At-Takwir

سورة التكوير

Súrà 81 · Mákí · 29 àwọn ẹsẹ

81:1Júzù 30 · ojú. 586

إِذَا الشَّمْسُ كُوِّرَتْ1

Nígbà tí Wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,
81:2Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا النُّجُومُ انْكَدَرَتْ2

àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
81:3Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا الْجِبَالُ سُيِّرَتْ3

àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),
81:4Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا الْعِشَارُ عُطِّلَتْ4

àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,
81:5Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا الْوُحُوشُ حُشِرَتْ5

àti nígbà tí Wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,
81:6Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا الْبِحَارُ سُجِّرَتْ6

àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,
81:7Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا النُّفُوسُ زُوِّجَتْ7

àti nígbà tí Wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)
81:8Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا الْمَوْءُودَةُ سُئِلَتْ8

àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé
81:9Júzù 30 · ojú. 586

بِأَيِّ ذَنْبٍ قُتِلَتْ9

ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún,
81:10Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا الصُّحُفُ نُشِرَتْ10

àti nígbà tí Wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,
81:11Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا السَّمَاءُ كُشِطَتْ11

àti nígbà tí Wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,
81:12Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا الْجَحِيمُ سُعِّرَتْ12

àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,
81:13Júzù 30 · ojú. 586

وَإِذَا الْجَنَّةُ أُزْلِفَتْ13

àti nígbà tí Wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),
81:14Júzù 30 · ojú. 586

عَلِمَتْ نَفْسٌ مَا أَحْضَرَتْ14

(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).
81:15Júzù 30 · ojú. 586

فَلَا أُقْسِمُ بِالْخُنَّسِ15

Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ t’ó ń yọ ní alẹ́, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán,
81:16Júzù 30 · ojú. 586

الْجَوَارِ الْكُنَّسِ16

(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ t’ó ń rìn lọ rìn bọ̀, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.
81:17Júzù 30 · ojú. 586

وَاللَّيْلِ إِذَا عَسْعَسَ17

Mo tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ.
81:18Júzù 30 · ojú. 586

وَالصُّبْحِ إِذَا تَنَفَّسَ18

Mo tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀.
81:19Júzù 30 · ojú. 586

إِنَّهُ لَقَوْلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ19

Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,
____________________
Wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hāƙƙọh; 69:40.
81:20Júzù 30 · ojú. 586

ذِي قُوَّةٍ عِنْدَ ذِي الْعَرْشِ مَكِينٍ20

alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,
81:21Júzù 30 · ojú. 586

مُطَاعٍ ثَمَّ أَمِينٍ21

ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.
81:22Júzù 30 · ojú. 586

وَمَا صَاحِبُكُمْ بِمَجْنُونٍ22

Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad s.a.w.) kì í ṣe wèrè.
81:23Júzù 30 · ojú. 586

وَلَقَدْ رَآهُ بِالْأُفُقِ الْمُبِينِ23

Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Najm; 53:13.
81:24Júzù 30 · ojú. 586

وَمَا هُوَ عَلَى الْغَيْبِ بِضَنِينٍ24

Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).
81:25Júzù 30 · ojú. 586

وَمَا هُوَ بِقَوْلِ شَيْطَانٍ رَجِيمٍ25

Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.
81:26Júzù 30 · ojú. 586

فَأَيْنَ تَذْهَبُونَ26

Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?
81:27Júzù 30 · ojú. 586

إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِلْعَالَمِينَ27

Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
81:28Júzù 30 · ojú. 586

لِمَنْ شَاءَ مِنْكُمْ أَنْ يَسْتَقِيمَ28

(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.
81:29Júzù 30 · ojú. 586

وَمَا تَشَاءُونَ إِلَّا أَنْ يَشَاءَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ29

Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà