Qaf

سورة ق

Súrà 50 · Mákí · 45 àwọn ẹsẹ

50:1Júzù 26 · ojú. 518

ق ۚ وَالْقُرْآنِ الْمَجِيدِ1

Ƙọ̄f. (Allāhu fi) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé búra.
50:2Júzù 26 · ojú. 518

بَلْ عَجِبُوا أَنْ جَاءَهُمْ مُنْذِرٌ مِنْهُمْ فَقَالَ الْكَافِرُونَ هَٰذَا شَيْءٌ عَجِيبٌ2

Ṣùgbọ́n wọ́n ṣèèmọ̀ nítorí pé olùkìlọ̀ kan wá bá wọn láti ààrin ara wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: "Èyí ni ohun ìyanu."
50:3Júzù 26 · ojú. 518

أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا ۖ ذَٰلِكَ رَجْعٌ بَعِيدٌ3

Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ (ni a óò tún jí dìde padà). Ìyẹn ni ìdápadà tó jìnnà (sí n̄ǹkan tí ó lè ṣẹlẹ̀).
50:4Júzù 26 · ojú. 518

قَدْ عَلِمْنَا مَا تَنْقُصُ الْأَرْضُ مِنْهُمْ ۖ وَعِنْدَنَا كِتَابٌ حَفِيظٌ4

Dájúdájú A ti mọ ohun tí ilẹ̀ ń mú jẹ nínú wọn. Tírà (iṣẹ́ ẹ̀dá ) tí wọ́n ń ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ Wa.
50:5Júzù 26 · ojú. 518

بَلْ كَذَّبُوا بِالْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُمْ فَهُمْ فِي أَمْرٍ مَرِيجٍ5

Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe òdodo (al-Ƙur’ān) ní irọ́ nígbà tí ó dé bá wọn. Nítorí náà, wọ́n ti wà nínú ìdààmú.
50:6Júzù 26 · ojú. 518

أَفَلَمْ يَنْظُرُوا إِلَى السَّمَاءِ فَوْقَهُمْ كَيْفَ بَنَيْنَاهَا وَزَيَّنَّاهَا وَمَا لَهَا مِنْ فُرُوجٍ6

Ṣé wọn kò wo sánmọ̀ òkè wọn bí A ti ṣe mọ ọ́n pa àti (bí) A ti ṣe é ní ọ̀ṣọ́, tí kò sì sí àlàfo sísán kan lára rẹ̀?
50:7Júzù 26 · ojú. 518

وَالْأَرْضَ مَدَدْنَاهَا وَأَلْقَيْنَا فِيهَا رَوَاسِيَ وَأَنْبَتْنَا فِيهَا مِنْ كُلِّ زَوْجٍ بَهِيجٍ7

Àti pé ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú oríṣiríṣi irúgbìn t’ó dára hù jáde láti inú rẹ̀.
50:8Júzù 26 · ojú. 518

تَبْصِرَةً وَذِكْرَىٰ لِكُلِّ عَبْدٍ مُنِيبٍ8

(Ó jẹ́) àríwòye àti ìrántí fún gbogbo ẹrúsìn tó ń ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
50:9Júzù 26 · ojú. 518

وَنَزَّلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً مُبَارَكًا فَأَنْبَتْنَا بِهِ جَنَّاتٍ وَحَبَّ الْحَصِيدِ9

A ń sọ omi ìbùkún kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì ń fi mú àwọn ọgbà oko àti àwọn èso tí wọ́n máa kájẹ hù jáde.
50:10Júzù 26 · ojú. 518

وَالنَّخْلَ بَاسِقَاتٍ لَهَا طَلْعٌ نَضِيدٌ10

(A tún mú) igi dàbínù hù ga, tí àwọn èso orí rẹ̀ so jìgbìnnì.
50:11Júzù 26 · ojú. 518

رِزْقًا لِلْعِبَادِ ۖ وَأَحْيَيْنَا بِهِ بَلْدَةً مَيْتًا ۚ كَذَٰلِكَ الْخُرُوجُ11

Arísìkí ni fún àwọn ẹrú (Allāhu). A sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè. Báyẹn ni ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè yó ṣe rí).
50:12Júzù 26 · ojú. 518

كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَأَصْحَابُ الرَّسِّ وَثَمُودُ12

Àwọn ènìyàn (Ànábì) Nūh, àwọn ènìyàn Rass àti àwọn (ènìyàn) Thamūd pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn.
50:13Júzù 26 · ojú. 518

وَعَادٌ وَفِرْعَوْنُ وَإِخْوَانُ لُوطٍ13

Àti àwọn ‘Ād, Fir‘aon àti àwọn ọmọ ìyá (Ànábì) Lūt,
50:14Júzù 26 · ojú. 518

وَأَصْحَابُ الْأَيْكَةِ وَقَوْمُ تُبَّعٍ ۚ كُلٌّ كَذَّبَ الرُّسُلَ فَحَقَّ وَعِيدِ14

àti àwọn ará ’Aekah àti àwọn ìjọ Tubba‘u; gbogbo wọn pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìlérí Mi sì di ẹ̀tọ́ (lórí wọn).
50:15Júzù 26 · ojú. 518

أَفَعَيِينَا بِالْخَلْقِ الْأَوَّلِ ۚ بَلْ هُمْ فِي لَبْسٍ مِنْ خَلْقٍ جَدِيدٍ15

Ǹjẹ́ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ kó agara bá Wa bí? Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì nípa ìṣẹ̀dá (wọn) ní titun ni.
50:16Júzù 26 · ojú. 519

وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ وَنَعْلَمُ مَا تُوَسْوِسُ بِهِ نَفْسُهُ ۖ وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنْ حَبْلِ الْوَرِيدِ16

Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn. A sì mọ ohun tí ẹ̀mí rẹ̀ ń sọ fún un. Àwa sì súnmọ́ ọn ju isan ọrùn rẹ̀.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mujādilah;58:7.
50:17Júzù 26 · ojú. 519

إِذْ يَتَلَقَّى الْمُتَلَقِّيَانِ عَنِ الْيَمِينِ وَعَنِ الشِّمَالِ قَعِيدٌ17

(Rántí) nígbà tí (mọlāika) àwọn agbọ̀rọ̀-sílẹ̀ méjì bá bẹ̀rẹ̀sí gba ọ̀rọ̀ (sílẹ̀), tí ọ̀kan jókòó sí ọ̀tún, tí ọ̀kan jókòó sí òsì.
50:18Júzù 26 · ojú. 519

مَا يَلْفِظُ مِنْ قَوْلٍ إِلَّا لَدَيْهِ رَقِيبٌ عَتِيدٌ18

(Ẹnì kan) kò sì níí sọ ọ̀rọ̀ kan àyàfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà pẹ̀lú rẹ̀ (fún àkọsílẹ̀ rẹ̀).
50:19Júzù 26 · ojú. 519

وَجَاءَتْ سَكْرَةُ الْمَوْتِ بِالْحَقِّ ۖ ذَٰلِكَ مَا كُنْتَ مِنْهُ تَحِيدُ19

Àti pé ìpọ́kàkà ikú yóò dé láti fi òdodo ọ̀run rinlẹ̀. Ìyẹn ni ohun tí ìwọ ń sá fún.
50:20Júzù 26 · ojú. 519

وَنُفِخَ فِي الصُّورِ ۚ ذَٰلِكَ يَوْمُ الْوَعِيدِ20

Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ìyẹn ni ọjọ́ ìlérí náà.
50:21Júzù 26 · ojú. 519

وَجَاءَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَعَهَا سَائِقٌ وَشَهِيدٌ21

Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò wá pẹ̀lú olùdarí kan àti ẹlẹ́rìí kan (nínú àwọn mọlāika).
50:22Júzù 26 · ojú. 519

لَقَدْ كُنْتَ فِي غَفْلَةٍ مِنْ هَٰذَا فَكَشَفْنَا عَنْكَ غِطَاءَكَ فَبَصَرُكَ الْيَوْمَ حَدِيدٌ22

