At-Tur

سورة الطور

Súrà 52 · Mákí · 49 àwọn ẹsẹ

52:1Júzù 27 · ojú. 523

وَالطُّورِ1

(Allāhu búra pẹ̀lú) àpáta Tūr.
52:2Júzù 27 · ojú. 523

وَكِتَابٍ مَسْطُورٍ2

(Ó tún búra pẹ̀lú) Tírà tí wọ́n kọ sílẹ̀
52:3Júzù 27 · ojú. 523

فِي رَقٍّ مَنْشُورٍ3

sínú tákàdá tí wọ́n tẹ́ sílẹ̀.
52:4Júzù 27 · ojú. 523

وَالْبَيْتِ الْمَعْمُورِ4

(Ó tún búra pẹ̀lú) Ilé Àbẹ̀wò náà.
52:5Júzù 27 · ojú. 523

وَالسَّقْفِ الْمَرْفُوعِ5

(Ó tún búra pẹ̀lú) àjà tí wọ́n gbé sókè (ìyẹn, sánmọ̀).
52:6Júzù 27 · ojú. 523

وَالْبَحْرِ الْمَسْجُورِ6

(Ó tún búra pẹ̀lú) agbami odò iná.
52:7Júzù 27 · ojú. 523

إِنَّ عَذَابَ رَبِّكَ لَوَاقِعٌ7

Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ máa ṣẹlẹ̀.
52:8Júzù 27 · ojú. 523

مَا لَهُ مِنْ دَافِعٍ8

Kò sí olùdènà kan fún un.
52:9Júzù 27 · ojú. 523

يَوْمَ تَمُورُ السَّمَاءُ مَوْرًا9

(Ó máa ṣẹlẹ̀) ní ọjọ́ tí sánmọ̀ máa mì tìtì tààrà.
52:10Júzù 27 · ojú. 523

وَتَسِيرُ الْجِبَالُ سَيْرًا10

Àwọn àpáta sì máa rìn lọ tààrà (bí eruku àfẹ́dànù).
52:11Júzù 27 · ojú. 523

فَوَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ11

Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́,
52:12Júzù 27 · ojú. 523

الَّذِينَ هُمْ فِي خَوْضٍ يَلْعَبُونَ12

àwọn tí wọ́n wà nínú ìsọkúsọ, tí wọ́n ń ṣeré.
52:13Júzù 27 · ojú. 523

يَوْمَ يُدَعُّونَ إِلَىٰ نَارِ جَهَنَّمَ دَعًّا13

(Rántí) ọjọ́ tí wọn yóò tì wọ́n lọ́ sínú iná Jahanamọ ní ìtìkutì.
52:14Júzù 27 · ojú. 523

هَٰذِهِ النَّارُ الَّتِي كُنْتُمْ بِهَا تُكَذِّبُونَ14

Èyí ni Iná náà tí ẹ̀ ń pè nírọ́.
52:15Júzù 27 · ojú. 524

أَفَسِحْرٌ هَٰذَا أَمْ أَنْتُمْ لَا تُبْصِرُونَ15

Ṣé idán ni èyí ni tàbí ẹ ò ríran?
52:16Júzù 27 · ojú. 524

اصْلَوْهَا فَاصْبِرُوا أَوْ لَا تَصْبِرُوا سَوَاءٌ عَلَيْكُمْ ۖ إِنَّمَا تُجْزَوْنَ مَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ16

Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ. Ẹ fara dà á tàbí ẹ ò fara dà á, bákan náà ni fun yín. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san.
52:17Júzù 27 · ojú. 524

إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي جَنَّاتٍ وَنَعِيمٍ17

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà àti ìdẹ̀ra.
52:18Júzù 27 · ojú. 524

فَاكِهِينَ بِمَا آتَاهُمْ رَبُّهُمْ وَوَقَاهُمْ رَبُّهُمْ عَذَابَ الْجَحِيمِ18

Wọn yóò máa jẹ ìgbádùn pẹ̀lú ohun tí Olúwa wọn fún wọn. Àti pé (Allāhu) yóò ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm.
52:19Júzù 27 · ojú. 524

كُلُوا وَاشْرَبُوا هَنِيئًا بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ19

Ẹ máa jẹ, ẹ máa mu ní gbẹdẹmukẹ nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
52:20Júzù 27 · ojú. 524

