Ad-Dukhan

سورة الدخان

Súrà 44 · Mákí · 59 àwọn ẹsẹ

44:1Júzù 25 · ojú. 496

حم1

Hā mīm.
44:2Júzù 25 · ojú. 496

وَالْكِتَابِ الْمُبِينِ2

(Allāhu) búra pẹ̀lú Tírà t’ó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
44:3Júzù 25 · ojú. 496

إِنَّا أَنْزَلْنَاهُ فِي لَيْلَةٍ مُبَارَكَةٍ ۚ إِنَّا كُنَّا مُنْذِرِينَ3

Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú òru ìbùkún. Dájúdájú Àwa ń jẹ́ Olùkìlọ̀.
44:4Júzù 25 · ojú. 496

فِيهَا يُفْرَقُ كُلُّ أَمْرٍ حَكِيمٍ4

Nínú òru náà ni wọ́n ti máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò níí tàsé (lórí ẹ̀dá).
44:5Júzù 25 · ojú. 496

أَمْرًا مِنْ عِنْدِنَا ۚ إِنَّا كُنَّا مُرْسِلِينَ5

Àṣẹ kan ni láti ọ̀dọ̀ Wa. Dájúdájú Àwa l’À ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́.
44:6Júzù 25 · ojú. 496

رَحْمَةً مِنْ رَبِّكَ ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ6

Ìkẹ́ kan ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
44:7Júzù 25 · ojú. 496

رَبِّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِنْ كُنْتُمْ مُوقِنِينَ7

Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.
44:8Júzù 25 · ojú. 496

لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ رَبُّكُمْ وَرَبُّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ8

Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
44:9Júzù 25 · ojú. 496

بَلْ هُمْ فِي شَكٍّ يَلْعَبُونَ9

Síbẹ̀, wọ́n sì wà nínú iyèméjì, tí wọ́n ń ṣeré.
44:10Júzù 25 · ojú. 496

فَارْتَقِبْ يَوْمَ تَأْتِي السَّمَاءُ بِدُخَانٍ مُبِينٍ10

Nítorí náà, máa retí ọjọ́ tí sánmọ̀ yóò mú èéfín pọ́nńbélé wá.
44:11Júzù 25 · ojú. 496

يَغْشَى النَّاسَ ۖ هَٰذَا عَذَابٌ أَلِيمٌ11

Ó máa bo àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀. Èyí ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
44:12Júzù 25 · ojú. 496

رَبَّنَا اكْشِفْ عَنَّا الْعَذَابَ إِنَّا مُؤْمِنُونَ12

(Àwọn ènìyàn yóò wí pé): Olúwa wa, gbé ìyà náà kúrò fún wa, dájúdájú àwa yóò gbàgbọ́ ní òdodo.
44:13Júzù 25 · ojú. 496

أَنَّىٰ لَهُمُ الذِّكْرَىٰ وَقَدْ جَاءَهُمْ رَسُولٌ مُبِينٌ13

Báwo ni ìrántí ṣe lè wúlò fún wọn (lásìkò ìyà)? Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé kúkú ti dé bá wọn.
44:14Júzù 25 · ojú. 496

ثُمَّ تَوَلَّوْا عَنْهُ وَقَالُوا مُعَلَّمٌ مَجْنُونٌ14

Lẹ́yìn náà, wọ́n gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì wí pé: "Wèrè tí ènìyàn kan ń kọ́ ní ẹ̀kọ́ ni."
44:15Júzù 25 · ojú. 496

إِنَّا كَاشِفُو الْعَذَابِ قَلِيلًا ۚ إِنَّكُمْ عَائِدُونَ15

Dájúdájú Àwa máa gbé ìyà náà kúrò fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹ̀yin yóò tún padà (sínú àìgbàgbọ́).
44:16Júzù 25 · ojú. 496

يَوْمَ نَبْطِشُ الْبَطْشَةَ الْكُبْرَىٰ إِنَّا مُنْتَقِمُونَ16

Ọjọ́ tí A óò gbá (wọn mú) ní ìgbámú t’ó tóbi jùlọ; dájúdájú Àwa yóò gba ẹ̀san ìyà (lára wọn).
44:17Júzù 25 · ojú. 496