Dájúdájú ìwọ ti wà nínú ìgbàgbéra níbi èyí. A sì ti ṣí èbìbò (ojú) rẹ kúrò fún ọ báyìí. Nítorí náà, ìríran rẹ yóò ríran kedere ní òní.
50:23Júzù 26 · ojú. 519

وَقَالَ قَرِينُهُ هَٰذَا مَا لَدَيَّ عَتِيدٌ23

(Mọlāika) alábàárìn rẹ̀ yóò sọ pé: "Èyí ni ohun tí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ mi (gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀)."
50:24Júzù 26 · ojú. 519

أَلْقِيَا فِي جَهَنَّمَ كُلَّ كَفَّارٍ عَنِيدٍ24

Ẹ jù ú sínú iná Jahanamọ, gbogbo aláìgbàgbọ́ olóríkunkun,
50:25Júzù 26 · ojú. 519

مَنَّاعٍ لِلْخَيْرِ مُعْتَدٍ مُرِيبٍ25

olùdènà-iṣẹ́ rere, alákọyọ, oníyèméjì,
50:26Júzù 26 · ojú. 519

الَّذِي جَعَلَ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ فَأَلْقِيَاهُ فِي الْعَذَابِ الشَّدِيدِ26

ẹni tó mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Ẹ jù ú sínú ìyà líle.
50:27Júzù 26 · ojú. 519

۞ قَالَ قَرِينُهُ رَبَّنَا مَا أَطْغَيْتُهُ وَلَٰكِنْ كَانَ فِي ضَلَالٍ بَعِيدٍ27

(Èṣù) alábàárìn rẹ̀ yóò wí pé: "Olúwa wa, èmi kọ́ ni mo ṣì í lọ́nà, ṣùgbọ́n ó ti wà nínú ìṣìnà tó jìnnà (sí òdodo) tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀."
50:28Júzù 26 · ojú. 519

قَالَ لَا تَخْتَصِمُوا لَدَيَّ وَقَدْ قَدَّمْتُ إِلَيْكُمْ بِالْوَعِيدِ28

(Allāhu) yóò sọ pé: "Ẹ má se ṣàríyànjiyàn lọ́dọ̀ Mi. Mo kúkú ti ṣe ìlérí fun yín ṣíwájú.
50:29Júzù 26 · ojú. 519

مَا يُبَدَّلُ الْقَوْلُ لَدَيَّ وَمَا أَنَا بِظَلَّامٍ لِلْعَبِيدِ29

Wọn kò sì lè yí ọ̀rọ̀ náà padà ní ọ̀dọ̀ Mi. Èmi kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrú Mi."
50:30Júzù 26 · ojú. 519

يَوْمَ نَقُولُ لِجَهَنَّمَ هَلِ امْتَلَأْتِ وَتَقُولُ هَلْ مِنْ مَزِيدٍ30

(Rántí) ọjọ́ tí A óò sọ fún iná Jahnamọ pé: Ṣèbí o ti kún?" Ó sì máa sọ pé: "Ṣèbí àfikún tún wà?"
50:31Júzù 26 · ojú. 519

وَأُزْلِفَتِ الْجَنَّةُ لِلْمُتَّقِينَ غَيْرَ بَعِيدٍ31

Wọ́n máa sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). Kò sì níí jìnnà (sí wọn).
50:32Júzù 26 · ojú. 519

هَٰذَا مَا تُوعَدُونَ لِكُلِّ أَوَّابٍ حَفِيظٍ32

Èyí ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún gbogbo olùronúpìwàdà, olùṣọ́ (òfin Allāhu).
50:33Júzù 26 · ojú. 519

مَنْ خَشِيَ الرَّحْمَٰنَ بِالْغَيْبِ وَجَاءَ بِقَلْبٍ مُنِيبٍ33

Ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Allāhu ní ìkọ̀kọ̀, tí ó tún dé pẹ̀lú ọkàn tó ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà),
50:34Júzù 26 · ojú. 519

ادْخُلُوهَا بِسَلَامٍ ۖ ذَٰلِكَ يَوْمُ الْخُلُودِ34

(A óò sọ fún wọn pé:) "Ẹ wọ inú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àlàáfíà. Ìyẹn ni ọjọ́ gbére."
50:35Júzù 26 · ojú. 519