مُتَّكِئِينَ عَلَىٰ سُرُرٍ مَصْفُوفَةٍ ۖ وَزَوَّجْنَاهُمْ بِحُورٍ عِينٍ20

Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn tí wọ́n tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. A sì máa fún wọn ní àwọn ìyàwó ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́.
52:21Júzù 27 · ojú. 524

وَالَّذِينَ آمَنُوا وَاتَّبَعَتْهُمْ ذُرِّيَّتُهُمْ بِإِيمَانٍ أَلْحَقْنَا بِهِمْ ذُرِّيَّتَهُمْ وَمَا أَلَتْنَاهُمْ مِنْ عَمَلِهِمْ مِنْ شَيْءٍ ۚ كُلُّ امْرِئٍ بِمَا كَسَبَ رَهِينٌ21

Àti pé àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn tún tẹ̀lé wọn nínú ìgbàgbọ́ òdodo, A máa da àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn pọ̀ mọ́ wọn. A ò sì níí dín kiní kan kù nínú iṣẹ́ wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun t’ó ṣe níṣẹ́.
52:22Júzù 27 · ojú. 524

وَأَمْدَدْنَاهُمْ بِفَاكِهَةٍ وَلَحْمٍ مِمَّا يَشْتَهُونَ22

A máa fún wọn ní àlékún èso àti ẹran tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí.
52:23Júzù 27 · ojú. 524

يَتَنَازَعُونَ فِيهَا كَأْسًا لَا لَغْوٌ فِيهَا وَلَا تَأْثِيمٌ23

Wọn yó sì máa gba ife ọtí mu láààrin ara wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kò sí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
52:24Júzù 27 · ojú. 524

۞ وَيَطُوفُ عَلَيْهِمْ غِلْمَانٌ لَهُمْ كَأَنَّهُمْ لُؤْلُؤٌ مَكْنُونٌ24

Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. (Wọ́n) dà bí àlúùúlù àfipamọ́.
52:25Júzù 27 · ojú. 524

وَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَسَاءَلُونَ25

Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, wọn yó sì máa bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ara wọn.
52:26Júzù 27 · ojú. 524

قَالُوا إِنَّا كُنَّا قَبْلُ فِي أَهْلِنَا مُشْفِقِينَ26

Wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwa jẹ́ olùpáyà láààrin àwọn ènìyàn wa.
52:27Júzù 27 · ojú. 524

فَمَنَّ اللَّهُ عَلَيْنَا وَوَقَانَا عَذَابَ السَّمُومِ27

Ṣùgbọ́n Allāhu ṣàánú wa. Ó sì là wá níbi ìyà Iná.
52:28Júzù 27 · ojú. 524

إِنَّا كُنَّا مِنْ قَبْلُ نَدْعُوهُ ۖ إِنَّهُ هُوَ الْبَرُّ الرَّحِيمُ28

Dájúdájú àwa máa ń pè É tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olóore, Àṣàkẹ́-ọ̀run."
52:29Júzù 27 · ojú. 524

فَذَكِّرْ فَمَا أَنْتَ بِنِعْمَتِ رَبِّكَ بِكَاهِنٍ وَلَا مَجْنُونٍ29

Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kì í ṣe adábigba tàbí wèrè lórí ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
52:30Júzù 27 · ojú. 524

أَمْ يَقُولُونَ شَاعِرٌ نَتَرَبَّصُ بِهِ رَيْبَ الْمَنُونِ30

Tàbí wọ́n ń wí pé: "Eléwì kan tí à ń retí ikú rẹ̀ ni."
52:31Júzù 27 · ojú. 524

قُلْ تَرَبَّصُوا فَإِنِّي مَعَكُمْ مِنَ الْمُتَرَبِّصِينَ31

Sọ pé: "Ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.
52:32Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ تَأْمُرُهُمْ أَحْلَامُهُمْ بِهَٰذَا ۚ أَمْ هُمْ قَوْمٌ طَاغُونَ32

Tàbí ọpọlọ wọn ń pa wọ́n láṣẹ èyí ni? Tàbí ìjọ alákọyọ ni wọ́n ni?
52:33Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ يَقُولُونَ تَقَوَّلَهُ ۚ بَلْ لَا يُؤْمِنُونَ33

Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni." Rárá o, wọn kò gbàgbọ́ ni.
52:34Júzù 27 · ojú. 525