۞ وَلَقَدْ فَتَنَّا قَبْلَهُمْ قَوْمَ فِرْعَوْنَ وَجَاءَهُمْ رَسُولٌ كَرِيمٌ17

Dájúdájú A dán àwọn ènìyàn Fir‘aon wò ṣíwájú wọn. Òjíṣẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé sì dé wá bá wọn.
44:18Júzù 25 · ojú. 496

أَنْ أَدُّوا إِلَيَّ عِبَادَ اللَّهِ ۖ إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ18

(Ó sọ pé): “Ẹ kó àwọn ẹrúsìn Allāhu lé mi lọ́wọ́. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
44:19Júzù 25 · ojú. 497

وَأَنْ لَا تَعْلُوا عَلَى اللَّهِ ۖ إِنِّي آتِيكُمْ بِسُلْطَانٍ مُبِينٍ19

Ẹ má ṣe ṣègbéraga sí Allāhu. Dájúdájú èmi ti mú ẹ̀rí pọ́nńbélé wá ba yín.
44:20Júzù 25 · ojú. 497

وَإِنِّي عُذْتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُمْ أَنْ تَرْجُمُونِ20

Dájúdájú Èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín pé kí ẹ má ṣe sọ mí lókò pa.
44:21Júzù 25 · ojú. 497

وَإِنْ لَمْ تُؤْمِنُوا لِي فَاعْتَزِلُونِ21

Tí ẹ kò bá sì gbà mí gbọ́, ẹ fi mí sílẹ̀ jẹ́."
44:22Júzù 25 · ojú. 497

فَدَعَا رَبَّهُ أَنَّ هَٰؤُلَاءِ قَوْمٌ مُجْرِمُونَ22

Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ ẹlẹ́sẹ̀.
44:23Júzù 25 · ojú. 497

فَأَسْرِ بِعِبَادِي لَيْلًا إِنَّكُمْ مُتَّبَعُونَ23

(Allāhu sọ pé): "Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní alẹ́ (nítorí pé) wọn yóò tọ̀ yín lẹ́yìn.
44:24Júzù 25 · ojú. 497

وَاتْرُكِ الْبَحْرَ رَهْوًا ۖ إِنَّهُمْ جُنْدٌ مُغْرَقُونَ24

Kí o sì fi agbami odò sílẹ̀ ní yíyanu sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Dájúdájú àwọn ni ọmọ ogun tí A máa tẹ̀rì sínú agbami.
44:25Júzù 25 · ojú. 497

كَمْ تَرَكُوا مِنْ جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ25

Mélòó mélòó nínú àwọn ọgbà oko àti odò ìṣẹ́lẹ̀rú tí wọ́n fi sílẹ̀ (lẹ́yìn ìparun wọn).
44:26Júzù 25 · ojú. 497

وَزُرُوعٍ وَمَقَامٍ كَرِيمٍ26

Àti àwọn irúgbìn pẹ̀lú àyè àpọ́nlé (tí wọ́n fi sílẹ̀).
44:27Júzù 25 · ojú. 497

وَنَعْمَةٍ كَانُوا فِيهَا فَاكِهِينَ27

Àti ìdẹ̀ra tí wọ́n ń gbádùn nínú rẹ̀ (ṣíwájú ìparun wọn).
44:28Júzù 25 · ojú. 497

كَذَٰلِكَ ۖ وَأَوْرَثْنَاهَا قَوْمًا آخَرِينَ28

Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn ṣe rí). A sì jogún (ìlú) wọ́n fún ìjọ ènìyàn mìíràn.
44:29Júzù 25 · ojú. 497

فَمَا بَكَتْ عَلَيْهِمُ السَّمَاءُ وَالْأَرْضُ وَمَا كَانُوا مُنْظَرِينَ29

Nígbà náà, sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sunkún wọn. Wọn kò sì fi ìyà wọn falẹ̀.
44:30Júzù 25 · ojú. 497

وَلَقَدْ نَجَّيْنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ مِنَ الْعَذَابِ الْمُهِينِ30

