَذُوقُوا عَذَابِي وَنُذُرِ39

Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
54:40Júzù 27 · ojú. 530

وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِنْ مُدَّكِرٍ40

Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:41Júzù 27 · ojú. 530

وَلَقَدْ جَاءَ آلَ فِرْعَوْنَ النُّذُرُ41

Dájúdájú àwọn ìkìlọ̀ dé bá àwọn ènìyàn Fir‘aon.
54:42Júzù 27 · ojú. 530

كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا كُلِّهَا فَأَخَذْنَاهُمْ أَخْذَ عَزِيزٍ مُقْتَدِرٍ42

Wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́, gbogbo rẹ̀ pátápátá. A sì gbá wọn mú ní ìgbámú (tí) Alágbára, Olùkápá (ń gbá ẹ̀dá mú).
54:43Júzù 27 · ojú. 530

أَكُفَّارُكُمْ خَيْرٌ مِنْ أُولَٰئِكُمْ أَمْ لَكُمْ بَرَاءَةٌ فِي الزُّبُرِ43

Ṣé àwọn aláìgbàgbọ́ (nínú) yín l’ó lóore jùlọ sí àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ti parẹ́ bọ́ sẹ́yìn) ni tàbí ẹ̀yin ní ìmóríbọ́ kan nínú ìpín-ìpín Tírà (pé ẹ̀yin kò níí jìyà)?
54:44Júzù 27 · ojú. 530

أَمْ يَقُولُونَ نَحْنُ جَمِيعٌ مُنْتَصِرٌ44

Tàbí wọ́n ń wí pé: "Gbogbo wa ni a óò ranra wa lọ́wọ́ láti borí (Òjíṣẹ́)"
54:45Júzù 27 · ojú. 530

سَيُهْزَمُ الْجَمْعُ وَيُوَلُّونَ الدُّبُرَ45

A máa fọ́ àkójọ náà lógun. Wọn sì máa fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun.
54:46Júzù 27 · ojú. 530

بَلِ السَّاعَةُ مَوْعِدُهُمْ وَالسَّاعَةُ أَدْهَىٰ وَأَمَرُّ46

Àmọ́ sá, Àkókò náà ni ọjọ́ àdéhùn wọn. Àkókò náà burú jùlọ. Ó sì korò jùlọ.
54:47Júzù 27 · ojú. 530

إِنَّ الْمُجْرِمِينَ فِي ضَلَالٍ وَسُعُرٍ47

Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìṣìnà (nílé ayé, wọn yó sì wà nínú) Iná jíjò (ní ọ̀run).
54:48Júzù 27 · ojú. 530

يَوْمَ يُسْحَبُونَ فِي النَّارِ عَلَىٰ وُجُوهِهِمْ ذُوقُوا مَسَّ سَقَرَ48

Ní ọjọ́ tí A óò dojú wọn délẹ̀ wọ inú Iná, (A ó sì sọ pé): Ẹ tọ́ ìfọwọ́bà Iná wò.
54:49Júzù 27 · ojú. 530

إِنَّا كُلَّ شَيْءٍ خَلَقْنَاهُ بِقَدَرٍ49

Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá.
54:50Júzù 27 · ojú. 531

وَمَا أَمْرُنَا إِلَّا وَاحِدَةٌ كَلَمْحٍ بِالْبَصَرِ50

Àṣẹ Wa (fún mímú n̄ǹkan bẹ) kò tayọ (àṣẹ) ẹyọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́jú.
____________________
Ìyẹn ni pé, a máa lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún nínú sàréè, àmọ́ láààrin ká ṣẹ́jú ká lajú, gbogbo ẹ̀dá máa jí dìde láti inú sàréè wọn.
54:51Júzù 27 · ojú. 531

وَلَقَدْ أَهْلَكْنَا أَشْيَاعَكُمْ فَهَلْ مِنْ مُدَّكِرٍ51

Àti pé dájúdájú A ti pa àwọn irú yín rẹ́. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:52Júzù 27 · ojú. 531

وَكُلُّ شَيْءٍ فَعَلُوهُ فِي الزُّبُرِ52

Gbogbo n̄ǹkan tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì wà nínú ìpín-ìpín tírà.
54:53Júzù 27 · ojú. 531

وَكُلُّ صَغِيرٍ وَكَبِيرٍ مُسْتَطَرٌ53

Àti pé gbogbo n̄ǹkan kékeré àti n̄ǹkan ńlá (tí wọ́n ṣe) wà ní àkọsílẹ̀.
54:54Júzù 27 · ojú. 531

إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي جَنَّاتٍ وَنَهَرٍ54

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà (Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn odò (t’ó ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
54:55Júzù 27 · ojú. 531

فِي مَقْعَدِ صِدْقٍ عِنْدَ مَلِيكٍ مُقْتَدِرٍ55

Ní ibùjókòó òdodo nítòsí Ọba Alágbára Olùkápá.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Ali Jaber - Al-Qamar · Tlawati