فَلْيَأْتُوا بِحَدِيثٍ مِثْلِهِ إِنْ كَانُوا صَادِقِينَ34

Kí àwọn náà mú ọ̀rọ̀ kan bí irú rẹ̀ wá tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
52:35Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ خُلِقُوا مِنْ غَيْرِ شَيْءٍ أَمْ هُمُ الْخَالِقُونَ35

Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni?
52:36Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ خَلَقُوا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ ۚ بَلْ لَا يُوقِنُونَ36

Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni.
52:37Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ عِنْدَهُمْ خَزَائِنُ رَبِّكَ أَمْ هُمُ الْمُصَيْطِرُونَ37

Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni àwọn àpótí ọrọ̀ Olúwa rẹ wà? Tàbí àwọn ni olùborí?
52:38Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ لَهُمْ سُلَّمٌ يَسْتَمِعُونَ فِيهِ ۖ فَلْيَأْتِ مُسْتَمِعُهُمْ بِسُلْطَانٍ مُبِينٍ38

Tàbí wọ́n ní àkàbà tí wọ́n ń fi gbọ́rọ̀ (nínú sánmọ̀ ni)? Kí olùgbọ́rọ̀ wọn mú ẹ̀rí pọ́nńbélé wá?
52:39Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ لَهُ الْبَنَاتُ وَلَكُمُ الْبَنُونَ39

Tàbí àwọn ọmọbìnrin ni tiRẹ̀, àwọn ọmọkùnrin sì ni tiyín?
52:40Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ تَسْأَلُهُمْ أَجْرًا فَهُمْ مِنْ مَغْرَمٍ مُثْقَلُونَ40

Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́dọ̀ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
52:41Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ عِنْدَهُمُ الْغَيْبُ فَهُمْ يَكْتُبُونَ41

Tàbí ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń kọ ọ́ sílẹ̀?
52:42Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ يُرِيدُونَ كَيْدًا ۖ فَالَّذِينَ كَفَرُوا هُمُ الْمَكِيدُونَ42

Tàbí wọ́n ń gbèrò ète kan ni? Nígbà náà, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn l’ó máa f’orí kó ète.
52:43Júzù 27 · ojú. 525

أَمْ لَهُمْ إِلَٰهٌ غَيْرُ اللَّهِ ۚ سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يُشْرِكُونَ43

Tàbí wọ́n ní ọlọ́hun kan lẹ́yìn Allāhu ni? Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
52:44Júzù 27 · ojú. 525

وَإِنْ يَرَوْا كِسْفًا مِنَ السَّمَاءِ سَاقِطًا يَقُولُوا سَحَابٌ مَرْكُومٌ44

Tí wọ́n bá sì rí apá kan nínú sánmọ̀ t’ó ya lúlẹ̀, wọ́n á wí pé: "Ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ ni (wọn kò níí gbàgbọ́)."
52:45Júzù 27 · ojú. 525

فَذَرْهُمْ حَتَّىٰ يُلَاقُوا يَوْمَهُمُ الَّذِي فِيهِ يُصْعَقُونَ45

Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ títí wọn yóò fi bá ọjọ́ wọn tí wọn máa pa wọ́n sínú rẹ̀ pàdé.
52:46Júzù 27 · ojú. 525

يَوْمَ لَا يُغْنِي عَنْهُمْ كَيْدُهُمْ شَيْئًا وَلَا هُمْ يُنْصَرُونَ46

Ọjọ́ tí ète wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
52:47Júzù 27 · ojú. 525

وَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا عَذَابًا دُونَ ذَٰلِكَ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ47

Àti pé dájúdájú ìyà kan ń bẹ fún àwọn t’ó ṣàbòsí yàtọ̀ sí (ìyà ọ̀run) yẹn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
52:48Júzù 27 · ojú. 525

وَاصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ فَإِنَّكَ بِأَعْيُنِنَا ۖ وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ حِينَ تَقُومُ48

Ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa Rẹ, dájúdájú ìwọ wà ní ojútó Wa. Kí ó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ nígbà tí ó bá ń dìde nàró (fún ìrun kíkí).
52:49Júzù 27 · ojú. 525

وَمِنَ اللَّيْلِ فَسَبِّحْهُ وَإِدْبَارَ النُّجُومِ49

Àti ní alẹ́ (nígbà tí) àwọn ìràwọ̀ bá kúrò níta tán, ṣàfọ̀mọ́ fún Un.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Abdullah Basfar - At-Tur · Tlawati