Dájúdájú A gba àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl là nínú ìyà yẹpẹrẹ.
44:31Júzù 25 · ojú. 497

مِنْ فِرْعَوْنَ ۚ إِنَّهُ كَانَ عَالِيًا مِنَ الْمُسْرِفِينَ31

(A là wọ́n) lọ́wọ́ Fir‘aon. Dájúdájú ó jẹ́ onígbèéraga. Ó sì wà nínú àwọn alákọyọ.
44:32Júzù 25 · ojú. 497

وَلَقَدِ اخْتَرْنَاهُمْ عَلَىٰ عِلْمٍ عَلَى الْعَالَمِينَ32

A kúkú ṣà wọ́n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn) pẹ̀lú ìmọ̀.
____________________
“pẹ̀lú ìmọ̀” ní àyè yìí túmọ̀ sí pé, ṣíṣa àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá ti wà nínú ìmọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nípa wọn ṣíwájú ìṣẹ̀dá wọn. Bákan náà, “lórí àwọn ẹ̀dá” ní àyè yìí túmọ̀ sí àwọn ẹ̀dá ìgbà tiwọn. Àmọ́ lẹ́yìn ìgbédìde Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), ìjọ rẹ̀ ni Allāhu tún ṣà lẹ́ṣà lórí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl àti àwọn ènìyàn yòókù pátápátá. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:110. Kíyè sí i, ibikíbi nínú al-Ƙur’ān tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ti sọ pé Òun ṣa àwọn ẹ̀dá kan lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá mìíràn, ó dúró fún àwọn ẹ̀dá ìgbà tiwọn nìkan. Ìṣàlẹ́ṣà náà kò sì kan àwọn ará ìgbà mìíràn. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:47 àti 122, sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:33, sūrah al-’Ani‘ām; 6:86, sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:140 àti sūrah al-Jāthiyah; 45:16.
44:33Júzù 25 · ojú. 497

وَآتَيْنَاهُمْ مِنَ الْآيَاتِ مَا فِيهِ بَلَاءٌ مُبِينٌ33

A sì fún wọn ní àwọn àmì tí àdánwò pọ́nńbélé wà nínú rẹ̀.
44:34Júzù 25 · ojú. 497

إِنَّ هَٰؤُلَاءِ لَيَقُولُونَ34

Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ń wí pé:
44:35Júzù 25 · ojú. 497

إِنْ هِيَ إِلَّا مَوْتَتُنَا الْأُولَىٰ وَمَا نَحْنُ بِمُنْشَرِينَ35

"Kò sí ikú kan àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí ó pa wá nílé ayé). Wọn kò sì níí gbé wa dìde.
44:36Júzù 25 · ojú. 497

فَأْتُوا بِآبَائِنَا إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ36

(Bí bẹ́ẹ̀ kọ́), ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo."
44:37Júzù 25 · ojú. 497

أَهُمْ خَيْرٌ أَمْ قَوْمُ تُبَّعٍ وَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ أَهْلَكْنَاهُمْ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا مُجْرِمِينَ37

Ṣé àwọn ni wọ́n lóore jùlọ ni tàbí àwọn ènìyàn Tubba‘u àti àwọn t’ó ṣíwájú wọn? A pa wọ́n rẹ́; dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
44:38Júzù 25 · ojú. 497

وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا لَاعِبِينَ38

A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe.
44:39Júzù 25 · ojú. 497

مَا خَلَقْنَاهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ39

A kò dá àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
44:40Júzù 25 · ojú. 498

إِنَّ يَوْمَ الْفَصْلِ مِيقَاتُهُمْ أَجْمَعِينَ40

Dájúdájú ọjọ́ òpínyà (ìyẹn, ọjọ́ àjíǹde) ni àkókò àdéhùn fún gbogbo wọn pátápátá.
44:41Júzù 25 · ojú. 498

يَوْمَ لَا يُغْنِي مَوْلًى عَنْ مَوْلًى شَيْئًا وَلَا هُمْ يُنْصَرُونَ41

Ní ọjọ́ tí ọ̀rẹ́ kan kò níí fi kiní kan rọ ọ̀rẹ́ kan lọ́rọ̀. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
44:42Júzù 25 · ojú. 498

