اليوربا

سورة الإسراء · 17:110

قُلِ ادْعُوا اللَّهَ أَوِ ادْعُوا الرَّحْمَٰنَ ۖ أَيًّا مَا تَدْعُوا فَلَهُ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَىٰ ۚ وَلَا تَجْهَرْ بِصَلَاتِكَ وَلَا تُخَافِتْ بِهَا وَابْتَغِ بَيْنَ ذَٰلِكَ سَبِيلًا

Sọ pé: “Ẹ pe Allāhu tàbí ẹ pe ar-Rahmọ̄n (Àjọkẹ́-ayé).” Èyíkéyìí tí ẹ bá fi pè É (nínú rẹ̀), ṣebí tiRẹ̀ ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ. Má ṣe kígbe lórí ìrun (àti àdúà) rẹ. Má sì ṣe wà ní ìdákẹ́ rọ́rọ́. Wá ọ̀nà sáààrin méjèèjì yẹn.
____________________
Pípe Allāhu tàbí ar-Rahmọ̄n tàbí èyíkéyìí nínú àwọn orúkọ Allāhu tí ó dára jùlọ, kò túmọ̀ sí fífa orúkọ kan nínú àwọn orúkọ Allāhu pẹ̀lú òǹkà púpọ̀ bíi sísọ pé Allāhu, Allāhu … tàbí ar-Rahmọ̄n, ar-Rahmọ̄n … Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìlànà àwọn onibid‘ah. Èyí tí ó tọ sunnah ni lílo àwọn orúkọ náà nínú gbólóhùn. Kí á wo àwọn ìhun àti àgbékalẹ̀ àdúà Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nínú àwọn tírà hadīth lórí èyí tàbí tíra Hisnul-muslim “Odi Ìṣọ́ Mùsùlùmí” ti àáfà wa Ƙọhtọ̄niy.