لَهُمْ مَا يَشَاءُونَ فِيهَا وَلَدَيْنَا مَزِيدٌ35

Ohun tí wọ́n ń fẹ́ wà nínú rẹ̀. Àlékún sì tún wà ní ọ̀dọ̀ Wa.
50:36Júzù 26 · ojú. 520

وَكَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُمْ مِنْ قَرْنٍ هُمْ أَشَدُّ مِنْهُمْ بَطْشًا فَنَقَّبُوا فِي الْبِلَادِ هَلْ مِنْ مَحِيصٍ36

Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Wọ́n sì ní agbára jù wọ́n lọ. (Nígbà tí ìyà dé) wọ́n sá àsálà kiri nínú ìlú. Ǹjẹ́ ibùsásí kan wà (fún wọn bí?)
50:37Júzù 26 · ojú. 520

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَذِكْرَىٰ لِمَنْ كَانَ لَهُ قَلْبٌ أَوْ أَلْقَى السَّمْعَ وَهُوَ شَهِيدٌ37

Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ní ọkàn tàbí ẹni tó fi etí sílẹ̀, tó wà níbẹ̀ (pẹ̀lú ọkàn rẹ̀).
50:38Júzù 26 · ojú. 520

وَلَقَدْ خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ وَمَا مَسَّنَا مِنْ لُغُوبٍ38

Dájúdájú A ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì fún ọjọ́ mẹ́fà. Kò sì rẹ̀ Wá rárá (áḿbọ̀sìbọ́sí pé A óò sinmi ní ọjọ́ keje).
50:39Júzù 26 · ojú. 520

فَاصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ قَبْلَ طُلُوعِ الشَّمْسِ وَقَبْلَ الْغُرُوبِ39

Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti wíwọ̀ (rẹ̀).
50:40Júzù 26 · ojú. 520

وَمِنَ اللَّيْلِ فَسَبِّحْهُ وَأَدْبَارَ السُّجُودِ40

Àti pé ní òru àti ni ẹ̀yìn ìrun ṣe àfọ̀mọ́ fún Un.
50:41Júzù 26 · ojú. 520

وَاسْتَمِعْ يَوْمَ يُنَادِ الْمُنَادِ مِنْ مَكَانٍ قَرِيبٍ41

Kí o sì tẹ́tí sí ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè láti àyè kan t’ó súnmọ́.
50:42Júzù 26 · ojú. 520

يَوْمَ يَسْمَعُونَ الصَّيْحَةَ بِالْحَقِّ ۚ ذَٰلِكَ يَوْمُ الْخُرُوجِ42

Ọjọ́ tí wọn yóò gbọ́ igbe pẹ̀lú òdodo. Ìyẹn ni ọjọ́ ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè).
50:43Júzù 26 · ojú. 520

إِنَّا نَحْنُ نُحْيِي وَنُمِيتُ وَإِلَيْنَا الْمَصِيرُ43

Dájúdájú Àwa, Àwa l’À ń sọ ẹ̀dá di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
50:44Júzù 26 · ojú. 520

يَوْمَ تَشَقَّقُ الْأَرْضُ عَنْهُمْ سِرَاعًا ۚ ذَٰلِكَ حَشْرٌ عَلَيْنَا يَسِيرٌ44

(Rántí) ọjọ́ tí ilẹ̀ yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ mọ́ wọn lára, (tí wọn yóò máa) yára (jáde láti inú ilẹ̀). Ìyẹn ni àkójọ t’ó rọrùn fún Wa.
50:45Júzù 26 · ojú. 520

نَحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَقُولُونَ ۖ وَمَا أَنْتَ عَلَيْهِمْ بِجَبَّارٍ ۖ فَذَكِّرْ بِالْقُرْآنِ مَنْ يَخَافُ وَعِيدِ45

Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí. Ìwọ kò sì níí jẹ wọ́n nípá (láti gbàgbọ́). Nítorí náà, fi al-Ƙur’ān ṣe ìrántí fún ẹni tí ń páyà ìlérí Mi.

Ṣeré láti ìbẹ̀rẹ̀ súrà

Abdullah Basfar - Qaf · Tlawati