إِلَّا مَنْ رَحِمَ اللَّهُ ۚ إِنَّهُ هُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ42

Àyàfi ẹni tí Allāhu bá kẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
44:43Júzù 25 · ojú. 498

إِنَّ شَجَرَتَ الزَّقُّومِ43

Dájúdájú igi zaƙūm
44:44Júzù 25 · ojú. 498

طَعَامُ الْأَثِيمِ44

ni oúnjẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.
44:45Júzù 25 · ojú. 498

كَالْمُهْلِ يَغْلِي فِي الْبُطُونِ45

Ó dà bí epo gbígbá tí ń hó nínú ikùn
44:46Júzù 25 · ojú. 498

كَغَلْيِ الْحَمِيمِ46

(t’ó) dà bí híhó omi gbígbóná.
44:47Júzù 25 · ojú. 498

خُذُوهُ فَاعْتِلُوهُ إِلَىٰ سَوَاءِ الْجَحِيمِ47

Ẹ mú un. Kí ẹ wọ́ ọ sáàrin gbùngbùn inú iná Jẹhīm.
44:48Júzù 25 · ojú. 498

ثُمَّ صُبُّوا فَوْقَ رَأْسِهِ مِنْ عَذَابِ الْحَمِيمِ48

Lẹ́yìn náà, ẹ rọ́ ìyà olómi gbígbóná lé e lórí.
44:49Júzù 25 · ojú. 498

ذُقْ إِنَّكَ أَنْتَ الْعَزِيزُ الْكَرِيمُ49

Tọ́ ọ wò (ṣebí) dájúdájú ìwọ ni alágbára, alápọ̀n-ọ́nlé (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pe ara rẹ).
44:50Júzù 25 · ojú. 498

إِنَّ هَٰذَا مَا كُنْتُمْ بِهِ تَمْتَرُونَ50

Dájúdájú (ìyà) èyí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀!
44:51Júzù 25 · ojú. 498

إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي مَقَامٍ أَمِينٍ51

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà ní àyè ìfàyàbalẹ̀.
44:52Júzù 25 · ojú. 498

فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ52

(Wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
44:53Júzù 25 · ojú. 498

يَلْبَسُونَ مِنْ سُنْدُسٍ وَإِسْتَبْرَقٍ مُتَقَابِلِينَ53

Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ àti àrán t’ó nípọn; wọn yó sì máà kọjú síra wọn.
44:54Júzù 25 · ojú. 498

كَذَٰلِكَ وَزَوَّجْنَاهُمْ بِحُورٍ عِينٍ54

Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn yó ṣe rí). A sì máa fi àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ ṣe ìyàwó fún wọn.
44:55Júzù 25 · ojú. 498

يَدْعُونَ فِيهَا بِكُلِّ فَاكِهَةٍ آمِنِينَ55

Wọn yóò máa bèèrè fún gbogbo n̄ǹkan eléso nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀.
44:56Júzù 25 · ojú. 498

لَا يَذُوقُونَ فِيهَا الْمَوْتَ إِلَّا الْمَوْتَةَ الْأُولَىٰ ۖ وَوَقَاهُمْ عَذَابَ الْجَحِيمِ56

Wọn kò níí tọ́ ikú wò níbẹ̀ àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí wọ́n ti kú nílé ayé). (Allāhu) sì máa ṣọ́ wọn níbi ìyà iná Jẹhīm.
44:57Júzù 25 · ojú. 498

فَضْلًا مِنْ رَبِّكَ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ57

Ó jẹ́ oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
44:58Júzù 25 · ojú. 498

فَإِنَّمَا يَسَّرْنَاهُ بِلِسَانِكَ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ58

Nítorí náà, A ṣe (al-Ƙur’ān) ní ìrọ̀rùn lórí ahọ́n rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
44:59Júzù 25 · ojú. 498

فَارْتَقِبْ إِنَّهُمْ مُرْتَقِبُونَ59

Nítorí náà, máa retí. Dájúdájú àwọn náà ń retí.
____________________
ìparun àwọn agbọ́mágbà

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Abdullah Basfar - Ad-Dukhan · Tlawati